Ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ Bakatue
Ayẹyẹ ọdún ìbílè Bakatue jẹ́ èyí tí àwọn olóyè àti ènìyàn Elmina ní ààrin Gbùngbùn Ghana máa ń ṣe.[1] Ayẹyẹ ọdún ìbílè náà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1847, tí wọ́n sì máa ń ṣe ní Ọjọ Ìṣẹ́gun àkọ́kọ́ nínú oṣù Agẹmọ (oṣù keje) ní ọdọọdún.[1]
Àwọn ènìyàn Dutch jábọ̀ ìròyìn pé ọdún ìbílẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1847, tí Gómìnà Cornelis Nagtglas sì kéde ní ọdún 1860.[2] Wọ́n máa ń fi ọdún ìbílẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ àkókò ẹ̀ja pípa tuntun ní Elmina.[3] Orúkọ ọdún yìí tí í ṣe Bakatue jẹyọ láti inú ẹ̀ka èdè Fante, èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ "draining of a lagoon".[4]Bákan náà ni wọ́n máa ń fi ọdún ìvílẹ̀ náà ṣàjọyọ̀ ìdásílẹ̀ ìlú Elmina láti àwọn ará Portugal lásìkò tí wọ́n kó Gold Coast lẹ́rú.[4] Yàtọ̀ sí èyí, wọ́n máa ń fi ọdún ìbílè náà gbàdúrà sí òrìṣà wọn fún ọdún ìpẹja tuntun, kí wọ́n ba lè rí ọ̀pọ̀ ẹja pa lódò.
Àtòjọ àwọn ètò náà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọjọ́ Ajé àti Ìṣẹ́gun àkọ́kọ́ nínú oṣù Agẹmọ (oṣù keje) ní àwọn ara Elmina máa ń yà sọ́tọ̀ láti fi ṣe ayẹyẹ ọdún ìbílè yìí.
Ọjọ́ Ajé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gbogbo ètò tó yẹ ní ṣíṣe ni wọ́n máa ń ṣe ní ọjọ́ yìí.
Ọjọ́ Ìṣẹ́gun
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọjọ́ yìí papọ̀ mọ́ àsìkò ìgbà òjò ní ìlú Ghana. Ìdí tí wọ́n fi yan ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni pé ọjọ́ yìí ni wọ́n fi ń bọ òrìṣà odò.[5] Látàrí èyí ní Elmina, ní ìbámu pèlú àwọn ìlú tí wọ́n ti ń pẹja ní ìlú Ghana, Àwọn apẹja ò kì í lọ sódo rárá ní ọjọ́ yìí láti fi bọ̀wọ̀ fún òrìṣà odò náà.[6] Lásìkò ọdún yìí, olorí Olóyè àti àwọn Olóyè ní ìlú Elmina máa rúbọ ẹyin ìbílẹ̀ àti iṣu gígún tí wọ́n fi epo yí, fún Nana Brenya, tí í ṣe òrìṣà odò, tí wọ́n sì máa gbàdúrà fún àlàáfíà. Ní òwúrò ọjọ́ ayẹyẹ́ náà, gbogbo ọmọ-ẹgbé ìdílé ọlọ́lá ní Elmina máa jókòó sí ìjókòó ọlọ́lá.[6]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 "Festivals in Ghana". www.ghanaweb.com. Archived from the original on 27 December 2011. Retrieved 27 December 2011. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Doortmont, Michel René; Smit, Jinna (2007). Sources for the Mutual History of Ghana and the Netherlands: An Annotated Guide to the Dutch Archives Relating to Ghana and West Africa in the Nationaal Archief, 1593-1960s. BRILL. p. 285. ISBN 90-04-15850-2. https://books.google.com/books?id=-SBwMhYAZw0C&pg=PA285. Retrieved 2016-11-19.
- ↑ "Bakatue". www.ghananation.com. Archived from the original on 17 February 2012. Retrieved 29 December 2011. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ 4.0 4.1 "Edina Bakatue Festival". www.ghanaexpeditions.com. Archived from the original on 26 April 2012. Retrieved 29 December 2011. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Bakatue festival". pathghana.com. Archived from the original on 15 October 2011. Retrieved 29 December 2011. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ 6.0 6.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedEdina3