Ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ Ohum
Ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ Ohum jẹ́ èyí tí àwọn ará Akuapem àti Akyem tó wà ní apá Ìlà-Oòrùn ilẹ̀ Ghana máa ń ṣe.[1][2][3][4]
Wọ́n máa ń ṣe àjọyọ̀ yìí ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun/Ọjọ́ Rú nínú oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ tàbí Ọ̀wàrà, tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìgbà tí àwọn ará Akyem ṣe ayẹyẹ ọdún Ohumkan, tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ Àìkú ńnú oṣù Ọ̀pẹ tàbí Ṣẹẹrẹ fún àwọn ènìyàn Akuapem. Kí àjọyọ̀ yìí tó bẹ̀rẹ̀, wọ́n máa kéde ìdádúró ariwo fún ọ̀sẹ̀ méjì.[5] Àwọn ará Akyem máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹlẹ́ẹ̀dá wọn pẹ̀lú odò Birim tí ó fi bùkún wọn. Wọ́n máa ń lo àwọn ohun èlò láti ilẹ̀ wọn àti omi wọn gẹ́gẹ́ bíi àmì láti fi ṣèrántí àwọn baba-ńlá wọn rí wọ́n tiraka láti dáàbò bo ìlú wọn. Àwọn ara ìlú náà máa ń san ẹ̀jé láti lè tẹ̀síwájú nínú àṣá̀ yìí láti mú kí ijọba wọn wà ń àlàáfíà, kí wọ́n sì máa ní ìbísí àti ìrẹ̀sí lásìkò ayẹyẹ náà.[6]
Ohumkyire ni ayẹyẹ tí wọ́n máa ń ṣe láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè fún àsìkò oṣu tuntun, àti láti béèrè ojúrere rẹ̀ fún ọdún tó ńbọ̀.[7] Bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n máa ń ṣàjọyọ̀ ilẹ̀ Akyem.[5]
Àtòjọ àwọn àwòrán
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Ghana » Eastern Region » Atiwa District". atiwa.ghanadistricts.gov.gh. Retrieved 2015-06-28.
- ↑ "Ohum Festival". www.okyeman.com. Retrieved 2019-01-27.
- ↑ (in en) Ghana and Its people. Intercontinental Books. https://books.google.com/books?id=35MrDwAAQBAJ&q=ohumkyire&pg=PA120.
- ↑ "Ohum Festival". www.okyeman.com. Retrieved 2019-10-21.
- ↑ 5.0 5.1 "Festivals Ghana - Easy Track Ghana". www.easytrackghana.com. Retrieved 2019-10-21.
- ↑ "Akyem Kyebi". wikimapia.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-08-11.
- ↑ Quashie, Richard (2017-07-20). "These photos of the Ohum Festival are enough proof that there is wealth in Ghana". Yen.com.gh - Ghana news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-10-21.