Jump to content

Bolanle Awe

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Bọ́láńlé Awẹ́)
Bọ́láńlé Awẹ́
Ọjọ́ìbí26 Oṣù Kínní 1933 (1933-01-26) (ọmọ ọdún 91)
Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèọmọ Nàìjíríà
Gbajúmọ̀ fúnNigerian Women's history, Oral history
Olólùfẹ́Olúmúyìwá Awẹ́

Bọ́láńlé (Fájẹ́m̄bọ́là) Awẹ́ tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kìíní ọdún 1933, (26 January 1933) jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ ìtàn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ìgbésí ayé àti ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Bọ́láńlé lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kìíní ọdún 1933 ní ilu Ilesha orile-ede Nàìjíríà. Oruko obi re je Samuel Akindeji Fajembola ati Mosebolatan Abede. Baba Fajembola wa lati ilu Ibadan, osisowo koko ni won ati alakoso ni ile ise John Holt & Co, sowo ati ile-iṣẹ ọjà gbogbogbo. Iya Bolanle je ara ilu Ilesa , omo idile Abede, omo Oba lati idile Bilayirere, ikan ninu awon ile oba merin ti Ilesa. Oluko ni Iya Bolanle

.Igbati won gbe baba rẹ si ọkan ninu awọn ẹka ti John Holt & Co. ni Ilesa, ni won bi Awe. Arabinrin naa jẹ olokiki ni ilu ilesa, nibiti awọn oṣiṣẹ Islam, Kristiẹniti, ati ẹsin Yoruba ti gbe ni iṣọkan[1].Ó kàwé ní Holy Trinity School, Imọ̀fẹ́-Iléṣa, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, St James Primary School, Òkèbọ́lá, ní Ìbàdàn, ní ipinle Oyo àti St Anne's School, Ìbàdàn.[2] Ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Perse School ní Cambridge, ìwé ẹ̀rí A Level, ó lọ sí St Andrews University ní Scotland níbi tí ó ti kàwé gboyè dìgírì kejì nínú ìmọ̀ ìtàn, bẹ́ẹ̀ náà o kàwé gboyè ọ̀mọ̀wẹ́ nínú ìmọ̀ ìtàn bákan náà ní Oxford University. Lẹ́yìn èyí, Bọ́láńlé padà sí Nàìjíríà padà sí Nàìjíríà, tí ó sìn gba iṣẹ́ olùkọ́ ní University of Ibadan, níbi tí ó ti gboyè ọ̀jọ̀gbọ́n.[3]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Professor Bolanle Awe – DAWN Commission". DAWN Commission. 2018-11-22. Retrieved 2022-08-24. 
  2. Olujimi, Toluwanimi (2006-05-01). "Nigeria: Founding Fathers Laid Foundation for Under-Development". Vanguard (Allfrica.com). http://allafrica.com/stories/200605010687.html. 
  3. Bolanle Awe - A Quintessential teacher, historian Archived 2016-02-23 at the Wayback Machine., 2014, MyNewsWatchTimesNG.com, Retrieved 15 February 2016.