Baselios Cleemis

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
His Eminence Baselios Cleemis
Cardinal, Major Archbishop of Trivandrum
ChurchSyro-Malankara Catholic Church
ArchdioceseTrivandrum
SeeTrivandrum, India
Enthroned5 March 2007
PredecessorCyril Baselios
Ordination11 June 1986
Consecration15 August 2001
Created Cardinal24 November 2012
RankCardinal-Priest
Other
MottoTo Unite in Love
Personal details
Born15 Oṣù Kẹfà 1959 (1959-06-15) (ọmọ ọdún 60)
Mukkoor, Thiruvalla, Kerala, India
ParentsMathew and Annamma Thottumkal
Alma materPontifical University of Saint Thomas Aquinas


Baselios Cleemis Thottunkal (Malayalam: ബസേലിയോസ് കർദ്ദിനാൾ ക്ലിമ്മീസ്) tàbí tí wọ́n bá fẹ́ gẹ́gẹ́ bí olórí ecclesiastical, Baselios Cleemis Cardinal Thottunkal[1][2][3][4][5] jẹ́ Major Archbishop ti Syro-Malankara Catholic Church. Pope Benedict XVI yànhán sí College of Cardinals tí Catholic Church ní Papal Basilica of Saint Peter ní Ọjọ́ kẹrìnlélógún Oṣù mọ́kànlá Ọdún 2012. Nígbà tí wọ́n yànhàn, òhun ló kéré jùlọ ní ẹgbẹ́ College of Cardinals. Ó jẹ́ olórí ecclesiastical Syro-Malankara Catholic Church àkọ́kọ́. Ní Ọjọ́ ọ̀kànlélọ́gbọ̀n Oṣù kínín Ọdún 2013, ó di ọmọ ẹgbẹ́ Congregation for the Oriental Churches àti ti  Pontifical Council for Interreligious Dialogue. Ní Ọjọ́ kejìlá Oṣu kejìlá Ọdún 2013, wọ́n dìbò yànhàn gẹ́gẹ́ bí  Ààrẹ Kerala Catholic Bishops' Council. Ní Ọjọ́ kọkànlá Oṣù kejì Ọdún 2014, wọ́n dìbò yànhàn gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Catholic Bishops' Conference of India.

Ìgbà èwe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Baselios Cleemis ní Ọjọ́ karùndínlógún Oṣù kẹfà Ọdún 1959  bí Isaac Thottumkal (wọ́n tún lè pèé ní Thottunkal) ní Mukkoor, ìlú kékeré kan tí o súnmọ́ ìlú Mallappally ní agbèègbè Pathanamthitta  ní State of Kerala ní Gúúsù India. Àwọ́n òbí rẹ̀ ni Mathew àti Annamma Thottumkal. Ẹbí Thottumkal jẹ́ ara ẹbí Pakalomattom, tó jẹ́ ẹbí onígbàgbọ́ Syria ìgbàanì ní Kerala.[6]

Ètò ẹ̀kọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alakọ́bẹ̀rẹ̀ Minor Seminary Formation ní  Tiruvalla lati 1976 sí 1979. Ó gba iyì B.Phil. lati St. Joseph's Pontifical Institute, Mangalapuzha, Aluva, níbi tí ó tí o lati 1979 sí  1982. Ó gba iyì  B.Th. lati Papal Seminary, Pune níbi tí ó ti kàwé lati 1983 sí 1986. Thottunkal di àlùfáà ní Ọjọ́ kọkànlá Oṣù kẹfà Ọdún 1986. Ó kàwé fún Master of Theology ní Dharmaram College, Bangalore lati  1986 sí 1989. Thottunkal ṣe Doctorate ní  Ecumenical Theology lati Pontifical University of St. Thomas Aquinas (Angelicum), Rome ní Ọdun 1997.[7]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]