Jump to content

Bayan Ul Quran

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Bayan Ul Quran
Fáìlì:Bayan Ul Quran.jpg
Cover
Olùkọ̀wéAshraf Ali Thanwi
CountryBritish India
LanguageUrdu
SubjectTafsir
GenreClassic
PublisherMatba Mujtabai, Delhi
Publication date
1908
Media typeHardcover

Bayan Ul Quran (Urdu: بیان القرآن) jẹ́ àtẹ̀jáde tafsir mẹ́ta (àlàyé) Quran tí ọ̀mọ̀wé Mùsùlùmí ilẹ̀ Indian, Ashraf Ali Thanwi kọ. (ní ọdún 1943).[1] Èdè Urdu ni wọ́n fi kọ́, ó jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì fún òǹkọ̀wé tó kọ.[2] Wọ́n ní tafsīr náà jẹ́ èyí tí a kan ṣe fún fún àwọn ọ̀mọ̀wé. [3]

Àtòjọ àlàyé yìí bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1320 AH.[4] Thanwi parí rẹ̀ ní 1905 (1323 AH).Ọ̀nà méjìlá ni wọ́n ṣe àtẹ̀jáde rẹ̀ sí láti Matb'a Mujtabai,ní Delhi ní ọdún 1908 (1326 AH).[5] Ìwé pàtàkì Khutba-i-Tafsir-i-Bayan al Quran láti ọwọ́ òǹkọ̀wé yìí, ó ti rọ̀gbàká àwọn àtẹ̀jáde tókù, nítorí nínú ‘Khutba’ Thanwi, ó ti sọ ìdí tí a fi to àwọn Tafsir náà jọ. Ó ní:: "Mo máa ronú nípa àtòjọ àlàyé kan nípa Kúràní, èyí tó lè fọwọ́ kan àwọn ipa àti aágbọn tó ṣe pàtàkì tó ṣe pàtàkì láwùjọ láì sí ìyípadà kankan,ṣùgbọ́n mo mọ̀ nípa àwọn àlàyé Kùránì tí wọ́n ti gúnlẹ̀ síbi kan náà síwájú èyí,nítorí náà ni mo ṣe máa ń rí àwọn àlàyé Kùránì mìíràn gẹ́gẹ́ bi àfikún ohun tó ti wà tẹ́lẹ̀.Tó jẹ́ ìgbà tí àwọn ènìyàn máa ń túmọ̀ Kùránì nítorí àtijẹ àtimu èyí tí kò sì bá òfin yìí Sharia mu, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Mùsùlùmí ni wọ́n ṣìnà nítorí àsìrò tí wọ́n gbọ́. Bákan náà dẹ̀ rè é àwọn ìwé pélébé kan tako àsìgbọ́ Kùránì yìí, sugbon àwọn ìwé yìí kò tó fún ìtakò náà.... Nínú àgbékalẹ̀ èyí ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Rabi al-Awal 1320 A.H, mo bẹ̀rẹ̀ àtòjọ Tafsir, ní èrò èrè ayé tí mo ti rí jẹ́ láti ara Allah. Tí yóò sì jẹ́ èrè fún gbogbo ayé náà." [6]

Ọgbọ́n Àmúlò

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn àbùdá méje tó ṣe pàtàkì tí Thanwi sọ pé Tafsir yìí ní nínú ni:[6]

  1. Lílo àwọn ọ̀rọ̀ tó rọ̀ láti túmọ̀ àwọn ẹsẹ Kùrán kí ó lè rọrùn láti yé.
  2. Kí a má fi àwọn àpólà ọ̀rọ̀ túmọ̀, nítorí àwọn àpólà ọ̀rọ̀ máa ń ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtumọ̀. Ìtumọ̀ gbọ́dọ̀ wà ní ọ̀rọ̀ geere ni, kí ó lè yànànà àlàyé náà ní kíkún.
  3. A ti ṣe iṣẹ́ àkànṣe lórí pé kí àwọn tó ń kà á má bà á má ṣe ìyè méjì tàbí àṣìrò. A ti ṣe àwọn Ìrànlọ́wọ́ fún àwọn àlàyé tó le pẹ̀lú ìwé pélébé nínú rẹ̀.
  4. Tí aáyà kan bá yapa rírọ́ ìtumọ̀ rẹ̀, a ti fi èyí tó jẹ́ ojúlówó rẹ̀ sí èrò. èyí tó jẹ́.
  5. Àwọn aáya kọ̀ọ̀kan ti sọ àsọ̀yé ìtumọ̀ tí wọ́n ní pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ bí ìró ìró wọn ṣe dún.
  6. Nínú àwọn ìwé òfin mẹ́rin tó wà, titi Hanafi ni a ṣe àmúlò, ṣùgbọ́n tí a bá nílò àwọn tókù, a fi àwọn náà sí ẹgbẹ́ òsì ojú ewé náà.
  7. Fún àwọn ìdí pàtàkì kan, a ṣe àfikún ààyè, ní èyí tí a ti ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ Makki àti Madami tó ṣókùnkùn. A tún fún wa ní àkóónú àti agbékalẹ̀ àwọn aáyà. Ààyè àwọn èdè Lárúbáwá wà fún ìpìlẹ̀ ìtumọ̀, èyí tí yóò wúlò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti ọ̀mọ̀wé.

Thanwi jẹ́ ọlọ́yàyà olùtẹ̀lẹ́ ìwé òfin Hanafi. Èyí tí ó sì ń hàn nínú àtẹ̀jáde rẹ̀.

Ní tòótọ́, Thanwi jẹ́ ọ̀mọ̀wé ìwé òfin, ó jẹ́ ni ti ó ní ẹ̀mí ìfọkànsí bákan náà had. Fún ìdí èyí, nígbà tó ń ṣe àwọn àmújáde àṣẹ tó tọ́ láti inú aáyà Kùránì, bẹ́ẹ̀ náà àwọn èyí tó kọjá òye nínú Kùránì. Ìtumọ̀ àkọ́kọ́ nínú èdè Urdu ni èyí, ní èyí tó jẹ́ pé a yọ àwọn ọ̀rọ̀ tó kọjá òye jáde sọ́tọ̀ nínú Kùránì.Ìdí pàtàkì fún àmújáde yìí ni láti yànnànà ìrújú Tasawwuf.[6]

Gẹ́gẹ́ bi Thanwi nínú ìtumọ̀ Kùránì yìí, ó ní ó tẹ́lẹ̀ àwọn òṣùwọ̀n ogún kan tó jẹ́ pàtàkì.[7]

  1. A ṣe àmúlò Tafsir al-Baydawi, Tafsir al-Jalalayn, Tafsir-i-Rehmani, Al-itqan, Tafsir-i-Malim Al-Tanzil, Tafsir al-Alusi, Tafsir-i-Madarik, Tafsir-i-Khazin, Tafsir-i-Ibn-e-Kathir, Al-Dur al-Manthur àti Al-Kashshaaf àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà tí à ń ṣe àtòjọ ìtumọ̀. Yàtọ̀ sí àwọn Tafasir, a tún lo àwọn ìwé òfin àti àwọn Hadith mìíràn.
  2. A ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín orí, aáyà àti àsamọ̀ àwọn orí náà sílẹ̀.
  3. A pèsè ìtọ́ka fún àwọn aáyà yìí, kí a lè dènà àwítúnwí ìtumọ̀ àwọn aáyà náà.
  4. A ti ṣe àyẹ̀wò rírọ́ Tafsir dáadáa, àti bí a ṣelè ṣàlàyé rẹ̀, kí a tó sọ pé ó jẹ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì fún ìtumọ̀ Kùránì.
  5. Nígbà tí à ń yànnànà ìsiyè méjì, èròǹgbà wa ni láti yànnànà ìsiyè méjì tó ń bí ìró.
  6. Àwọn ọ̀rọ̀ tí èrò wọn kò ní ìtumọ̀ kò sí nínú ìtumọ̀ yìí.
  7. A yàgò fún àwọn àpólà ọ̀rọ̀, kí òye ìtumọ̀ náà lè yé ni.
  8. ÀWỌN mú àwọn ìròyìn nípa ìwé mímọ àtijọ́ nínú All Tafsir-i-Haqani.
  9. Nínú àwọn ààyè mìíràn, ìtumọ̀ yìí yẹ kí ó fẹjú kiri, a rò pé kí a ṣe àmúlò àwọn tó bá tún jẹ́ ojúlówó fún èyí.
  10. A ṣe àlàyé àwọn ọ̀rọ̀ Fiqh, èyí tí ó sì wà nínú àwọn àpẹẹrẹ.
  11. A pèsè atọ́ka àkóónú, èyí tí ó jẹ́ kí Tafsir náà rọrùn fún àwọn tí wọ́n fẹ́ kà á.
  12. Àwọn aṣíwájú àti àwọn tí wọ́n tẹ̀le ti kọ́kọ́ ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ̀,tí èyí sì hàn nínú ìtumọ̀ náà.
  13. Láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò nípa ìtumọ̀, èyí tó jẹ́ ojúlówó nìkan ni a gbà wọlé.
  14. Àwọn àlàyé aáyà kan wà tó ṣe wí pé, àwọn ọ̀mọ̀wé àti àwọn tó bá páyà Ọlọ́run nìkan ló lè jẹ àǹfàní láti ara wọn.
  15. Àwọn aáyà kan wà, tí wọn ṣàlàyé púpọ̀, ṣùgbọ́n síbẹ̀ síbẹ̀, yóò yé ènìyàn.
  16. Àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì kan wà tí kò sí nínú ìtumọ̀ náà, ṣùgbọ́n, tí a lè fi òye kíka ìwé ìtumọ̀ náà gbe.
  17. A fi àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tayọ ìtumọ̀ ní síṣẹ́ǹtẹ̀lé
  18. A yan àlàyé tí Marfu Ahadith láti ọwọ́ Muhammad láàyò ju àwọn ìgbàgbọ́ tó kù lọ.
  19. Àwọn òṣùwọ̀n tí a wá kà síwájú yìí ó, a kò sọ nínú ìwé ìtumọ̀ náà, ṣùgbọ́n òǹkọ̀wé kojú wọn láàárín ọ̀nà ìwé ìtumọ̀ náà.
  20. Ìtumọ̀ èdè Lárúbáwá yìí wà fún àwọn tó bá lóye, nítorí náà, kò nílò láti ka àwọn òṣùwọ̀n yìí, kí ó tó tẹ̀le.

Iṣẹ́ náà wà ní àtẹ̀jáde ìpín mẹ́ta. Ìfáárà tó kún wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́, tí ó ṣe àfojúsùn sí àwọn ọ̀ràn tó wà nínú Quran. Àwọn àtẹ̀jáde ìwé náà, a ti àkóónú wọn ló wà ní ìsàlẹ̀:[8]

Àtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ògbufọ̀ Bengali ìwé yìí jáde ní ọdún 1972 láti ilé ìyáwèé Emdadia lábẹ́ orúkọ 'Tafsire Ashrafi'.[9]

A ṣe àtẹ̀jáde ògbufọ̀ Gẹ̀ẹ́sì titi abridged ní ilé iṣẹ́ tẹ̀wetẹ̀wé Zam-Zam ní ọdún 2003 fún àwọn tó ń tọ ipa suluk, ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn ẹ̀mí èyí tó jẹ́ kókó tó jẹyọ nínú tasawwuf. Ó bẹ̀rẹ̀ láti Al-Fatiha, Ad Dhuha títí dé Al-nas.


Àwọn àràbarà Tafsir yìí tó da hàn nínú ìsọ Anwar Shah Kashmiri’: "Mo kọ́kọ́ rò pé ìtumọ̀ yìí wà fún àwọn ènìyàn lásán ni, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ti mo wò ó dáradára tán, mo ri wí pé ó ṣe pàtàkì sí àwọn ọ̀mọ̀wé náà bákan náà."[7] Bilal Ahmad Wani,olùṣèwádìí ilé-ẹ̀kọ́ gíga a Kashmir kọ pé , "Ìwé ìtumọ̀ yìí kún fún ọgbọ́n, lọ́nà tó ṣe wí pé gbogbo ènìyàn ni yóò lè jẹ Àǹfàní rẹ̀ ní bí ọgbọ́n oníkálukú bá ṣe mọ. Àlàyé rẹ̀ tún kún, èyí tó tún wá ṣe pàtàkì ni pé, ó ṣe àmújáde àwọn ọ̀rọ̀ tó kọjá òye ènìyàn jáde kúrò nínú Kùránì, láti lè wẹ àwọn èrò nípa àwọn ọ̀rọ̀ yìí mọ́, àwọn èrò bi Wahdat al-Wajud (Ìṣọ́kan Ẹ̀dá) àti Nazriah-i Hulul (Àkúdàáyá) àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ."[7]

Àdàkọ:Portal box

Àwọn Ìtọ́kasí

  1. Asir Adrawi (in ur). Tazkirah Mashāhīr-e-Hind: Karwān-e-Rafta (2 April 2016 ed.). Deoband: Darul Muallifeen. p. 35. 
  2. Àdàkọ:Cite thesis
  3. Àdàkọ:Cite thesis
  4. Wani, Bilal Ahmad (2016). "Tafsir Bayan al-Quran of Maulana Ashraf Ali Thanwi: An Estimate". Asian Journal of Multidisciplinary Studies 4 (2): 198. ISSN 2348-7186. http://www.ajms.co.in/sites/ajms2015/index.php/ajms/article/view/1645.  Text was copied from this source, which is available under a Creative Commons Attribution 3.0 License.
  5. Ali, Syed Shahid (in ur). Urdu Tafāsīr Bīswi Sadī Mai. Lahore: Maktaba Qāsim al-Uloom. p. 12. 
  6. 6.0 6.1 6.2 Wani 2016, p. 198.
  7. 7.0 7.1 7.2 Wani 2016, p. 199.
  8. Maulana Ashraf Ali Thanvi (in ur). Tafseer E Bayan Ul Quran. http://archive.org/details/TafseerEBayanUlQuran. 
  9. Ullah, Sakhawat (26 July 2019). "Sequence of Quran translation in Bengali language". Kaler Kantho. https://www.kalerkantho.com/print-edition/islamic-life/2019/07/26/795902. 

Àdàkọ:Ashraf Ali Thanwi Àdàkọ:Tafsir Àdàkọ:Authority control