Betty Acquah
Betty Acquah (tí wọ́n bí ní 20 March 1965) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ghana àti ayàwòrán aṣègbèfábo. Ó máa ń lo ọ̀dà àti òróró fún àwọn àwòrán rẹ̀.[1][2]
Ìbẹ̀rèpẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Cape Coast ní Ghana, ó sì lọ sí Wesley Girls' Senior High School àti Holy Child School. Lẹ́yìn náà ni ó lọ sí Kwame Nkrumah University of Science and Technology, níbi tí ó ti gboyè master's degree nínú ìmọ̀ Visual Arts, tó sì sojú dé yíya àwòrán. Ní Japan, ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ ọnà ní Tokyo School of Art.[3]
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Acquah ti ń ṣiṣẹ́ fún ọdún méje ní yàrá àwọn àwòrán fún Center for National Culture ní ìlú Accra, ó sì ti ń ṣàfihàn àwọn iṣẹ́ rè ní Berj Art Gallery láti ọdún 2002 wọ 2005. Ó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ Ghana Association of Visual Artists.[4] Ní oṣù kẹfà ọdún 2019, ó sọ ọ́ di mímọ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí Newsday BBC ṣe fún un pé ó wu òun láti ṣi national art gallery kan sí ìlú Ghana.[5]
Acquah ti ṣàfihàn àwọn iṣẹ́ rè ní Ghana, Nàìjíríà, United Kingdom, India, Germany, Spain, Japan àti United States of America.[4]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Patrick William Dodoo and others exhibit Luxury Arts at Orca Deco Art Exhibition in celebration of Ghana’s Independence Month". GhanaWeb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 1970-01-01. Archived from the original on 2024-01-13. Retrieved 2024-01-13.
- ↑ Ago, Tommytwohatsin Art • 2 Years (2017-12-31). "Ghanaian dancers by Betty Acquah". Steemit (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-09-24.
- ↑ "Art: Betty Acquah | Maple Tree Literary Supplement -issue17". www.mtls.ca. Retrieved 2019-09-24.
- ↑ 4.0 4.1 "Betty Acquah" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-09-24.
- ↑ "BBC World Service - Newsday, Calling for a national art gallery in Ghana". BBC (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-09-24.