Jump to content

Big Six (àwọn ajìjàgbara)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

A. Philip Randolph (Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹrin, ọdún 1889 – Ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù karùn-ún , ọdún 1979) jẹ́ olùjàfẹ́tọ̀ọ́ àwùjọ nínú ìgbésẹ̀ òṣìṣẹ́ àti ẹgbẹ́ Ẹ̀tọ́ aráàlú . Ní ọdún 1925, ó ṣètò Ẹgbẹ́ Alábòójútó Arákùnrin ti Ọkọ̀ Sísùn . Èyí ni ìgbìyànjú pàtàkì àkọ́kọ́ láti ṣe àgbékalẹ̀ Ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́ kan fún àwọn òṣìṣẹ́ ti Ilé-iṣẹ́ Pullman, èyí tí ó jẹ́ agbanisísẹ́ pàtàkì i ti Àwọn ọmọ Áfíríkà - Amẹ́ríkà . Nígbà Ogun Àgbáyé II, Randolph jẹ́ ohun èlò nínú ìgbésẹ̀ March on Washington, èyí tí kò kẹlẹ̀ yọrí sí March on Washington gangan ṣùgbọ́n ó jẹ́ àbájáde ni ìsopọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ ogun àti níkẹyìn àwọn ológun . Ó wà láàyè títí di ẹni àádọ́rùn-ún [90] ọdún.

Roy Wilkins (Ọgbọ̀n ọjọ́ Oṣù Kẹjọ, Ọdún 1901 – Ọjọ́ kẹjọ Oṣù Kẹsàn-án, Ọdún 1981) jẹ́ ajìjàgbara fún ẹ̀tọ́ aráàlú láti ọdún 1930 sí ọdún 1970. Ní ọdún 1955, ó jẹ́ olùdarí ti National Association for the Advancement of Colored People (NAACP). Ó ní orúkọ tí ó dára jùlọ gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ fún Ìgbésẹ̀ Ẹ̀tọ́ Ìlú. Ó kópa nínú March on Washington (1963),  the Selma to Montgomery marches (1965), àti Ìgbésẹ̀ Tako Ìbẹ̀rù (1966).

Whitney Young (Ọjọ́ kọ̀kànlélọ́gbọ̀n oṣù keje , ọdún 1921 - Ọjọ́ kọkànlá Oṣu Kẹta, Ọdún 1971) lo púpọ̀ jùlọ nínú iṣẹ́ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ láti fòpin sí ìyàsọ́tọ̀ iṣẹ́ ní Gúsù, àti pé ó ní àtìlẹyìn láti ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́hìn ìrírí rẹ̀ ti ìjà nínú Ogun Àgbáyé II ó sì tìkalárarẹ̀ di olùfaragbá ìyàsọ́tọ̀ yìí. . Ní ọdún 1961, Young jẹ́ olùdarí ti Àjùmọ̀ṣe Ìlú ti Orílẹ̀-èdè, ipò tí ó wà títí ó fi kú ní ọdún 1971. Gẹ́gẹ́ bí olùdarí, ó sọ Líìgì ìgboro àpapọ̀ láti àjọ ẹ̀tọ́ aráàlú di èyí tí ó ń jà fún ìdájọ́ òdodo, àti pé ó ṣe bẹ́ẹ̀ nípa mímú òfin ètò ẹ̀kọ́ tuntun wá àti àwọn ètò tí kò ya àwọn ọmọ ẹgbẹ́ aláwọ̀ funfun kúrò nínú àjọ náà.