Jump to content

Bikiya Graham-Douglas

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Bikiya Graham-Douglas
Ọjọ́ìbíBikiya Graham-Douglas
on March 4
in Port-Harcourt, Rivers State
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Actress/Performing Artiste
Ìgbà iṣẹ́2009 - Present
Parent(s)Alabo Tonye Graham-Douglas H.E. Bolere Elizabeth Ketebu

Bikiya Graham-Douglas jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọbìnrin àwọn tọkọtaya olóṣèlú Nàìjíríà kan, Alabo Graham-Douglas àti Bolere Elizabeth Ketebu. Graham-Douglas ti kẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga bíi London Academy of Music and Dramatic Art, Oxford School of Drama, Bridge Theatre Training Company àti Point Blank Music School . Ó gba oyè ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ Business Economics àti Business Law láti Yunifásitì ìlú Portsmouth, Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì

Òun ni olùdásílè Beeta Universal Arts Foundation (BUAF).[1]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó gbajúmọ̀ fún àwọn ipa rẹ̀ nínu àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù àti sinimá àgbéléwò. Lára wọn ni Flower Girl, Shuga, Closer, Saro, For Coloured Girls, Suru L'ere, Lunch Time Heroes, Jenifa's Diary, Legacy àti The Battleground.[2][3][4]

Bikiya bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ nígbà tó fi kópa nínu eré ti Femi Oguns kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Torn, èyí tó wáyé ní Arcola Theatre, ̀Ilú Lọ́ndọ̀nù. Ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Africa Unite Music Group, èyítí ó ṣe onígbọ̀wọ́ àkọ́kọ́ àmì-ẹ̀yẹ Best African Act níbi ayẹyẹ MOBO Awards. Ó tún ti ṣiṣẹ́ rí pẹ̀lú MTV Base Africa níbi àkọ́kọ́ ayẹyẹ MTV Africa Music Awards (MAMA).

Àwọn ìyẹ́sí tí ó ti ní

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Àmì ẹ̀yẹ ti Africa Magic Viewers Choice Awards (AMVCA 2014) gẹ̀gẹ̀ bi amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèrébìnrin tí ó dára jùlọ fún ipa rẹ̀ nínu fíìmù Flower Girl.[5]
  • Àmì ẹ̀yẹ ti Nollywood Movies Awards (NMA 2014)[6]
  • Àmì ẹ̀yẹ ti Nigeria Entertainment Awards (NEA 2014)[7]
  • Àmì ẹ̀yẹ ti National Association of Nigerian Theatre Arts Practitioners (NANTAP)

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Our People". Beeta Universal Arts Foundation (BUAF). Archived from the original on 23 July 2014. Retrieved 11 December 2014. 
  2. "MTV Shuga cast members!". MTV Base. Retrieved 11 December 2014. 
  3. "Posts by tag: Bikiya Graham Douglas". Gist Factory. December 22, 2013. Archived from the original on December 10, 2014. Retrieved December 10, 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "When For Coloured Girls came to Lagos". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 30 July 2014. Retrieved 11 December 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. "2014 AMVCA winners". Africamagic.dstv.com. Archived from the original on 15 March 2014. Retrieved 11 December 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "Nollywood Movies Awards". Noolywoodmoviesawards.tv. Archived from the original on 13 December 2014. Retrieved 11 December 2014. 
  7. "Nominees". Neaawards.com. Retrieved 11 December 2014.