Boity Thulo
Boity Thulo | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Boitumelo Thulo 28 Oṣù Kẹrin 1990 Potchefstroom, North West |
Ẹ̀kọ́ | Monash University |
Iṣẹ́ | |
Ìgbà iṣẹ́ |
|
Website | Official site |
Musical career | |
Irú orin | Hip hop |
Instruments | Vocals |
Associated acts | Nasty C |
Boitumelo Thulo (bíi ni ọjọ́ kejìdínlógbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 1990) tí orúkọ inagi rẹ jẹ Boity jẹ́ òṣèré, olórin, oníṣòwò àti mọ́dẹ́lì lórílẹ̀ èdè South Áfríkà.
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Thulo sì ìlú Potchefstroom, ìyá mama rẹ sì ló tọ dàgbà.[1] Òun nìkan ni ọmọ ìyá rẹ bí. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Monyash University níbi tí ó tí kọ́ ẹ̀kọ́ Psychology and Criminology, ṣùgbọ́n kò parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nítorí pé kò rí owó ilé ẹ̀kọ́ na ṣan.[2]
Iṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Thulo bẹ̀rẹ̀ sì ní ṣe atọkun ètò pẹlu Crib Note ni ọdún 2011. Òun àti Stevie French jọ ṣe atọkun fun ètò The Media Career Guide Show lórí SABC.[3][4] Ó ti ṣe atọkun fun oríṣiríṣi ètò bíi SkyRoom Live, Ridiculousness Africa, Club 808, Zoned, Change Down, àti Big Brother Africa.[5] Ní ọdún 2012, ó kópa nínú eré Rock ville.[6] Ní ọdún 2014, ó farahàn gẹ́gẹ́ bíi Betty nínú eré Dear Betty.[7] Ó kọ ipa ránpé nínú eré Mrs Right Guy ni ọdún 2016.[8] Thulo kọ́kọ́ farahàn gẹ́gẹ́ bí olórin níbi ayẹyẹ Migos Culture Tour ni ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹwàá ọdún 2017[9]. Ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 2018, ó gbé orín tí ó pè àkọlé rẹ̀ ni Wuz Dat,[10] orin náà sì gba àmì ẹ̀yẹ Best Collabo láti ọ̀dọ̀ South African Hip-Hop Awards ni odun 2018[11]. Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kejì ọdún 2019, ó gbé orin rẹ kejì jáde ti àkòrí rẹ jẹ Bakae.[12]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Boity Thulo - Age, House, Engaged, Biography...". Marathi TV.
- ↑ "Boity Thulo: I also had to drop out of university". Channel24.
- ↑ "GFC Launches Media Career Guide". Gauteng Film Commission. Archived from the original on 2019-02-03. Retrieved 2020-02-17.
- ↑ "SABC 1's new Media TV Show". YoMZansi.
- ↑ "Boity Thulo". TVSA.
- ↑ "Boity Article". Press Reader.
- ↑ "Boity Thulo". IMDb.
- ↑ "Mrs Right Guy". IMDb.
- ↑ "HUH? Is Boity Thulo A Rapper Now?". People Magazine. Archived from the original on 2019-05-11. Retrieved 2020-10-28.
- ↑ "Listen: Boity drops new song 'Wuz Dat' ft. Nasty C". EastCoastRadio.
- ↑ "Boity gets her first ever nod at the #SAHHA2018". Times LIVE.
- ↑ "LISTEN: BOITY'S 2ND SINGLE 'BAKAE' IS A BANGER!". Daily Sun.