Bolanle Ninalowo
Bolanle Ninalowo | |
---|---|
Bolanle Ninalowo at the 2020 AMVCA | |
Ọjọ́ìbí | 7 Oṣù Kàrún 1980 Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Orúkọ míràn | Nino |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Iléẹ̀kọ́ gíga | DeVry University |
Iṣẹ́ | Actor |
Ìgbà iṣẹ́ | 2010–present |
Bọ́láńlé Nínálowó tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ní ó (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ keje oṣù karùn-ún ọdún 1980) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò àti onímọ̀ Ìsirò-owó ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ṣùgbọ́n tí ó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Bí ó ṣe ń ṣeré tíátà, bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ akọrin. [1][2][3]
Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Nínálowó sí ìlú Ìkòròdú ni ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Kí óó dèrò ìlú-ọba ó kàwé àkóbẹ̀rẹ̀ àti sẹ̀kọ̀ndìrì rẹ̀ ní ìlú Èkó.[4]
Ìgbìyànjú nídìí ìṣe sinimá àgbéléwò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ síwájú, Nínálowó jẹ́ onímọ̀ Ìsirò-owó, nítorí ìdí èyí, ó kọ́kọ́ ṣíṣe ni ilé-ìfowópamọ́ gẹ́gẹ́ bí Aṣèṣirò-owó (Accountant) fún ìgbà díẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kí ó tó dára pọ̀ mọ́ ìṣe eré sinimá àgbéléwò ṣíṣe lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Bákan náà, nígbà tí ó padà sí Nàìjíríà, ó tún bá ilé-ìfowópamọ́ Guaranty Trust Bank ṣíṣe kí ó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà. Nínálowó kò fi bẹ́ẹ̀ rọ́wọ́ mú nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò gẹ́gẹ́ bí olóòtú, ṣùgbọ́n lọ́dún 2014, ní ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá di gbajúmọ̀ nídìí ìṣe sinimá àgbéléwò.[5] [6]
Àwọn àmìn ẹ̀yẹ tí ó ti gbà àti àwọn tí wọ́n dárúkọ díje rẹ̀ fún
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Revelation of the Year, Best of Nollywood Award, 2010
- Best Supporting Actor of the Year ‘English’, City People Movie Award, 2017[7]
- The Best Actor in a Leading Role ‘English‘ Picture Perfect’ Best of Nollywood Awards (BON), 2017
- Best Actor of the Year ‘English’ City People Movie Award, 2018
- Best Actor of the Year ‘English’, City People Movie Award, 2018
Àtòjọ díẹ̀ nínú àwọn sinimá-àgbéléwò tí ó ti kópa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Husbands of Lagos
- Ratnik
- Picture Perfect (2016 film)
- Road To Yesterday
- Tiwa’s Baggage
- Coming From Insanity
- Night Bus To Lagos
- Atlas
- A fire In The Rain
- 30 Years A Virgin
Awon àmì ẹ̀yẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Year | Award ceremony | Prize | Result | Ref |
---|---|---|---|---|
2010 | Best of Nollywood Awards | Revelation of the Year | Gbàá | |
2017 | City People Movie Award | Best Supporting Actor of the Year - English | Gbàá | [8] |
Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Lead role - English | Gbàá | [9] | |
2018 | Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Lead Role - Yoruba | Wọ́n pèé | |
City People Movie Award | Best Actor of the Year - English | Gbàá |
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Why my marriage failed –Bolanle Ninalowo". Newtelegraph. 2017-12-31. Archived from the original on 2019-12-21. Retrieved 2019-12-17.
- ↑ Nigeria, Information (2018-03-21). "My success story in Nollywood – Bolanle Ninalowo". Information Nigeria. Retrieved 2019-12-17.
- ↑ Bada, Gbenga (2015-05-13). "Rukky Sanda’s cousin becomes Nollywood’s new toast". Pulse Nigeria. Retrieved 2019-12-17.
- ↑ "Bolanle Ninalowo biography, net worth, age, family, contact & picture". Nigeria Business Directory - Find Companies, People & Places in Nigeria. 1980-05-07. Retrieved 2019-12-17.
- ↑ "Bolanle Ninalowo Biography & Net Worth". 360dopes. 2018-07-20. Retrieved 2019-12-17.
- ↑ "BOLANLE NINALOWO: WHY I SEPARATED FROM THE MOTHER OF MY KIDS - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2017-11-03. Retrieved 2019-12-17.
- ↑ Emmanuel, Daniji (2017-10-18). "Full List Of Winners At The 2017 City People Movie Awards". City People Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-11-23.
- ↑ Emmanuel, Daniji (18 October 2017). "Full List Of Winners At The 2017 City People Movie Awards". City People Magazine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 23 November 2019.
- ↑ "BON Awards 2017: Kannywood’s Ali Nuhu receives Special Recognition Award". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 23 November 2017. Retrieved 7 October 2021.