Bose Ogulu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Bose Ogulu jẹ́ ọ̀mọ̀wé, oníṣòwò obìnrin àti aláákòso ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ogulu ni aláákòso Burna Boy's èyí tí í ṣe iṣẹ́ orin kíkọ ọmọ rẹ, ìdí nì yí tí wọ́n tún fi mọ̀ ọ́ sí Mama Burna

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ogulu jẹ́ ọmọ bíbí inú Benson Idonije, ẹnití ń ṣe ìlú mọ̀ ọ́ ká olórin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Idojije ni aláákòso fún Fela Kuti nígbà kan. Pẹ̀lú oyè aláàkọ́kọ́ ti Yunifásítì (Bachelor of Art degree) tí ó gbà nínú ìmọ̀ lórí i àwọn èdè àjèjì àti oyè onípele kejì (Masters of Art degree) tí ó gbà nínú ìmọ̀ lórí i ìtunmọ̀ èdè láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifasiti ilu Port Harcourt. Ogulu ṣe àṣeyọrí nínú iṣé rẹ gẹ́gẹ́ bí i olùtunmọ̀ èdè fún àwọn ilé-ìṣòwò ti ìwọ̀-oorùn Áfíríkà (Federation of West Africa Chambers of Commerce). Àwọn èdè bí i èdè Geesi, Faranse, Jemani, Italia àti èdè Yòrùbá já geere ní ẹnu rẹ.[1][2] Ìdí nì yí tí ó fi dá ilé-ìwé tí wọ́n ti ń kọ́ èdè , tí wọ́n ń pè ní àwọn Afárá Èdè (Language Bridges), sílẹ̀. Ilé-ẹ̀kọ́ yi ni ó ti ṣe ètò ìrìn-àjò ti àṣà fún àwọn ọ̀ọ̀dọ́ tí ó lé ní ẹgbẹ̀sán án (1,800).[3]

Ní àfikún, Ogulu ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i olùkọ́ èdè Faranse fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní Yunifásítì ti ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà ní ìlù Port Harcourt. Ó fi ẹ̀yìn tì nì ẹnu iṣẹ́ ní ọdún 2018.[4]

Iṣẹ́ rẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ogulu ń ṣe aláàkóso àwọn iṣẹ́ orin Damini ọmọ rẹ, ẹni tí ó ń ṣiṣẹ́ orin lábẹ́ orúkọ Burna Boy èyí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ ọ́ sí. Ó tún ń ṣe àkóso iṣẹ́ orin Nissi ọmọ rẹ̀ obìnrin, ẹni tí ó ń ṣiṣẹ́ orin lábẹ́ Nissi tí í ṣe orúkọ rẹ̀ gangan. Ogulu ṣe aláàkóso fún Burna Boy títí di ọdún 2014 kí ó tó tún wa di aláàkóso ọmọ rẹ̀ yí padà làti ọdún 2017 síwájú. Èyí ni ó fún un ní orúkọ ìnágijẹ, Mama Burna tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ ọ́ sí.[5][6] Ogulu ti gba àwọn àmì ẹ̀yẹ fún Burna Boy ọmọ rẹ̀ níbi ọ̀pọ̀ ayẹyẹ tí ó ti ṣe asojú rẹ. Lára àwọn àmì ẹ̀yẹ yi ni àwọn ẹ̀bùn orin ti Áfíríkà (All Africa Music awards), The Headdies àti MTV Europe Music Award.[7] Nígbà tí ó gbọ́ wípé ọmọ rẹ, Burna Boy ti borí láti gbà àmì ẹ̀yẹ ọdún 2019 ti MTV fún òṣèré Áfíríkà tí ó dára jùlọ, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ó pè é níbi tí ó ti ń ṣe eré lọ́wọ́ láti lè sọ ìròyìn ayọ̀ yí fún un.[8]

Nígbà tí Burna Boy gba àwọn ẹ̀bùn mẹ́rin kan níbi ayẹyẹ àwọn àmì ẹ̀yẹ ti Soundcity MVP ti ọdún 2018, Ogulu ni ó lọ ṣe aṣojú fún ọmọ rẹ̀ níbí yi ni ó ti ṣo ọ̀rọ̀ tí ó fa ìdùnnú àwọn akọìròyìn nígbà tí ó sọ pé " Ẹ má a retí ìsínwín díẹ̀ si." Ní ibi àwọn àmì ẹ̀yẹ ti BET tí wọ́n ṣe ní ọdún 2019 ní ìlú California, Ogulu ló lọ ṣe aṣojú ọmọ rẹ̀ láti gba àmì ẹ̀ye fún un fún Best Internation Act. Níbi àmí ẹ̀yẹ yi ni ó ti kà á nínú ọ̀rọ̀ rẹ níbití ó ti ń sọ fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tí ó ti di ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pé kí wọ́n rántí wípé ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà ni wọ́n kí ó tó di wípé wọ́n di ohunkóhun. Ọ̀rọ̀ rẹ yi mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn dìdedúró pàtẹ́wọ́.[9][10]

Bose Ogulu ni aláṣẹ àti olùdásílẹ̀ ti Spaceship Collective àti Spaceship publishing (aṣọ àtẹ̀jáde).[11]

Ìgbésí ayé rẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bose Ogulu ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Samuel Ogulu ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn tí wọ́n sì bí ọmọ mẹ́ta tí orúkọ wọn ń jẹ́ Damini, Ronami ati Nissi Ogulu.[12]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Ogunnaike, Lola. "Burna Boy Is Trying to Wake Up Africa". GQ. Retrieved 2020-11-03. 
  2. "Burna Boy révèle pourquoi il préfère que sa mère soit son manager". Life Magazine (in Èdè Faransé). Retrieved 2020-11-03. 
  3. "Bose Ogulu (Mama Burna)". OKAYAFRICA's 100 WOMEN. 2019-02-24. Archived from the original on 2020-09-30. Retrieved 2020-11-03. 
  4. Okoruwa, Samuel (2019-08-02). "Facts About Burna Boy’s Mom: Bose Ogulu". Reterdeen. Retrieved 2020-11-03. 
  5. "Title of new album and other Burna Boy's revelations in Twitter Q&A". Pulse Nigeria. 2020-03-31. Retrieved 2020-11-03. 
  6. Durosomo, Damola (2019-03-29). "The Internet Doesn't Know Mama Burna At All". OkayAfrica. Retrieved 2020-11-03. 
  7. "Burna Boy absent at coronation as Africa's artiste of the year". P.M. News. 2019-11-24. Retrieved 2020-11-03. 
  8. Ekechukwu, Ferdinand (2019-11-09). "Burna Boy Relishes MTV EMA Trophy". THISDAYLIVE. Retrieved 2020-11-03. 
  9. "Remember you were Africans before you became anything else, Burna Boy’s mum gives epic speech at BET Awards". Punch Newspapers. 2016-06-19. Retrieved 2020-11-03. 
  10. "How Burna Boy Became Nigeria's Surprise Success Story". Billboard. 2020-10-10. Retrieved 2020-11-03. 
  11. "A look at Spaceship Collective; a rising indegenous record label". Businessday NG. 2020-09-04. Retrieved 2020-11-03. 
  12. "Burna Boy's parents, Samuel and Bose Ogulu celebrate 30th wedding anniversary". Linda Ikeji's Blog. 2020-09-02. Retrieved 2020-11-03.