Brukina
Ìrísí
Brukina tí a tún mọ̀ sí Burkina, ohun mímu ti Senegalese àti Ivorian. [1][2] ohun mímu tàbí ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí a fi ọkà bàbà ilẹ̀ ṣe àti mílíìkì. Brukina gbajúmọ̀ jù ní gbígbé jáde ní agbègbè àríwá ti Ghana. Ó tún jẹ́ mímọ̀ sí 'Deger'.
Àgbéyẹ̀wò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Brukina di gbígbà gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ pípé nítorí agbára rẹ̀ àti àkóónú asaralóooore tí ó.[3][4] Ó kún fún ọkà bàbà nìkan, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn irúgbìn àtijọ́, àti mílíìkì.[5]
Ṣíṣe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Brukina máa ń di ṣíṣe nípa lílo ọkà bàbà, mílíìkì màlúù ọ̀tun tàbí ẹbu mílíìkì, iyọ̀, omi àti súgà. Láti ṣe Brukina:
- Fọ ọkà bàbà náà kí o sì rẹ ẹ́ sómi mọ́jú
- Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, gbẹ omi náà kí o sì lọ ọkà bàbà náà sí ìrísí tí ó rí gbágungbàgun
- Gbé omi kaná
- Wa ọkà bàbà náà sínú alásẹ́ kí o sì fi ọwọ́ rẹ yí i títí o fi lè sọ ọ́ di bọ́ọ̀lù kéékèèké
- Nígbà tí omi náà bá gbóná, da àwọn bọ́ọ̀lù kéékèèké ti ọkà bàbà náà sínú abọ́ kí o sì dé e pẹ̀lú ìdérí
- De abọ́ náà dáadáa kí o sì jẹ́ kí ooru láti inú omi gbígbóná náà sè é rọ̀
- Nígbà tí àwọn bọ́ọ̀lù kéékèèké náà bá ti rọ̀ tí wọ́n bá sì ti sè, dà á sínú abọ́ kí o sì jẹ́ kí ó tutù
- Pò ó pẹ̀lú mílíìkì màlúù ọ̀tun tàbí ẹbu mílíìkì àti omi kí o sì pò ó papọ̀
- Fi súgà díẹ̀ si láti lè ní adùn
- Gbé e sínú ẹ̀rọ a-mú-nǹkan-tútù kí o sì bù ú. [1][6]
Àǹfààní ìlera
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọkà bàbà ní in Brukina kún fún magnesium, manganese, calcium, phosphorus, Vitamin B etc.
Mílíìkì náà kún fún Vitamin D àti Calcium.[7]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 "Burkina: Latest millet smoothie in town". www.ghanaweb.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2019-06-22. Retrieved 2019-06-22. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Recipe: Easy Steps To Prepare Burkina Drink". Modern Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2019-06-22. Retrieved 2019-06-22. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Burkina the Ghanaian drink you must try". Muse Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-01-26. Archived from the original on 2019-06-22. Retrieved 2019-06-22. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Dogbevi, Emmanuel (2013-09-05). "FDA trains 'Burkina' drink producers in Accra". Ghana Business News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2019-06-22. Retrieved 2019-06-22. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Brukina: A nutritious food contaminated with E. coli - MyJoyOnline.com". www.myjoyonline.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-06-16. Retrieved 2022-01-22.
- ↑ "NEWS". miczd.gov.gh. Archived from the original on 2020-06-06. Retrieved 2020-06-18. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:02