Cavafy Museum
Cavafy Museum jẹ́ musíọ́mù kan ní Alexandria, orílẹ̀ èdè Egypt, inú ilé tí musíọ́mù yìí sì wà jẹ́ ilé tí ó jẹ́ ibùgbé akéwì Griki kan, Constantine P. Cavafy nígbà ayé rẹ̀.
Ibi tí ó wà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ilé náà wà ní Alexandria Opera House (Fouad St.), ní Attarin division, Alexandria. Orúkọ òpópónà tí ilé náà wà ni Lepsius nígbà tí Cavafy sì wà láyé; wọ́n padà yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sharm El Sheikh, lẹyìn ìgbà tí wọ́n sí musíọ́mù náà, wọ́n tún yí orúkọ òpópónà tí ó wà sí Cavafy Street, ó sì sún mọ́ òpópónà méjì tí ó ṣe pàtàkì jù ní ìlú náà, Fouad St. àti Safiya Zaghloul St.
Àwọn ohùn tí ó wà nínú ibẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn ohun tí ó wà níbẹ̀ ni àwọn lẹ́tà, àkọọ́lẹ̀ àti ewì tí Cavafy kọ. Àwọn àwòrán àti fọ́tò Cavafy àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tún wà níbẹ̀, musíọ́mù náà tún jẹ́ ilé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àtijọ́.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |