Cellulitis

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Cellulitis
CellulitisSkin cellulitis
CellulitisSkin cellulitis
Skin cellulitis
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10L03. L03.
ICD/CIM-9682.9 682.9
DiseasesDB29806
MedlinePlus000855

Cellulitis jẹ́ àkóràn kòkòrò àìlèfojúrí bacteria tí ó ní ṣe pẹ̀lú inú ipele awọ ara. Ó maa ń dojú kọ ipele tí ó wà láàrín inú àti ìta ara pẹ̀lú ìpele ibí olọ́rá nínú awọ ara. Àmì àti àpẹẹrẹ tí a fì lè mọ̀ pé àkóràn yìí ti wọ ara ní pípọ́n ròdòrodo ara tí ó sì maa ń fẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀. Àwọn ààlà ibí pípọ́n yìí kìí mú tí ó sì maa ń fa kí awọ ara wú. Tí wọ́n bá raá ojú ibẹ maa funfun ṣùbọ́n kò kìí rí báyìí ní gbogbo ìgbà. Ojú ibi àkóràn yìí maa ń dun ènìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀.[1] Nígbà míràn àwọn ibi tí omi ara maa ń gbà lè fi ara gba,[1][2] tí ó sì lè fa ibà tàbí kí ó maa rẹ ènìyàn.[3]

Ẹsẹ̀ àti ojú ní ó sábà maa ń ràn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé kò sí ibi tí kò loè ràn lára. Ó maa ń sábà ran ẹsẹ̀ tí ara bá lè bó. Àwọn okùnfa míràn ní ìsanrajù àti ẹsẹ̀ wíwú, àti dídàrúgbó. Fún àkóràn ojú, kìí ṣe nípasẹ̀ ojú bíbó lásán. Àwọn àkóràn kòkòrò tí ó maa ń fàá ni  streptococci àti Staphylococcus aureus. Ní ìdàkejì sí cellulitis , erysipelas jẹ́ àkóràn kòkòrò àìlèfojúrí bacteria tí ó ní ṣe pẹ̀lú àwọn ipele ògééré awọ ara tí ó wà pẹ̀lú ibi pípọ́n àti àwọn igun tí ó hàn kedere, tí ó sì maa ń fa ibà.[1] Ó yẹ kí a fagi lé àwọn àkóràn tí ó lewu bíi àwọn èyí tí ó n ran egungun tàbí èyí tó ń ran awọ ara fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́.[2]

A maa ń ṣe ìwádìí àìsàn yìí làtàrí àwọn ààmì àti àpẹẹrẹ tí ó rọ̀ mọ́ọ, yíyọ sẹ́ẹ̀lì jádé fún ìwádìí kìí sábà ṣeéṣe.[1] Ìtọ́jú pẹ̀lú egbòògi tí ó ń pa àkóràn kòkòrò tí wọ́n maa ń gbà sí ẹnu bíi cephalexin, amoxicillin, tàbí cloxacillin, ní wọ́n maa ń sábà lò.[1][4] Àwọn tí ara wọn lòdì sí penicillin, lè lo erythromycin tàbí clindamycin.[4] Tí methicillin-resistant S. aureus (MRSA) bá jẹ́ ìṣòro, wọ́n lè júwe doxycycline tàbí trimethoprim/sulfamethoxazole fún wọn.[1] Ìsòro yìí ní ṣe pẹ̀lú ọyún  tàbí tí èyàn bá ní àkóràn MRSA tẹ́lẹ̀.[1][3] sítẹríọ́dù lè tète fa imúláradá fún àwọn tó ń lo egbògi apàkóràn lọ́wọ́.[1] Ṣíṣe àyẹ̀wó ní ojú ibí tí ó bá ràn ṣe pàtàkì[2] bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oògùn araríro[4]

Ìyàtọ̀ maa ń wà fún àwọn ènìyàn bíi 95% lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wá tí wọ́n bágba ìtọ́jú.[3] Ìnira tí ó rọ mọ ni eéwo.[1] àkóràn kòkòrò àìlèfojúrí bacteria ran àwọn ènìyàn bíi mílíọnù 155 tí cellulitis sì ran ènìyàn bí mẹ́tàdínlógójì ní ọdún 2013.[5] Cellulitis ní ọdún 2013 ṣe okùnfà ikú àwọn ènìyàn bíi ẹgbẹ̀rú mẹ́ta jákèjádò gbogbo àgbáyé.[6] Ní United Kingdom, cellulitis ni ìdí tí wọ́n fi dá 1.6% gbogbo àwọn  ènìyan tí ó wá sí ilé ìwòsàn dùbúlẹ̀.[4]

Àwọn ààmì àti àpẹẹrẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ààmì àti àpẹẹrẹ cellulitis ni pípọ́n ròdòròdò, gbígbóná àti ìrora lójú ibí tí ó bá ràn. Àwòrán wọ̀nyìí ṣe àfihàn èyí tí kò léwu púpọ̀, kò si ń ṣe ìgbà tí ó bá kọ́kọ́ ran ènìyàn.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 1.6 1.7 1.8 Vary, JC; O'Connor, KM (May 2014).
  2. 2.0 2.1 2.2 Tintinalli, Judith E. (2010).
  3. 3.0 3.1 3.2 Mistry, RD (Oct 2013).
  4. 4.0 4.1 4.2 4.3 Phoenix, G; Das, S; Joshi, M (Aug 7, 2012).
  5. Global Burden of Disease Study 2013, Collaborators (22 August 2015).
  6. GBD 2013 Mortality and Causes of Death, Collaborators (17 December 2014).