Chantal Youdum
Chantal Youdum | |
---|---|
Orílẹ̀-èdè | Cameroonian |
Iṣẹ́ | Film director, film producer |
Ìgbà iṣẹ́ | 2011-present |
Chantal Youdum jẹ́ olùdarí eré àti agbéréjáde ọmọ orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù
Ìsẹ̀mí rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2011, Youdum ṣẹ̀dá eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Au coeur de l'amour, èyítí wọ́n gbé sáfẹ́fẹ́ lóri ìkànnì TV5 àti Canal 2. Eré náà dá lóri ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí kò mọ bàbá rẹ̀, ó sì ṣàfihàn àwọn òṣèré bíi Valérie Duval, ẹnití ó rọ́pò òṣèrébìnrin Rouène.[1] Youdum darí fíìmù ti ọdún 2014 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Sweet Dance, èyí tí n ṣàfihàn Pélagie Nguiateu àti Alain Bomo Bomo.[2]
Ní ọdún 2016, wọ́n yan Youdum gẹ́gẹ́bi ọ̀kan nínu àwọn obìnrin méje tí wọ́n mú ìdàgbàsókẹ̀ bá ìwé-ìtàn kíkọ ní ilé Áfríkà.[3] Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ olùṣàkóso ìpele fún ti eré Aissa ní ọdún 2017, èyítí Jean Roke Patoudem darí. Eré náà dá lóri ìtàn ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí ó ní láti lọ gbé pẹ̀lú bàbá rẹ̀ ní abúlé míràn. Wọ́n kọ́kọ́ gbé eré Aissa jáde níbi ayẹyẹ Panafrican Film and Television Festival of Ouagadougou àti Vues d'Afrique Festival.[4] Ní ọdún 2017 yìí bákan náà, Youdum darí eré Rêve corrompu.[5] Eré náà dá lóri ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ó fi abúlé rẹ̀ sílẹ̀ láti lọ gbé ní ààrin ìlú nírètí láti ṣóríire níbẹ̀. Eré náà gba àmì-ẹ̀yẹ níbi ayẹyẹ Écrans Noirs Festival ti ọdún 2018.[6]
Ní ọdún 2018, Youdum lọ́wọ́sí ṣíṣẹ̀dá eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Mimi la Bobonne, pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Francis Tene. Wọ́n ṣe ìfihàn eré náà níbi ayẹyẹ Festival International de Films de Femmes ní ìlú Yaoundé.[7]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Bangoua, Prince De (1 November 2013). "Valérie Duval : " On ne valorise pas le mannequinat et la culture au Cameroun "". Culturebene (in French). Retrieved 3 November 2020.
- ↑ "Longs Métrages, France". Patou Films International (in French). Retrieved 3 November 2020.
- ↑ Bomo, Andrea (7 August 2016). "Reshaping The African Women Narrative". Femmes Lumière. Archived from the original on 12 October 2019. Retrieved 3 November 2020.
- ↑ "Avant-première de la série web ‘AISSA’ dans les Salles Canal Olympia". Cameroun Web (in French). 8 February 2018. Retrieved 3 November 2020.
- ↑ "Le cinéma féminin célébré pour la 8ème fois au Cameroun". Africine (in French). Retrieved 3 November 2020.
- ↑ "RECOMPENSES: DEUX FILMS CAMEROUNAIS EN LICE AUX TROPHÉES FRANCOPHONES DU CINEMA 2018". Le Film Camerounais (in French). Retrieved 3 November 2020.
- ↑ Medjorn, Colbie (21 June 2018). "Festival International de Films de Femmes Mis Me Binga 2018 : Du 26 au 30 Juin 2018". Kulture Master Online (in French). Archived from the original on 29 October 2021. Retrieved 3 November 2020.