Jump to content

Chidinma àti Chidiebere Aneke

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ìwé-alàyé[ìdá]
Chidinma àti Chidiebere Aneke
Ọjọ́ìbíChidinma àti Chidiebere Aneke
24 Oṣù Kẹjọ 1986 (1986-08-24) (ọmọ ọdún 38)
Enugu, Ìpínlẹ̀ Enugu, Nàìjíríà
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Nigeria, Nsuka
Iṣẹ́Òṣèrébìnrin àti Olóòtú sinimá àgbéléwòCV

Chidinma àti Chidiebere Aneke jẹ́ gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́ká Òṣèrébìnrin àti Olóòtú sinimá àgbéléwò ìbejì tí wọ́n jọ ara wọn lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ẹgbẹ́ Nollywood tí wọ́n máa ń pè ní Ìbejì Aneke. Wọ́n jẹ́ àbígbẹ̀yìn àwọn òbí wọn àti ọmọ bíbí ìlú Ìpínlẹ̀ Enugu lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [1]

Ìgbésí ayé àti ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn láti ìbẹ̀rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Chidinmma àti Chidiebere lọ́jọ́ kẹfà oṣù kẹjọ ọdún 6 1986 ní Ìpínlẹ̀ Enugu, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ọmọ ilé-olórogún òníyàwó mẹta niwọ́n. Bàbá wọn jẹ olówó àti ọlọ́rọ̀ tí ó fi owó àti ọlà kẹ́ wọn láti ìgbà èwe wọn, ṣùgbọ́n èyí yí padà ní kété tí bàbá wọn ṣaláìsí, tí àwọn ẹbí sìn pín ogún rẹ̀ láàárín ara wọn.

Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn ní Ìpínlẹ̀ Enugu kí wọ́n tó tẹ̀ síwájú ẹ̀kọ́ gíga ní University of Nigeria, Nsuka níbi tí wọ́n ti kàwé gboyè nínú ìmọ̀ eto ìbánisọ̀rọ̀ àti ìmọ̀ ìfowópamọ́ àti ìsúná-owó lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.[2]

Àwọn ìbejì Aneke bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà lọ́dún 1999, tí wọ́n sì kópa àkọ́kọ́ nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Enuka. Sinimá yìí ló mú ògo wọn bú yọ lágbo òṣèrẹ̀ sinimá àgbéléwò Nollywood. Lọ́dún 2004,àwọn ìbejì wọ̀nyí tún kópa nínú gbankọgbì sinimá kan tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Desperate Twins, èyí mú kí wọn gbajúmọ̀ sí i, tí wọ́n sìn yàn wọ́n mọ́ àwọn tí wọ́n díje fún Òṣèrébìnrin tí ìràwọ̀ wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní tán lórí the African Magic Viewers’ Choice Award. Wọn ti kópa nínú sinimá tó ju ọgọ́rin lọ. Bẹ́ẹ̀ náà àwọn ti gbé oríṣiríṣi sinimá jáde fún ara wọn. Lára àwọn sinimá wọn mi; ‘Heart of Isiaku’, ‘Onochie’, ‘Broken Ambition’’, àti ‘Adaora’.[3]

Àṣàyàn àwọn sinimá wọn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Jealous Friends[4]

Desperate Twins[5]

Lagos Girls[6]

Broken Ambition[7]

Humanitarian Award [8]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]