Chimamanda Ngozi Adichie

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Chimamanda Ngozi Adichie
Adichie, Fairfax, 2013
Ọjọ́ ìbí15 Oṣù Kẹ̀sán 1977 (1977-09-15) (ọmọ ọdún 46)
Enugu, Enugu State, Nigeria
Iṣẹ́Novelist, short story writer, nonfiction writer
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Ìgbà2003 — present
Notable worksPurple Hibiscus
Half of a Yellow Sun
Americanah
Notable awardsMacArthur Fellowship (2008)
Chimamanda Ngozi Adichie talks about The Thing Around Your Neck on Bookbits radio.

Chimamanda Ngozi Adichie ( /ˌɪmɑːˈmɑːndə əŋˈɡzi əˈd/;

Ọjọ́ kẹẹ̀dógún, Oṣù Ọ̀wàrà, Ọdún 1977 ni wọ́n bí Chimamanda Ngozi Adichie. Òǹkọ̀wé ni lára àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ni ìwé ìtàn àròsọ, Ìwé ìtàn àròsọ kúkúrú àti ìwé ìtàn àròsọ ajẹmọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ gidi. Wọ́n ṣe àpèjúwe rẹ̀ nínú "Times in Literary Supplement"  gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ó tayọ jùlọ nínú àwọn Òǹkọ̀wé elédè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́, tí ó sì ṣe àṣeyọrí láti fojú àwọn ọwọ́ ìran òǹkàwé tuntun mọ́ra sí lítíréṣọ̀ Áfríkà, pàápàá jùlọ ní ibùdó rẹ̀ kejì Nàìjíríà.[2] [3]

Ẹ̀kọ́ àti ìṣe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adichie tí kọ àwọn ìwé Purple Hibiscus ní ọdún 2003, Half of a Yellow Sun ní ọdún 2006 àti Americanah ní ọdún 2013, Àkópọjọ̀ ìtàn kúkúrú The Thing Around Your Neck ní ọdún 2009 àti ìwé àrokọ̀ gígùn We should All Be Feminist ní ọdún 2014. Àwọn ìwé rẹ̀ tí ó jẹ́ tuntun ni Dear Ijeawele, or A Feminist Manifesto in Fifteen Suggestion ní ọdún 2017, Zikora ní ọdún 2020 àti Notes on Grief ní ọdún 2021. Ní ọdún 2008, ó gba àmì ẹ̀yẹ ètò MacArthur Genius Grant. Òun ló gba àmì ẹ̀yẹ PEN Pinter Prize ní ọdún 2018

Iléẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndìrì Yunifásítì ti Naijiria, Nsukka ni Adichie ti parí ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndìrì rẹ̀ níbi tí ó ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ ajemọ́ akadá. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó àti ìmọ̀ nípa oògùn ní Yunifásítì ti Nàìjíríà fún ọdún kan àti àbọ̀.  Ní àsìkò náà ni ó siṣẹ́ olótùú ìwé ìròyìn Compass tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìjọ àgùdá ń ṣe àkóso rẹ̀. Ó kúrò ní Orílẹ̀èdè Nàìjíríà lọ sí United States lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlogún láti lọ kọ́ ìmọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ àti sáyẹ̀nsì òṣèlú ní Yunifásítì Drexel ní Philadelphia Pennsylvania.

Ní ọdún 2003, Adichie parí ẹ̀kọ́ òye ìjìnlẹ̀ nínú àròkọ àtinúdá ní Yunifásítì John Hopkins.

Ẹbí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún 2009 ni Adichie fẹ́ Ivara Esege, oníṣègùn òyìnbó ọmọ Nàìjíríà. Wọ́n bí ọmọbìnrin kan ní ọdún 2016. Adichie ń pín àsìkò rẹ láàárín United States àti Nàìjíríà, níbi tí ó ń kọ́ àwọn èèyàn nípa àròkọ.

Àwọn ìwé tí ó kọ tàbí kópa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Brockes, Emma (4 March 2017). "Chimamanda Ngozi Adichie: 'Can people please stop telling me feminism is hot?'". The Guardian. ISSN 0261-3077. Retrieved 22 August 2017.

"Chimamanda Ngozi Adichie". Front Row. 3 May 2013. BBC Radio 4. Retrieved 18 January 2014.

"Chimamanda Ngozi Adichie Biography | List of Works, Study Guides & Essays | GradeSaver". gradesaver.com.

Luebering, J.E. "Chimamanda Ngozi Adichie | Biography, Books, & Facts". Encyclopedia Britannica. Retrieved 19 May 2021.

Nixon, Rob (1 October 2006). "A Biafran Story". The New York Times. ISSN 0362-4331. Archived from the original on 15 September 2012.

Copnall, James (16 December 2011), "Steak Knife", The Times Literary Supplement, p. 20.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Chimamanda Ngozi Adichie". Front Row. 3 May 2013. BBC Radio 4. Retrieved 18 January 2014. 
  2. "Official Author Website". Chimamanda Ngozi Adichie. 2017-06-27. Retrieved 2020-01-02. 
  3. "Chimamanda Ngozi Adichie - Biography, Books, & Facts". Encyclopedia Britannica. 1977-09-15. Retrieved 2020-01-02.