Chinenye Akinlade
Chinenye Ochuba-Akinlade jẹ ọ̀dọ́mọbìnrin tó wà nípò ìdíje ẹlẹ́wà ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ochuba-Akinlade ni ọmọ keje nínú ọmọ méjọ, ó tún jẹ́ ìbejì. Ọmọ Ígbò ni. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ gírámà rẹ̀ ní Regan Memorial Secondary School, ó gbóyè nínú ìdíje 2002 ti ọ̀dọ́bìnrin tó rẹ́wà jù lọ ní Nàìjíríà nígbà tí ó ń dúró de gbígba wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga. [1] Bí ó ti jẹ́ pé ó jẹ́ àyànfẹ́ fún adé "Miss Universe 2002", ó kùnà láti ṣe mẹ́wàá tí ó ga jùlọ, ṣùgbọ́n ó dára jùlọ ní Miss World, níbi tí ó ti jẹyọ láàrín ọmọbìnrin mẹ́wàá tí ó dára jùlọ nínú ìdíje, bákan náà bí African Continental Queen of Beauty. [2]
Ochuba-Akinlade ti jẹ́ akékòó tẹ́lẹ̀ ní Fásítì ti Èkó, Ochuba-Akinlade parí òye rẹ̀ nípa Accounting and Financing ní University of Greenwich, London ní ọdún 2008, ó parí èkó rẹ̀ pẹ̀lú kíláàsì kejì (second class upper). [3] Ó padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, níbití ó ti fẹ́ oníṣòwò Kunle Akinlade, ó sì ṣiṣẹ́ fún ilé iṣẹ́ epo Exxon Mobil. Ochuba-Akinlade ti bí ọmọ méjì báyìí. [4]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ MBGN 2002 Archived 12 May 2005 at the Wayback Machine.
- ↑ "Chinenye Ochuba- Epitome of Black Beauty". www.gisters.com. Archived from the original on 2008-09-06. Retrieved 2017-08-29. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Chinenye Graduates Archived 29 April 2010 at the Wayback Machine.
- ↑ Ochuba-Akinlade gets groovy[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]