Jump to content

Krómósómù

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Chromosome)
Àwòrán krómósómù ẹ̀ùkáríọ́tì tó ti jẹ́ títúndá. (1) Chromatid – one of the two identical parts of the chromosome after S phase. (2) Centromere – the point where the two chromatids touch, and where the microtubules attach. (3) Short arm. (4) Long arm.

Krómósómù jẹ́ àdìmú alátòjọ DNA àti proteínì tó wà nínú àwọn àhámọ́. Ó jẹ́ DNA lílọ́po kan soso tó ní ọ̀pọ̀ àwọn àbímọ́, àwọn apilẹ̀sẹ̀ onílànà àti àwọn ìtèlẹ́ntẹ̀lẹ́ núkléótídì míràn. Àwọn krómósómù tún ní àwọn proteínì alẹ̀mọ́ DNA, tí wọ́n jẹ́ bíi pálí fún DNA àti láti kóìjánu àwọn ìmúṣe rẹ̀.

Àwọn krómósómù yàtọ́ gidigidi sí ra wọn láàrin orísi àwọn ohun ẹlẹ́ẹ̀mí. Hóró DNA le jẹ́ olóbìírípo tàbí onígbọọrọ, bẹ́ sì ni inú rẹ̀ le ní núkléótídì tó pọ̀ tó 100,000 dé 10,000,000,000[1] lórí èwọ̀n gígún kan. Àwọn àhámọ́ eukarioti (àwọn àhámọ́ tí wọ́n ní kóróonú) ní krómósómù onígbọọrọ títóbi nígbàtí àwọn àhámọ́ prokarioti (àwọn àhámọ́ tí kò ní kóróonú) ní krómósómù olóòbírípo kékeré, bótilẹ̀jípé àwọn ìsàtì sí òfin yìí wà. Bákannáà, àwọn àhámọ́ tún le ní ju irú kan krómósómù lọ; fún àpẹre, mitokọ́ndríà nínú ọ̀pọ̀ àwọn eukarioti àti adáláwọ̀ nínú àwọn ọ̀gbìn ní àwọn krómósómù kékeré ti wọn.

Nínú àwọn eukarioti, àwọn krómósómù nínú kóróonú jẹ́ dídìpọ́ látọwọ́ àwọn proteínì sí àdìmú kíkipọ̀ kan tó únjẹ́ kromatínì. Èyí jẹ́ kí àwọn hóró DNA gígùn ó le wọ inú kóróonú àhámọ́. Àdìmú àwọn krómósómù àti kromatínì yàtọ̀ pẹ̀lú ìpínyà àhámọ́. Àwọn krómósómù ṣe pàtàkì fún ìpínyà àhámọ́, wọ́n sì gbọdọ̀ jẹ́ títúndá, pínpín, àti jẹ́ kíkó sínú àwọn àhámọ́ ọmọ wọn láìsí sòró láti baà ridájú pé orísirísi àbímọ́ àti ìwàláàyè wà fún àwọn ọmọọmọ wọn. Àwọn krómósómù le wà bóyá bí i áṣẹ́po tàbí aláìṣẹ́po. Àwọn krómósómù aláìṣẹ́po jẹ́ atínrín onígbọọrọ kansoso, nígbàtí àwọn krómósómù aṣẹ́po ní àwòkọ méjì tí wọ́n jọ ara wọn (wọ́n únjẹ́ krómátídì) jẹ́ sísopọ̀ pẹ̀lú sentrómẹ́rì.


  1. Paux E, Sourdille P, Salse J, et al. (2008). "A Physical Map of the 1-Gigabase Bread Wheat Chromosome 3B". Science 322 (5898): 101–104. doi:10.1126/science.1161847. PMID 18832645.