Jump to content

Clem Ohameze

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Clem Ohameze
Clem Ohameze at a party, August 2011
Ọjọ́ìbí27 Oṣù Kẹfà 1965 (1965-06-27) (ọmọ ọdún 59)
Port Harcourt, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Orúkọ mírànClem
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Port Harcourt
Iṣẹ́Actor
Ìgbà iṣẹ́1995-present
Ọmọ ìlúOguta, Imo State, Nigeria

Clem Ohameze jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ti ń ṣeré fún nǹkan bí ogún ọdún sẹ́yìn.[1] Clem Ohameze bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún 1995. Ṣùgbọ́n ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbajúmọ̀ ní kété tí ó kópa nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ End TIME.[2] Ó ti kópa nínú sinimá àgbéléwò tó ti to ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) fún ọdún ogún tí ó ti ń ṣeré láti ọdún 1995 títí di àkókò yìí.

Wọ́n bí Clem Ohameze lọ́jọ́ kẹtàdínlógbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 1965 (27 June 1965) nílùú Port Harcourt, ní ìpínlẹ̀ Rivers, lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Holy Family College/Baptist High School fún ẹ̀kọ́ ilé-ìwé gírámà. Ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Institute of Management Technology, Enugu, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi tí ó ti kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú Dípólómà nínú ìmọ̀ Ìbánisọ̀rọ̀[3]. Bákan náà ó lọ sí University of Port Harcourt níbi tí ó ti kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú dìgírì nínú Ìmọ̀ Àyíká àti Ènìyàn (Ìṣeọ̀rọ̀àwùjọ àti Anthropology) lọ́dún 1989. Bákan náà, ó tún kàwé gboyè dìgírì kejì nínú ìmọ̀ ìṣègùn àbò àti àyíká ní òkè-òkun ní Buckingham University, ní London lọ́dún 2010.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Clem Ohameze battles for The Kingdom". Vanguardngr.com. 2012-10-27. Retrieved 2013-09-21. 
  2. "Clem Ohameze Makes Nollywood Comeback With Eucharia Anunobi, Others In The Kingdom". nigeriafilms.com. 2012-11-03. Archived from the original on 2013-09-21. Retrieved 2013-09-21. 
  3. Suleiman, Taiye (2008-04-07). "Nollywood Photo Blog: Pictorial Glance at Clem Ohameze of Nollywood". Nollywood Photo Blog. Retrieved 2017-02-21.