Cleopatra Tawo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Cleopatra Tawo
Ọjọ́ìbí29 October
Port Harcourt, Rivers State, Nigeria
Aláìsí(2017-12-01)1 Oṣù Kejìlá 2017
University of Uyo Teaching Hospital, Akwa Ibom State, Nigeria
Orúkọ mírànCleo, Cleo Tao
Iṣẹ́Radio host
Ìgbà iṣẹ́2000–2017

Cleopatra Tawo tí orúkọ inagi rẹ jẹ Cleo Tao jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí rádíiò ni ilé iṣẹ́ Planet Fm 101.1 Fm ni ìlú Uyo ni ìpínlẹ̀ Akwa Ibom. Òun ni atọ́kun ètò Day Break on Planet àti AutoMania. Kí ó tó darapọ̀ mọ́ Planet Fm, Tawo tí si ṣé pẹ̀lú Rythm Fm 93.7 ni ìlú Portharcourt ni ìpínlẹ̀ Rivers gẹ́gẹ́ bíi atọ́kun fún àwọn ètò bíi Morning Drive, Afternoon Drive, Sunday at the Rhythm àti Midnight Caller.[1] Tawo kọ́ iṣẹ́ agbejọ́rò kí ó tó padà wá di agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ni ọdún 2000. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ni Rythm Fm 93.7 ni ìlú Portharcourt. Ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kejìlá, ọdún 2005, àwọn agbófinró mú òhun àti Klem Ofuokwu lórí ẹ̀sùn pé wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà afárá tí ó bà jẹ́.[2][3] Wọ́n lọ ọ̀sẹ̀ méjì ní àtìmọ́lé kí wọn tó fí àwọn méjèèjì náà lẹ̀.[4] Ní ọjọ́ kìíní oṣù kejìlá, ọdún 2017 ni ó fi àyè sílẹ̀, ó kú sí ilé ìwòsàn tí University of Uyo Teaching Hospital.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]