Colleen Higgs
Colleen Higgs (ni a bí ní ọdún 1962 ní Kimberley, Gúúsù Áfíríkà) ó jẹ́ òǹkọ̀wé àti atẹ̀wéjáde ti Gúúsù Áfíríkà. Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé, ó ti ṣe Àtẹ̀jáde ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé ewì àti ìtàn kékéèké nínú ìwé àtìgbàdégbà ní Gúúsù Áfríkà bẹ̀rẹ̀ láti bí ọdún 1990. Gẹ́gẹ́ bí atẹ̀wéjáde, ó jẹ́ gbajúgbajà àti ẹni-ọ̀wọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ìtẹ̀wéjáde "independent publishing house, Modjaji Books".
Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Higgs lọ ìgbà ọmọdé rẹ̀ ní ìlú Lesotho, ìgbà èwe àti ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ ló lò ní ìlú Johannesburg, ní lọ́ọ́lọ́ yìí ni ó lò ọdún márùn-ún ní ìlú Grahamstown. Ní ìlú Cape Town ni ó ń gbé báyìí. Ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, Ẹni tó ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn olùkọ́, òǹkọ̀wé àti olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga amẹ́kọ̀ọ́gbòòrò àti olùdarí ètò ilé-iṣẹ́ "The Centre for the Book" . Ó jẹ́ olùdásílẹ̀ àti atẹ̀wéjáde ní ilé-iṣẹ́ ìtẹ̀wéjáde "Modjaji Books", ilé-iṣé ìtẹ̀wéjáde tó dá dúró tí ó sì wà ní ìlú Cape Town, èyí tó ń tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé tí àwọn obìnrin ń kọ jáde. Ní báyìí àwọn ìtàn kékéèké, ìwé ìtàn-ara-ẹni, ìtàn, ìwé-ewì àti ìtàn-abójú-ayé-mu tí ilé-iṣẹ́ ìtẹ̀wéjáde tí tẹ̀ jáde: Whiplash by Tracey Farren ni a kà mọ́ àwọn ìwé ìtàn a bójú-ayé-mú fún àmì-ẹ̀yẹ Times Fiction award.[1]
Higgs tún jẹ́ akéwì, tí a sì ti ń tẹ ewì rẹ̀ jáde nínú ìwé-àtìgbàdégbà láti nǹkan bí ọdún 1990. Ìwé àkójọpọ̀ ewì rẹ̀ àkọ́kọ́ction, Halfborn Woni a tẹ̀ jáde ní ọdún 2004.[2]
Ìkànnì ayélujára rẹ̀ (on BooksLive) ni à ń ṣe àfikún láti ìgbàdégbà pẹ̀lú àwọn àkòónú àtúngbéyẹ̀wò, ìròyìn, àwọn àpilẹ̀kọ àti ojú-àmúwayé lórí ìtẹ̀wéjáde Gúúsù Áfíríkà.[3] Ní ọdún 2020 ni a tẹ ìwé ìtàn nípa ara-ẹni rẹ̀ My Mother, My Madness jáde.[4]
Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Halfborn Woman (2004), Hands-On Books collection of poems
- A Rough Guide to Small-scale and Self-publishing (2005), Centre for the Book
- South African Small Publishers' Catalogue (editor with Maire Fisher) (2006), Centre for the Book
- Small Publishers' Catalogue - Africa, 2010 (2010) (editor with Bontle Senne)
- Lava Lamp Poems (2011), Hands-On Books, collection of poems
- Looking for Trouble: mostly Yeoville stories (2012), Hands-On Books, collection of stories
- Small Publishers' Catalogue - Africa, 2013 (2013)
- My Mother, My Madness (2020), Deep South
Àwọn Ìwé Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Colleen Higgs on Modjaji Books Archived 31 January 2010 at the Wayback Machine.. Retrieved 28 October 2009.
- ↑ Roll Over, Gutenberg! Interview with Colleen Higgs Archived 12 May 2008 at the Wayback Machine., Absolut Write. Retrieved 7 February 2008.
- ↑ Colleen Higgs' Bookslive Blog Archived 2012-03-13 at the Wayback Machine.. Retrieved 28 October 2009.
- ↑ "Founder of Modjaji Books Publishes New Memoir on Her Mother’s Final Years". 31 July 2020. https://brittlepaper.com/2020/07/founder-of-modjaji-books-publishes-new-memoir-on-motherhood/.