Corine Onyango

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Corine Onyango
Ọjọ́ìbíÀdàkọ:Birth based on age as of date
Orílẹ̀-èdèKenyan
Iléẹ̀kọ́ gígaNorthwestern University
Iṣẹ́Actress, radio presenter
Ìgbà iṣẹ́2008-present
Notable workFrom a Whisper (2008)

Corine Onyango (tí wọ́n bí ní ọdún 1984/1985 ) jẹ́ òṣèrébìnrin àti atọ́kùn ètò orí rédíò ọmọ orílẹ̀-èdè Kẹ́nyà

Ìsẹ̀mí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Onyango ní orílẹ̀-èdè Kẹ́nyà. Bàbá rẹ̀ jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ tí ó wà fún ìdàgbàsókè ilẹ̀ Áfríká, African Development Bank. Ó ti lo àwọn ìgbà ayé rẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Kẹ́nyà, Ivory Coast, Tùnísíà, Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì, Sìmbábúè àti Amẹ́ríkà.[1] Onyango gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ ìbaraẹnisọ̀rọ̀ láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Northwestern University ní ọdún 2007.[2] Lẹ́hìn ìparí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó padà sí Kẹ́nyà pẹ̀lú ìpinnu láti wá lo àkókò ìsimi rẹ̀ níbẹ̀, ṣùgbọ́n ó yí èrò rẹ̀ padà lẹ́yìnwá tó sì pinnu láti fi Kẹ́nyà ṣe ìbùgbé.[3] Onyango gba iṣẹ́ atọ́kùn ètò rédíò ní ilé-iṣẹ́ Homeboyz Radio. Ó di atọ́kùn fún ètò "The Jumpoff'. Onyango ṣàpèjúwe iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bi ẹ̀kọ́ fún òun àti fún ilé-iṣẹ́ náà fúnrarẹ̀.

Ní ọdún 2008, Onyango ṣe àkọ́kọ́ ipa fíìmù rẹ̀ nínu eré Wanuri Kahiu kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ From a Whisper. Ó kópa gẹ́gẹ́ bi Tamani, ọmọbìnrin kan tí ìyá rẹ̀ ṣaláìsí ní àkókò ìṣẹ̀mílófó kan tí ó wáyé ní ìlú Nàìróbì ní ọdún 1998.[4] Wọ́n yan Onyango fún àmì-ẹ̀ye amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Africa Movie Academy Awards.[5] Ní ọdún 2010, Onyango tún kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí ó wà fún àwọn ọmọdé tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Tinga Tinga Tales.[6]

Onyango ti bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ n ṣe King Kwe.[7] Ọmọ náà ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Faransé.[1]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • 2008: From a Whisper
  • 2010: Tinga Tinga Tales (TV series)

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 n ti Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name "best" defined multiple times with different content
  2. orú
  3. rẹ̀
  4. ṣe
  5. ọ na
  6. ̀ ń
  7. ́sì

Àwọn ìtakùn Ìjásóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]