Cyprian Ekwensi
Cyprian Ekwensi |
---|
Cyprian Ekwensi jẹ́ òǹkọ̀wé ọmọ Orílẹ̀èdè Nàìjíríà.
ÌBẸ̀RẸ̀PẸ̀PẸ̀ AYÉ ÀTI Ẹ̀KỌ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Cyprian Odiatu Duaka Ekwensi jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ìgbò tí wọ́n bí sí ìlú Minna, Ìpínlẹ̀ Niger. Ọmọ bíbí ìlú Nkwelle Ezunaka ní Ìjọba ìbílẹ̀ Oyi, Ipinle Anambra, Nàìjíríà. Bàbá rẹ̀ ni David Anadumaka, apàlọ́ àti ọdẹ aperin. Ekwensi lọ sí Government College ní Ìbàdàn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Achimota College ní Ghana àti Iléẹ̀kọ́ ìmọ̀ ajẹmọ́-igbó Ìbàdàn, leyin náà ló ṣisẹ́ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ asọ́gbó fún ọdún méjì. Bákan náà ló lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ṣẹ́ Yaba Technical Institute, àti Iléẹ̀kọ́ nípa oògùn ní ìlú Èkó, Lagos School of Pharmacy àti Iléẹ̀kọ́ Chelsea nípa oògùn ní Yunifásítì ti London. Ó siṣẹ́ Olùkọ́ ní Kọ́lẹ́jì Igbóbì (Igbóbì College)
ẸBÍ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ekwensi fẹ́ Eunice Anyiwo, wọ́n sì bí ọmọ márùn-ún pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọọmọ, lára wọn ni Cyprian Ikechi Ekwensi tí wọ́n sọ nù orúkọ bàbá bàbá rẹ̀ àti Adrianne tí i ṣe ọmọọmọ tí ó dàgbà jù
IṢẸ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n yan Ekwensi ní olórí ajẹmọ́-àwòmọ́ ní Iléeṣé Iroyin Orílẹ̀èdè Nàìjíríà (Nigerian Broadcasting Corporation), bákan náà ni ẹ̀ka ìròyìn yàn án sípò ni àsìkò ìjọba Olómìnira àkọ́kọ́. Ó padà di olùdarí ẹ̀ka náà. Ó fi iṣẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 1966 ṣáájú ogun Abẹ́lé. Ó kó àwọn ẹbí rẹ̀ padà sí Enugu. Bákan náà ló jẹ́ alága Àjọ fún ìpolongo ìlú Biafra.
Ekwensi tí kọ ogúnlọ́gọ̀ àwọn ìtàn kéékèèké, eré onísẹ́ fún rédíò àti tẹlifíṣàn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ìtàn àròsọ pẹ̀lú àwọn ìwé ọmọdé.
IKÚ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ekwensi di olóògbé ni ọjọ́ kẹrìn, Oṣù Ọ̀wàrà Ọdún 2007 ní Niger Foundation ní ìlú Enugu níbi tí ó ti lọ ṣe iṣẹ́ abẹ fún àìsàn tí wọ́n kó sọ di mímọ̀. Ẹgbẹ́ àwọn Òǹkọ̀wé fẹ́ fún ní àmì ẹ̀yẹ ṣáájú ikú rẹ̀, wọn padà fi ṣe ìyẹ́sí fún un lẹ́yìn ikú rẹ̀
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
ÌTỌ́KASÍ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]"Cyprian Ekwensi dies at 86". Daily Trust online. 6 November 2007. Retrieved 21 November 2007.
"Nigeria Today Is Like A Yarn By Cyprian Ekwensi -". The NEWS. 1 December 2021. Retrieved 6 March 2022.
Adenekan, Shola (11 November 2007). "Prolific Writer Who Chronicled Modern Life in West Africa". The New Black Magazine online. Retrieved 21 November 2007.
Gérard, Albert S. (1986). European-Language Writing in Sub-Saharan Africa. John Benjamins Publishing Company. p. 654. ISBN 963-05-3834-2.
"Cyprian Ekwensi". Encyclopedia of World Biography. Thomson Gale.
CHUKA NNABUIFE (29 October 2009). "Authors convention begins in Minna". Nigerian Compass. Retrieved 9 November 2009.[permanent dead link]
"Ekwensi, Cyprian". Africana: The Encyclopedia of the African and African American Experience. Running Press. 2003. pp. 226–227. ISBN 0-7624-1642-4.
Gérard, p. 656.
"Jagua Nana's Daughter". Michigan State University Press. Archived from the original on 10 May 2007. Retrieved 21 November 2007.
"ANA plans post humous award for Ekwensi". The Tide Online. Rivers State Newspaper Corporation. 11 November 2007. Archived from the original on 17 July 2011. Retrieved 21 November 2007.
- "ANA plans post humous award for Ekwensi". The Tide Online. Rivers State Newspaper Corporation. 11 November 2007. Archived from the original on 17 July 2011. Retrieved 21 November 2007.