Dámilọ́lá Anwo-Ade
Damilola Anwo-Ade | |
---|---|
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Orúkọ míràn | Damilola Anwo-Ade |
Iṣẹ́ |
|
Dámilọ́lá Anwo-Ade tí í ṣe ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ olùṣàkóso Sprout Digital Development Limited tí ó ń bá ṣiṣẹ́ pọ̀. Òun sì ni olùdásílẹ̀ CodeIT.[1]
Ètò-ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Babcock University ni Dámilọ́lá lọ tí ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Information Resources Management ní ọdún 2003 wọ ọdún 2007. Ó tẹ̀ síwájú láti gba oyè Master's degree nínú Education Planning and International Development ní The Institute of Education, U ní ìlú London lọ́dún 2012. Dámilọ́lá ni olùṣàkóso Sprout Digital Development Limited tí ó ń bá ṣiṣẹ́ pọ̀.[2] Sprout jẹ́ ọ̀kan lára àwọn irinṣẹ́ ayélujára tó máa ń pèsè ojútùú fún àwọn ilé-iṣẹ́ àti òwò lóríṣiríṣi.[3]
Bákan náà, CodeIT jẹ́ ọ̀kan lára àwọn irinṣẹ́ ayélujára tó máa ń pèsè àyè sílẹ̀ fún àwọn ọmọdé (ọmọ ọdún márùn-ún sí méjìdínlógún) láti nímọ̀ lórí àwọn irinṣẹ́ ayélujára. Dámilọ́lá ti ṣiṣẹ́ ribiribi lórí ICT. Ó máa ń pèsè iṣẹ́ lóríṣiríṣi tó dá lórí ayélujára láti mu lọ ìpele tó kàn. Ó ti ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ ICT lóríṣiríṣi níbi tó ti ń kọ́ àwọn èèyàn ní Intel àti UN Women Nigeria.[4]
Látipa ṣẹ̀ iṣẹ́ ribiribi rẹ̀, U.S. Department of State's Bureau of Educational and Cultural Affairs yàn-án gẹ́gẹ́ bíi ọ̀kan lára àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní Silicon Valley lọ́dún 2017.[5]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Damilola Anwo-Ade – Medium". Medium. 2020-04-30. Retrieved 2020-05-01.
- ↑ "Damilola Anwo-ade's schedule for Social Media Week Lagos 2019". Social Media Week Lagos 2019. 2013-12-17. Retrieved 2020-05-01.
- ↑ "Damilola Anwo-Ade". F6S. Retrieved 2020-05-01.
- ↑ . (2018-11-22). "How more women will access tech solutions to boost business". Anwo-Ade – Daily Trust. Retrieved 2020-05-01.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "US honors 5 Nigerian women". Vanguard News. 2017-06-08. Retrieved 2020-05-01.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]