Jump to content

Dìgbòlugi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Dìgbòlugi
DìgbòlugiAjá tí ó ya dìgbòlugi ní ìpele wọ́nranwọ̀nran (wọ́nranwọ̀nran)
DìgbòlugiAjá tí ó ya dìgbòlugi ní ìpele wọ́nranwọ̀nran (wọ́nranwọ̀nran)
Ajá tí ó ya dìgbòlugi ní ìpele wọ́nranwọ̀nran (wọ́nranwọ̀nran)
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10A82. A82.
DiseasesDB11148
MedlinePlus001334

Dìgbòlugi jẹ́ kòkòrò àkóràn àrùn tí o ń fa ohun líle àrùn ọpọlọ nínu ènìyàn àti àwọn ẹlẹ́jẹ̀ gbígbóná ẹranko míìràn.[1] Lára àwọn amì àkọ́kọ́ rí ni ibà àti ara rínrìn ní àwọn ibi tó hàn síta.[1] Ọ̀kan tàbí méjì àmì tí ó máa ń tẹ̀lé àmì yíi níwọ̀nyí: Ìrìn hánran-hànran, ìdùnnú àìlékoníjànu, ìbẹ̀rù omi, àìlegbé àwọn ẹ̀yà ara kan, ìpòrúúru, àti àìlèrántí ohun.[1] Lẹ́hìn tí àmì jẹyọ, dìgbòlugi sábà máa ń jásí ikú.[1] Àkókò láárin ìgbà kíkó àrùn yíi àti ìgbà tí àmì jẹyọ jẹ́ láàrín oṣù kan sí mẹ́ta. Síbẹ̀síbẹ̀, àkókò yìi léjẹ̀ ókéré ọsẹ̀ kan sí ju ọdún kan.[1] Àkókò dálé ọ̀nàréré tí kòkòrò àkóràn gbọ́dọ̀ rìn láti dé ẹ̀yà ara bí ọpọlọ àti egungun ẹ̀hìn.[2]

Dìgbòlugi ń ran ènìyàn láti ara eranko míìràn. Dìgbòlugi lèràn nígbà tí eranko tí ó ní lára fèkanná ha tàbí bu ẹranko tàbí ènìyàn míìràn jẹ.[1] Itọ́ láti ara ẹranko tí ó ní àkóràn náà léṣòkùnfà dìgbòlugi nígbà tí itọ́ bá kan ibi itọ́ ẹranko tàbí ènìyàn míìràn.[1] Ọ̀pọ̀ dìgbòlugi nínu àwọn ènìyàn jẹ́ òkùnfà ìgéjẹ ajá.[1] Ju 99% ìṣẹ̀lẹ̀ dìgbòlugi ní àwọn orílẹ̀ èdè tí ajá ti ń ní dìgbòlugi, ìbùjẹ ajá ni o ń fà.[3] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà, àdán ni ó sábà maa ń fa dìgbòlugi, ó kérésí ìdá 5% dìgbòlugi lára àwọn ènìyàn ni o ń wá láti ọ̀dọ̀ ajá.[1][3] Àwọn eku kìí sábà ní dìgbòlugi.[3] kòkòrò àifójúrí dìgbòlugi maa ń lọsí ọpọlọ nípa àwọn ọ̀nà yíì ẹ̀yà ara bí ọpọlọ àti egungun ẹ̀hìn. Alè ṣàwarí àrùn yíi lẹ́hìn tí àwọn àmì rẹ̀ bá farahàn.[1]

Ìṣàkóso ẹranko àti ìpèsè àwọn oògùn ti dín ìjàm̀bá dìgbòlugi láti ara ajá kù ní àwọn ọ̀pọ̀ ẹkùn àgbayé.[1] Ìpèsè oògùn fún àwọn ènìyàn ní ibi tí wọ́n ti ń yára ko ṣe pàtàkì. Àwọn tí ò lè yára ko ni àwọn tí o ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àdán tàbí tí o ńlo àkókò púpọ̀ ni àwọn apá ibìkan lágbàyé níbi tí dìgbòlugi ti wọ́pọ̀.[1] Lára àwọn tí o ti ní dìgbòlugi, oògùn dìgbòlugi tàbí nígbà mííràn dìgbòlugi èròjà inú ara to ń gbógun ti kòkòrò dára ní dídẹ̀kun àrùn náà bí ènìyàn náà bá gba ìtọjú ṣáájú dìgbòlugi.[1] Fífọ ìgéjẹ àti ojú ìha léèkanná fún ìṣẹjú mẹ́ẹ̀dogún pẹ̀lú ọṣẹ àti omi, iodine ẹlẹ́fun, tàbí ọṣẹ ìyẹ̀fun lépa kòkòrò àìfojúrí nítorí wọ́n já fáfá ní dídẹ̀kun ìtànkálẹ̀ dìgbòlugi.[1] Àwọn ènìyàn díẹ̀ ni ó là lọ́wọ ìfarakó dìgbòlugi èyí sì wà láti ara ìtọjú púpọ̀, táa mọ̀sí Ètò Milwaukee.[4]

Dìgbòlugi ńfa ikú lágbayé lọ́dọọdún bi 26,000 sí 55,000.[1][5] Ju ìdá 95% ikú wọ̀nyíi ń ṣẹlẹ̀ ni Asia àti Africa.[1] Dìgbòlugi wà ní orílẹ̀ èdè 150 ní àwọn ojú ilẹ̀ ayé yàtọ̀ sí Antarctica.[1] Ju bílíọ́nù 3 àwọn ènìyàn ni o ń gbé ní ẹkùn lágbàyé níbi tí dìgbòlugi ti ń ṣẹlẹ̀.[1] Ní ọ̀pọ̀ Europe àti Australia, ara àdán nìkan ni dìgbòlugi wà.[6] Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè erékùsù ni kòní dìgbòlugi.[7]

References[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.00 1.01 1.02 1.03 1.04 1.05 1.06 1.07 1.08 1.09 1.10 1.11 1.12 1.13 1.14 1.15 1.16 1.17 "Rabies Fact Sheet N°99". World Health Organization. July 2013. Retrieved 28 February 2014. 
  2. Cotran RS, Kumar V, Fausto N (2005). Robbins and Cotran Pathologic Basis of Disease (7th ed.). Elsevier/Saunders. p. 1375. ISBN 0-7216-0187-1. 
  3. 3.0 3.1 3.2 Tintinalli, Judith E. (2010). Emergency Medicine: A Comprehensive Study Guide (Emergency Medicine (Tintinalli)). McGraw-Hill. pp. Chapter 152. ISBN 0-07-148480-9. 
  4. Hemachudha T, Ugolini G, Wacharapluesadee S, Sungkarat W, Shuangshoti S, Laothamatas J (May 2013). "Human rabies: neuropathogenesis, diagnosis, and management.". Lancet neurology 12 (5): 498–513. doi:10.1016/s1474-4422(13)70038-3. PMID 23602163. 
  5. Lozano R, Naghavi M, Foreman K, Lim S, Shibuya K, Aboyans V, Abraham J, Adair T, Aggarwal R, et al. (Dec 15, 2012). "Global and regional mortality from 235 causes of death for 20 age groups in 1990 and 2010: a systematic analysis for the Global Burden of Disease Study 2010.". Lancet 380 (9859): 2095–128. doi:10.1016/S0140-6736(12)61728-0. PMID 23245604. 
  6. "Presence / absence of rabies in 2007". World Health Organization. 2007. Retrieved 1 March 2014. 
  7. "Rabies-Free Countries and Political Units". CDC. Retrieved 1 March 2014.