Jump to content

Dele Alli

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

 

Bamidele Jermaine Alli ( / ˈd ɛ l i ˈ æl i / DEL -ee AL -ee ; [1] ti a bi 11 Oṣu Kẹrin ọdun 1996) jẹ agbabọọlu adi arin mu ara ilu Gẹẹsi ti o n gba boolu ninu idije Premier League pelu iko ẹgbẹ agbabọọlu Everton.


Dele gba boolu fun England U17, U18 ati U19, ṣaaju gbigba boolu pelu egbe agba orilede naa ni ọdun 2015. O kopa ninu UEFA Euro 2016 ati Ife Eye agbaye ti odun 2018, ti o ṣi gba bool wole ni igbehin eyi to je iranlọwọ fun iko egbe agba boolu England lati de ipele si asekagba idije naa.

Dele darapọ mọ egbe agbaboolu ojewewe Milton Keynes Dons leni odun mokanla (11) lẹhin ti o gba boolu pelu egbe agba boolu ojewewe City Colts[1].

O faran ninu idije agba oje fun igba akoko ninu egbe agbaboolu re akoko ni eni omo odun merindinlogun ninu egbe agbaboolu egbe MK Dons ni ọjọ 2 Oṣu kọkanla ọdun 2012, ni'gba ti won gbe wole lati ropo Jay O'Shea ni iseju merin din laadorin ninu idije pelu egbe agbaboolu Cambridge City ninu idije FA Cup ni Milton Road[2]. Boolu akoko ti o gba ninu idije naa ni o fi eyin ese gba[3]. O mi awon wole fun igba akoko pelu egbe agbaboolu naa ni ibi to gba ami ayo kan wole nigba ti won n koju egbe agbaboolu Cambridge ni ọjọ mọkanla lẹhin ifarahan re akoko, idije naa pari pelu ami ayo 6-1[4]. O ṣe takun-takun fun igba akoko ninu idije to pari pelu ami ayo 2–3 nigba ti egbe agbaboolu re lo koju egbe agbaboolu Conventry City ni ile won ni ọjọ kokandinlogbon Oṣu kejila, nibiti o ti gba boolu fun iṣẹju mokanlelaadorin ki o to jade fun Zeli Ismail[5].

  1. FATV Exclusive: Dele Alli Q & A with fans | #ask... 
  2. Osborne (2 November 2012). "Cambridge City 0–0 MK Dons". https://www.bbc.co.uk/sport/0/football/20091781. 
  3. Empty citation (help) 
  4. "MK Dons 6–1 Cambridge City". 13 November 2012. https://www.bbc.co.uk/sport/0/football/20216720. 
  5. "MK Dons 2 – 3 Coventry City". 29 December 2012. https://www.bbc.co.uk/sport/0/football/20823148.