Jump to content

Denise Newman (oṣerebinrin)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Denise Newman
Ọjọ́ìbíCape Town
Orílẹ̀-èdèSouth African
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́1982-present

Denise Newman jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfríkà.

Newman dàgbà ní agbègbè Athlone tí ó wà ní ìlú Cape Town. Òbí rẹ̀ kan jẹ́ olùránṣọ.[1] Ó ṣe àpèjúwe ara rẹ̀ pé òun maá sábà dá wà nígbà èwe òun, tó síì kọ̀ láti rí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ bá ṣeré.[2] Lẹ́hìn tí ó parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ láti Athlone High School ní ọdún 1972, ó lọ sí Amẹ́ríkà fún ètò-ẹ̀kọ́ Post-matric Learnership. Newman padà sí orílẹ̀-èdè rẹ̀ ní ọdún 1974 láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ àwùjọ. Newman gba iṣẹ́ kan ní ilé-ìṣeré Space Theatre níbi tí ó ti n ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi olùtọ́jú ilé-ìṣeré náà, tó síì maá n ṣètò ilẹ̀ gbígbá àti aṣọ fífọ̀ ní ilé-ìṣeré náà. Ní ọdún 1979, wọ́n fun ní ipò alákòóso ìpele, èyí tí ó fun ní ànfààní láti kó àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi òṣèré nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Political Joke, èyí tí Jean Naidoo ṣe olùdarí rẹ̀ tí Peter Snyders náà síì jẹ́ ònkọ̀tàn.[3]

Ní ọdún 1982, Newman kó àkọ́kọ́ ipa sinimá àgbéléwò rẹ̀ nínu eré City Lovers gẹ́gẹ́ bi Yvonne Jacobs, òṣìṣẹ́ ilé-ìtajà aláwọ̀dúdú kan tí ó yó ìfẹ́ okùnrin aláwọ̀funfun kan.[4] Ní ọdún 1985, ó kópa nínu eré aláwàdà tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Two Weeks in Paradise.[5]

Ní ọdún 2009, Newman kó ipa olú-ẹ̀dá-ìtàn nínu ere ́tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Shirley Adams, èyí tí olùdarí rẹ̀ jẹ́ Olivier Hermanus. Ó ṣe ìyá ọmọ ogún ọdún kan tí ó n gbèrò láti ṣekú pa ararẹ̀ lẹ́hìn tí ó rọ lápá àti ẹsẹ̀. Newman gba àmì-ẹ̀yẹ amúgbálẹ́gbẹ̀é òṣèré tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Carthage Film Festival fún ipa rẹ̀ nínu eré náà.[6]

Newman kópa gẹ́gẹ́ bi ìyá sí Tiny nínu eré The Endless River ní ọdún 2015, eré tí Hermanus darí.[7] Ó darapọ̀ mọ́ àwọn olùkópa eré tẹlifíṣọ̀nù Suidooster ní ọdún 2015.[8] Ó tún kópa gẹ́gẹ́ bi Dulcie September nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Cold Case: Revisiting Dulcie September ní ọdún 2015. Newman sọ di mímọ̀ wípé òun fẹ́ràn ipa náà ju ti ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Daleen Meintjies nínu eré 7de Laan lọ.[3] Ní ọdún 2019, ó ní ipa àlejò nínu abala ẹlẹ́kejì ti eré Die Byl.[9]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • 1982: City Lovers
  • 1985: Two Weeks in Paradise
  • 1995: The Syndicate
  • 1998: The Sexy Girls
  • 2004: Forgiveness
  • 2005: Gabriël
  • 2009: Shirley Adams
  • 2012: Material
  • 2015: The Endless River
  • 2015–present: Suidooster (TV series)
  • 2019: Die Byl (TV series)

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Abarder, Gasant (29 May 2015). "Denise delves into Dulcie’s story". IOL. https://www.iol.co.za/capeargus/denise-delves-into-dulcies-story-1865069. Retrieved 9 November 2020. 
  2. "A CONVERSATION WITH DENISE NEWMAN". Sarafina Magazine. 25 April 2017. https://sarafinamagazine.com/2017/04/25/a-conversation-with-denise-newman/. Retrieved 9 November 2020. 
  3. 3.0 3.1 "Denise delves into Dulcie’s story". IOL. 29 May 2015. https://www.iol.co.za/capeargus/denise-delves-into-dulcies-story-1865069. Retrieved 9 November 2020. 
  4. "'CITY LOVERS' AND 'COMING OF AGE'". https://www.nytimes.com/1982/09/30/movies/city-lovers-and-coming-of-age.html. Retrieved 9 November 2020. 
  5. "Two Weeks in Paradise". BFI. Retrieved 9 November 2020. 
  6. Cheshire, Godfrey (17 November 2010). "THE 2010 CARTHAGE FILM FESTIVAL". Filmmaker Magazine. https://filmmakermagazine.com/16112-the-2010-carthage-film-festival/#.X6lJ5bvYrrc. Retrieved 9 November 2020. 
  7. "'The Endless River': Venice Review". The Hollywood Reporter. 9 June 2015. https://www.hollywoodreporter.com/review/endless-river-venice-review-820801. Retrieved 9 November 2020. 
  8. "Leer ken Suidooster se Denise Newman". Netwerk24. 16 November 2015. https://www.netwerk24.com/Sarie/Bekendes/Ons-Praat-Met/leer-ken-suidooster-se-denise-newman-20170914. Retrieved 9 November 2020. 
  9. "Three reasons to binge gritty Cape Town cop drama, 'Die Byl'". News24. 18 July 2019. https://www.news24.com/channel/tv/news/three-reasons-to-binge-gritty-cape-town-cop-drama-die-byl-20190716. Retrieved 9 November 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]