Derssa
Derssa (Lárúbáwá: درسة) jẹ́ oúnjẹ tó gbajúmọ̀ ní Algeria,[1] Èyí tí a ṣe pẹ̀lú garlic, cumin, red chili pepper flakes, àti olive oil.[2] Wọn sábàá máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú ẹran lílọ̀ tàbí sísun, wọ́n sì máa ń lò ó gẹ́gẹ́ bí èlò fún ẹran tàbí ẹ̀fọ́ síwájú ṣíṣè. Ó lè ṣe iṣẹ́ orísìírísìí wọ́n sì sábàá máa ń lò ó láti fi adùn kún orísìírísìí oúnjẹ, wọ́n tún lè lò ó gẹ́gẹ́ bí ìfibọ̀ fún búrẹ́dì tàbí ẹ̀fọ́, tàbí gẹ́gẹ́ bí ìfibọ̀ sáńwiìsì tàbí ìwépọ̀.
Ohun èlò kan náà fún derssa lè yàtọ̀ láti agbègbè sí agbègbè tàbí kódà láti ilé sí ilé, pẹ̀lú àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀ nípa àfikún èròjà bí coriander, lemon juice, tàbí tomato paste.[3] Síbẹ̀síbẹ̀, ohun èlò tó ṣe pàtàkì jù lọ ti garlic, cumin, chili flakes, àti olive oil sábàá máa ń wà nínú orísìírísìí ẹ̀yà èlò oúnjẹ náà.
Derssa jẹ́ mímọ̀ fún líle, adùn títa, àti pé ó jẹ́ oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ní Algerian. Nígbà mìíràn, wọ́n máa kọ ọ́ bi "dersa" tàbí "dersah", ó sì tún jẹ́ mímọ̀ sí "harissa" ní àwọn agbègbè kan. Síbẹ̀, kò gbọ́dọ̀ di gbígbé fún ọbẹ̀ Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n ń pè ní harissa, èyí tí ó di ṣíṣe pẹ̀lú orísìírísìí èròjà gẹ́gẹ́ bí ata ṣíṣe, gálìkì, àti amọ́bẹ̀dùn.[4]
Nínú oúnjẹ Algerian, derssa máa ń di ṣíṣe nípa fífọ́ tàbí lílọ gálìkì àti cumin pẹ̀lú ọmọ odó àti ìyá odó tàbí tàbí Ẹ̀rọ ìṣe oúnjẹ, lẹ́yìn náà yóò di pípò mọ́ ata pupa àti òróró ólífì títí tí yóò fi kúnná. Derssa náà yóò wá di fífi sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí tàbí mọ́jú láti lè jẹ́ kí adùn rẹ̀ parapọ̀ síwájú kí ó tó di jíjẹ. Ní àfikún sí àwọn èròjà ti garlic, cumin, chili flakes, àti olive oil, àwọn ìyàtọ̀ derssa díẹ̀ lè jẹ́ àwọn ohun amọ́bẹ̀dùn yòókù tàbí àwọn èròjà bí paprika, coriander, lemon juice,[5] tàbí tomato paste. Ohun èlò tó ṣe rẹ́gí fún derssa lè yàtọ̀ ó dá lórí ìfẹ́ràn oníkálukú tàbí ìṣe agbègbè.[6][7][8]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ ""La Dersa : une sauce algérienne simple et savoureuse"". Marmiton.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Fatima-Zohra, Bouayed (1970-01-01) (in fr). La cuisine algérienne. Temps Actuels. pp. 11. https://www.amazon.co.uk/cuisine-alg%C3%A9rienne-Bouayed-Fatima-Zohra/dp/B0099RJDZ8.
- ↑ Warda. ""Dersa Algerian Spicy Sauce"". North African Cooking.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Courge à la dersa". archive.wikiwix.com. Retrieved 2023-02-24.
- ↑ Hansen, Victoria. ""Dersa (Harissa) Algerian Hot Pepper Sauce"". Allrecipes.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Dersa". CuisineAZ.
- ↑ "Dersa Algerian Garlic Sauce" by Christine Benlafquih on The Spruce Eats
- ↑ Garet, Alicia (2021-06-08). "Dersa: sauce à l'ail algérienne". Sos Recette (in Èdè Faransé). Retrieved 2023-02-24.