Jump to content

Donia Massoud

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Donia Massoud
Ọjọ́ìbí2 Oṣù Kàrún 1979 (1979-05-02) (ọmọ ọdún 45)
Alexandria, Egypt
Orílẹ̀-èdèEgyptian
Iṣẹ́Actress, singer

Donia Massoud (tí wọ́n bí ní 2 Oṣù Kaàrún, Ọdún 1979) jẹ́ òṣèrébìnrin àti akọrin ọmọ orílẹ̀-èdè Ìjíptì.

Massoud lẹni tí wọ́n bí tó sì dàgbà ní ìlú Alexandria. Nígbà tí ó pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, ó kó lọ sí ìlúKáírò. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ akorin àti òṣèré rẹ̀ ní ìlú Káírò.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 2000, Massoud lo ọdún mẹ́ta láti fi gba ìtàn àti àwọn orin àṣà káàkiri ilẹ̀ Ìjíptì. Ó gba àwọn orin àṣà sílẹ̀ níbi àwọn ayẹyẹ àjọ̀dún àti ìgbéyàwó. Massoud ṣe àgbéjáde àkójọpọ̀ àwọn orin rẹ̀ kan ní ọdún 2009 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Mahatet Masr. Èyí tí ó gbajúmọ̀ jùlọ nínu àwọn orin rẹ̀ ni orin tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Betnadeeny Tany Leeh", èyì tí ó fi n béèrè lọ́wọ ̀ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àtijọ́ ìdí tí ó ṣe ń pẹ ago rẹ̀ lẹ́hìn tí òun ti ní olólùfẹ́ míràn. Ó kọ orin náà káàkiri àgbáyé tó sì ṣe eré orin náà ní ilẹ̀ Africa, Europe, àti Asia.[1]

Yàtọ̀ sí iṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀, Massoud darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré orí-ìtàgé kan tí wọ́n pè ní Al-Warsha. Ó rí iṣẹ́ orin kíkọ láti farapẹ́ eré ìtàgé ṣíṣe. Massoud ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá àgbéléwò àti eré tẹlifíṣọ̀nù lórílẹ̀ èdè Ìjíptì àti Swídìn lédè Lárúbáwá àti Gẹ̀ẹ́sì.[2] Àwọn fíìmù tí ó ti kópa nínu rẹ̀ pẹ̀lú Galteny Mogremen (2006), In the Heliopolis Flat (2007) àti Genenet al asmak (2008).[3]

Ní ọdún 2015, Massoud fa awuyewuye fún ṣíṣe ọ̀ṣọ́ ara kan sí ẹ̀yìn rẹ̀.[4]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Àwọn fíìmù tí ó ti kópa
  • 2002 : Khalli Eldemagh Sahi
  • 2006 : Galteny Mogremen
  • 2007 : In the Heliopolis Flat
  • 2008 : Genenet al asmak
  • 2011 : Blue Dive
Àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù
  • 2005 : Alb Habiba
  • 2007 : Hanan w Haneen
  • 2008 : Eleiada
  • 2008 : Sharif we Nos
  • 2009 : Majnoun Laila
  • 2010 : Ahl Cairo
  • 2011 : Matt Nam Sabboba Massreya

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]