Doyin Abiola
Dr. Doyin Abiola, Doyinsola Hamidat Abiola (Nee Aboaba) ti jẹ́ aṣàkóso olùdarí àti aṣàtẹ̀jáde ìwé ìròyìn National Concord Newspaper[1] Òun ni obìnrin Nàìjíríà àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ olóòtú ìwé ìròyìn Daily Times of Nigeria| Nigerian daily.[2][3]
Ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Dr. Doyin Abiola kẹ́kọ̀ọ́ ní Yunifásitì ti Ìbàdàn , Nàìjíríà níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde nípa èdè Gẹ̀ẹ́sì àti eré-oníṣe ní 1969. Lẹ́yìn tí ó kẹ́kọ̀ọ́ jáde, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú ìwé ìròyìn Daily Sketch ní 1969. Ní àsìkò yìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ abala nínú ìwé ìròyìn náà tí wọ́n pè ní Tiro tí ó ń rí sí oríṣìíríṣìí ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ takọtabo. Ní 1970, ó kúrò ní ìwé ìròyìn Daily Sketch, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí United States láti kẹ́kọ̀ọ́ gba master’s degree nínú Journalism. Nígbà tí ó dé, wọ́n gbà á gẹ́gẹ́ bí i akọ̀wé abala ní Daily Times, ó sì lọ òkè láti jẹ́ ẹgbẹ́ olóòtú abala náà. Ó padà lọ sí New York University, ó sì gba PhD nínú communications and political science ní 1979. [4] Lẹ́yìn ètò PHD rẹ, ó padà sí Daily Times, wọ́n sì gbé e lọ sí àjọ àwọn olóòtú níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn olóòtú tí wọ́n ti ní ìrírí bí i Stanley Macebuh, Dele Giwa àti Amma Ogan. Ó jẹ́, síbẹ̀síbẹ̀, ìdúró kúkurú torí pé ìwé ìròyìn tuntun National Concord Newspaper tí wọ́n ṣẹ̀ dá sílẹ̀ pè é láti jẹ́ olóòtú ojoojúmọ́ rẹ àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà ni ó dé ipò olóòtú National Concord newspaper. Ó gba ìgbélárugẹ láti jẹ́ aṣàkóso olùdarí/olórí olóòtú ní 1986. Ó di obìnrin Nàìjíríà àkọ́kọ́ láti di olórí olóòtú ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ ní Nàìjíríà.[5][6] Dr. Doyin Abiola tún jẹ́ opó aṣàtẹ̀jáde àkọ́kọ́ àti olùdáni National Concord Newspaper Olóyè Moshood Abiola tí ó fẹ́ ní 1981.[7] Iṣẹ́ Doyin Abiola ní National Concord Newspaper lọ fún ọgbọ̀n ọdún. Ó tún ṣiṣẹ́ ní oríṣìíríṣìí ipò ní ilé iṣẹ́ atẹ̀ròyìn ní Nàìjíríà. Òun ni alága Awards Nominating panel ní Nigerian Media Merit Award àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe ní Nàìjíríà nígbà náà. Ó jẹ́ ara ìgbìmọ̀ onímọ̀ràn, Faculty of Social and Management Sciences, Ogun State University.
Àmì-ẹ̀yẹ àti ìdánimọ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó gbá àmì-ẹ̀yẹ Diamond Awards for Media Excellence (DAME) fún ìfinjì gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ sí ìdàgbàsókè ààlà ìmọ̀ àti ìmúlágbára ilé-iṣẹ́ ìròyìn gẹ́gẹ́ bí òpómúléró ìjọba alágbádá. Àwọn onídùúró DAME fi ọwọ́ sí yíyàn rẹ̀ pẹ̀lú ìṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí i olùgbà àmì-ẹ̀yẹ Lifetime Achievement Award níbi ayẹyẹ kẹrìnlélógún DAME. Òun ni obìnrin kejì tí yóò gba àmì-ẹ̀yẹ DAME Lifetime Achievement Award lẹ́yìn Mrs.(Omobola Onajide). [8] Wọ́n fún un ní Eisenhower Fellowship ní 1986.[9]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Buhari: God shamed enemies - Femi Adesina". Daily Post. 2017-03-25. Retrieved 2017-03-27.
- ↑ "Citation of Dr. Doyin Abiola, Lifetime Achievement Awardee at the 24th Dame". DAME Awards. Archived from the original on 2021-08-20. Retrieved 2017-03-27.
- ↑ "Buhari salutes Doyin Abiola at 75". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-02-01. Retrieved 2021-11-22.
- ↑ "Dr. Doyinsola Abiola Biography – MassMediaNG". Archived from the original on 2021-08-20. Retrieved 2022-07-23.
- ↑ "Buhari congratulates Doyin Abiola at 73". 31 January 2018.
- ↑ "Abiola's wife continues the struggle alone".
- ↑ "Moshood Abiola".
- ↑ "Dr. Doyinsola Abiola Biography – MassMediaNG". Archived from the original on 2021-08-20. Retrieved 2022-07-23.
- ↑ "Fellows Directory".