Driving Miss Daisy (fíìmù 2014)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Driving Miss Daisy
Fáìlì:Driving Miss Daisy 2014 poster.jpg
Film poster
AdaríDavid Esbjornson
Olùgbékalẹ̀Richard Moore
Òǹkọ̀wéAlfred Uhry
Àwọn òṣèréAngela Lansbury
James Earl Jones
Boyd Gaines
OlóòtúJill Bilcock
Ilé-iṣẹ́ fíìmùBroadway Near You
Umbrella Entertainment
OlùpínOmniverse Vision
Screenvision
Fathom Events
Déètì àgbéjáde
  • Oṣù Kàrún 25, 2014 (2014-05-25) (UK)
  • Oṣù Kẹfà 4, 2014 (2014-06-04) (US)
Àkókò90 minutes
Orílẹ̀-èdèUnited States
Australia
ÈdèEnglish

Driving Miss Daisy jẹ́ fíìmù tí wọ́n ṣe fún eré orí-ìtàgé ti ilẹ̀ Austraila ti ọdún 2013. Lára àwọn òṣèrẹ́ tó kópa ni Angela Lansbury, James Earl Jones àti Boyd Gaines. Wọ́n gbe jáde gẹ́gẹ́ bí i fíìmù ní ọdún 2014 láti ọwọ́ Broadway Near You (United States) pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Umbrella Entertainment (Australia).

Ìtàn ní ṣókí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Miss Daisy Werthan (Angela Lansbury) jẹ́ opó, ó sì jẹ́ obìnrin Jew ọmọdún méjìléláàádọ́rin tó ń gbé ní Atlanta, tí ọmọ rẹ̀, ìyẹn Boolie (Boyd Gaines) rí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti darúgbó jù láti wa ọkọ̀ fúnra rẹ̀. Èyí ló mu gba Hoke Coleburn, tó jẹ́ ọmọ Africa tó tan mọ́ ilẹ̀ America láti máa ṣịṣẹ́ awakọ̀. Ìbáṣepọ̀ yìí sì já sí adùn ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.

Àwọn akópa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìṣàgbéjáde àti ìpolongo lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣụ̀ karùn-ún ọdún 2014, wọ́n ṣe ìpolongo Driving Miss Daisy láti BFI Southbank ní London sí àwọn sínimá tó lọ bí i ọ̀ọ́dúnrún káàkiri ilẹ̀ Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan, lẹ́yìn náà ni ìbèèrè àti ìáhùn wáyé pẹ̀lú Angela Lansbury, èyí tí Omniverse Vision àti BFI.[1]

Ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹfà ọdún 2014, wọ́n ṣàgbéjáde fíìmù náà, wọ́n sì pín in fún sinimá tó lọ bí i ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta kààkiri ilẹ̀ Orílẹ̀ èdè America àti Canada, láti ọwọ́ Screenvision àti Broadway Near You.[2]

Ní oṣù kẹjọ ọdún 2014, wọ́n ṣàfihàn rẹ̀ ní Village CinemasMelbourne, Austrálíà, wọ́n sì ṣàfihàn ìbéèrè àti ìdáhùn ti Angela Lansbury.

Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Karùn-ún ọdún 2015, wọ́n ṣàgbéjáde Driving Miss Daisy káàkiri àwọn sinimá ní U.S. láti ọwọ́ Fathom Events àti Broadway Near You, wọ́n sì polongo rẹ̀ ní PBS Great Performances, ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù keje ọdún 2015, ní 9 pm.[3][4]

Àgbéjáde lórí DVD[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹjọ ọdún 2015, wọ́n ṣàgbéjáde Driving Miss Daisy ní orí DVD ní Region 1 láti ọwọ́ PBS Distribution, ó sì wà fún títà láti orí ẹ̀rọ-ayélujára wọn, ní ShopPBS.org.[5] Ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 2015, wọ́n gbé jáde fún títà lórí Amazon.com.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]