Jump to content

Dupsy Abiola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Modupeola Abiola
Ọjọ́ìbíÀdàkọ:March 1982
àríwá London, United Kingdom
Orílẹ̀-èdèBritish
Orúkọ míràn"Dupsy" Abiola
Iṣẹ́oníṣòwò obìnrin
Gbajúmọ̀ fúnIntern Avenue, Dragons' Den
Parents

Modupeola "Dupsy" Abiola (tí a bí ní oṣù kẹta ọdún 1982) jẹ́ agbẹjọ́rò àti oníṣòwò obìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdarí International Airlines Group (IAG).[1] Òun tún ni ọ̀lùdásílẹ̀ àti adarí Intern Avenue.[2]

Wọ́n bí Dupsy Abiola ní London, orílẹ̀-èdè England. Òun ni ọmọ Olóyè M.K.O. Abiola[3] àti Dele Abiola, òkan lára àwọn ìyàwó olóyè. Bàbá rẹ̀ jẹ́ gbajúmọ̀ oníṣòwò àti onìfifúnni. Ìyá Dupsy tọ dàgbà pẹ̀lú àwọn ọmọ márùn-ún míràn ní àríwá London.

Baba Dupsy, ẹni tí ó jẹ́ Aare Ona Kakanfo àwọn ènìyàn Yoruba kẹrìnlá di ọkàn lára àwọn tó bẹ̀rẹ̀ si ń jà fún ètọ́ àwọn ará ìlú àti fún ìjọba tiwa tiwa, ó díje fún ipò ààrẹ Nàìjíríà ó sì jáwé olúborí nínú ìbò náà nínú oṣù kẹfà ọdún 1933. Lẹ́yìn ǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ìjọba kò láti fi ìjọba lé M.K.O lọ́wọ́. Wọ́n padà ti Olóyè Abiola mó ilé, wọn kò sì jẹ́ kí ó fojú kan ìdílé rẹ̀. Àtìmọ́lé rẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú, àwọn bi akọ̀wé àjọ U.N., Kofi Annan - gbìyànjú láti wá ọ̀nà àti tú olóyè sílẹ̀. M.K.O kú ní ọjọ́ tí wọ́n gbèrò láti tu sílẹ̀, ní ọjọ́ keje oṣù keje ọdún 1998 nígbà tí Dupsy jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Thelwall, Mike (2011-07-07). "A comparison of link and URL citation counting". ASLIB Proceedings 63 (4): 419–425. doi:10.1108/00012531111148985. ISSN 0001-253X. http://dx.doi.org/10.1108/00012531111148985. 
  2. Beaty, Zoe (9 October 2012). "Grazia". Grazia Daily. Archived from the original on 2 November 2012. https://web.archive.org/web/20121102051626/http://www.graziadaily.co.uk/conversation/archive/2012/10/09/dragons-den-star-dupsy--i-gave-up-my-job-as-a-lawyer-to-follow-my-dream-.htm. Retrieved 22 January 2013. 
  3. Lynch, Russell (2016-09-12). "Entrepreneurs: Intern Avenue is helping graduates with careers ladder". Evening Standard (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-15.