Jump to content

Ebbe Bassey

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ebbe Bassey
Ọjọ́ìbíNew York
Iṣẹ́Osere
Ìgbà iṣẹ́1997 di lowolowo
Olólùfẹ́Mark Manczuk

Ebbe Bassey jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ati Amẹ́ríkà tí a yàn fún àmì-ẹ̀yẹ Africa Movie Academy Award kan fún tí òṣèré tí ó dára jùlọ ní ipa àtìlẹyìn nípasẹ̀ ipa tí ó kó gẹ́gẹ́ bi "Maa Dede" nínu Ties That Bind ní ọdún 2011.

Bassey ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù ilẹ̀ Nàìjíríà ati ti Amẹ́ríkà, lára wọn ni Doctor Bello, Mother of George, NYPD Blue, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ti rí yíyàn fún àmì-ẹ̀yẹ òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tí ó dára jùlọ látàrí ipa rẹ̀ nínu eré Ties That Bind.[1] Ní ọdún 2012, ó kéde rẹ̀ wípé òun fẹ́ gbé eré ṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Saving Father, léte àti la àwọn ènìyàn lọ́yẹ̀ nípa níní àti gbígbé ayé pẹ́lú kòkòrò àrùn AIDS.[2] Níbi ayẹyẹ Nigeria Entertainment Awards ti ọdún 2013, wọ́n tún yan Bassey gẹ́gẹ́ bi òṣèré tó n ṣe àtìlẹyìn tó dára jùlọ nínu fiimu.[3] Ní ọdún 2012 bákan náà, Bassey kópa nínu fiimu Turning Point. fiimu náà ṣì gba àwọn àmì-ẹ̀yẹ níbi ayẹyẹ Nollywood and African Film Critics Awards, èyí tí ó wáyé ní Amẹ́ríkà.[4] Ní ọdún 2016, ó kó ipa "Imani" nínu fiimu Tomorrow Ever After, ó sì ní àwọn èsì àtúnyẹ̀wò rere fún ipa rẹ̀ nínu fiimu náà.[5][6] Bassey pẹ̀lu Richard Mofẹ́-Damijo ni wọ́n jọ ṣètò ayẹyẹ Nigeria Entertainment Awards ti ọdún 2016 ní Ilé-iṣẹ́ tó wà fún eré ṣíṣe, Ilé-iṣẹ́ BMCC Tribeca Performing Arts Center ní ìlu New York.[7]

A bí Bassey ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ṣùgbọ́n ó lo àwọn ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ ní ìlu Calabar ṣááju kí ó tó padà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti máa gbé níbẹ̀.[8] Ó ti ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lu Mark Manczuk.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Sam-Duru, Prisca (May 25, 2012). "Women need spiritual core to be empowered – Ebbe Bassey". Vanguard. Retrieved 2017-11-11. 
  2. admin (March 20, 2012). "AFRICAN CINEMA: ACTRESS EBBE BASSEY MANCZUK NEEDS YOUR HELP TO COMPLETE HIV/AIDS AND SENIOR CITIZENS FILM PROJECT". ladybrillemag.com. Archived from the original on 2017-12-01. Retrieved 2017-11-30. 
  3. Michael, Abimboye (May 31, 2013). "Nigerian Entertainment Award announces 2013 nominees". Premium Times. Retrieved 2017-11-12. 
  4. Izuzu (May 24, 2016). "Governor Ayade launches Callywood, appoints filmmaker to run it". Pulse. Archived from the original on 2017-10-23. Retrieved 2017-11-30. 
  5. "Movie Review: Tomorrow Ever After". theyoungfolks.com. May 26, 2017. Retrieved 2017-11-12. 
  6. Linden, Sheri. "Tomorrow Ever After’: Film Review". Hollywood Reporter. Retrieved 2017-11-12. 
  7. Izuzu (August 6, 2016). "Joseph Benjamin, Faithia Balogun, Sambasa Nzeribe among winners". Pulse. Archived from the original on 2017-12-01. Retrieved 2017-11-30. 
  8. "American Actress Ebbe Bassey Making A Comeback On African Screens". Modern Ghana. June 15, 2012. Retrieved 2017-11-11. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]