Ebun Oni
Professor Ebun Oni (tí a bí ní ọjọ́ 21 oṣù karùn-ún, ọdún 1935 -tí ó sì di olóògbé ní ọjọ́ 2 oṣù kejìlá, ọdún 2021)[1] ni a mọ̀ sí Ebun Adegbohungbe nígbà ayé rẹ̀, tí ó wá padà di Ebun Adefunmilyo Oni (orúkọ ọkọ rẹ̀). Ó jé onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ń fi ohun àfojúrí fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa ayé , ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni, ó jẹ́ olùkọ́ ní yunifásitì àti òǹkọ̀wé. Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Nàìjíríà tó kọ́kọ́ di onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àkọ́kọ́, o sì di ìlú-mọ̀-ọ́n-ká látàri ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àtẹ̀jáde rẹ̀. Olùkọ́ ni Yunifásítì ìlú Ìbàdàn ni.
Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Adegbohungbe jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ti ilé-ìwé Methodist Girls High School, Yaba, Lagos[2] kí ó tó lọ kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ Physics ní University College of Ghana ní ọdún 1961. Iṣẹ́ àkọ́kọ́ tó yàn láàyò ni iṣẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ̀, kọ́dà ní ọdún 1967 ó sọ pé òun ni lọ́kàn láti jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tó máa kọ́ nípa ìmọ̀-ẹ̀rọ, àmọ́ ìjọba kọ̀ jálẹ̀ láti fún òun ní àǹfààní ìwé ọ̀fẹ́ torí ó jẹ́ obìnrin, nítorí náà wọ́n gbà á níyànjú láti kọ ẹ̀kọ́ nípa physics.[3]
Adegbohungbe gba ìwé-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ti ìjọba fún ìtẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rè, nínú geophysics ní Imperial College, London. Ó gboyè MSc ní ọdún 1963, ọdún kan náà ni ó dara pọ̀ mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ Physics ní University of Ife, Nàìjíríà.[4] [5]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Ade-Hall, Ademuyiwa. "Ebun Adefunmilayo Oni's life story, (1935 - 2021) - ForeverMissed.com". www.forevermissed.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-03-18.
- ↑ Augustine Togonu-Bickersteth 'Coincidences: Between German Physicists and Methodist Girls, Yaba, Lagos.' Archived 2023-02-11 at the Wayback Machine. Nigeria's Global Voice: News Express, 8 May 2013
- ↑ Proceedings of the Second International Conference of Women Engineers and Scientists (Women’s Engineering Society, 1967) Volume 3 ‘The Woman Engineer’ (Discussion) p.9
- ↑ Ebun Adegbohungbe, ‘Application to Some Economic problems in Nigeria’, Proceedings of the Second International Conference of Women Engineers and Scientists’ (Women’s Engineering Society, 1967) volume 2 ‘Food Enough For Everyone’.[1]
- ↑ Adegbohungbe, Christiana Ebun (1967). "Two-component proton precession magnetometer for use in the equatorial zone". Journal of Geophysical Research 72 (6): 1797–1798. doi:10.1029/JZ072i006p01797. https://agupubs.onlinelibrary.wiley.com/doi/abs/10.1029/JZ072i006p01797.