Ebun Oyagbola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ebun Oyagbola
Ọjọ́ìbíAdenike Ebunoluwa Akinola
Oṣù Kàrún 5, 1931 (1931-05-05) (ọmọ ọdún 92)
Igan Alade, Yewa North, Ogun State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́1958 – present

Adenike Ebunoluwa Oyagbola (bíi ni ọjọ́ karùn-ún, oṣù karùn-ún ọdún 1931) jẹ́ olóṣèlú tí ó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí mínísítà bìnrin àkọ́kọ́ ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ó sì gboyè náà ní ọdún 1979.[1] Oyagbọla jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Igan Aládé ní ìlú Yewa North ní ìpínlẹ̀ Ogun.[2] Ó si ṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ní àwọn ilé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ìlú Yewa àti Mushin. Ní ọdún 1960, ó lọ sí òkè òkun láti ní ìmọ̀ nínú ìsirò owó. Oyagbola darapọ̀ mọ́ Federal Civil Service ní ọdún 1963 lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè United Kingdom.[3] Ní ọdún 1979, ó di mínísítà bìnrin àkọ́kọ́ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lábẹ́ àkóso Shehu Shagari. [4]Ó dì àmbásẹ́dọ̀ tí Nàìjíríà fún àwọn orílẹ̀ orílẹ̀ èdè United Mexican States of Panama, Costa Rica atii Guatemala.[5][6]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]