Media Trust

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

 

Daily Trust logo.jpg
TypeDaily newspaper
FounderKabiru Yusuf
PublisherMedia Trust
EditorHamza Idris
Editor-in-chiefNaziru Mikailu
Managing editorsStella O Iyaji
Founded2001
LanguageEnglish-Hausa language's
HeadquartersAbuja, Nigeria
Sister newspapersAminiya
Official websitedailytrust.com

Media Trust jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn aládàáni tó wà ní Abuja, tó máa ń tẹ ìwé-ìròyìn ''Daily Trust'', Weekly Trust, Sunday Trust ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, àti ìwé-ìròyìn Aminiya ní èdè Hausa. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n máa ń ṣàgbéjáde ìròyì ilẹ̀ Africa tí wọ́n ń pè ní Kilimanjaro. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ilé-iṣẹ́ ìgbéròyìn jáde, ní ilẹ̀ Nàìjíríà.[1]

Ìtàn nípa rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ Weekly Trust ní oṣù kẹta ọdú 1998 àti Daily Trust ní oṣù kìíní, ọdún2001. Àwọn ìwé-ìròyìn méjèèjì yìí jẹ́ èyí tó tànkálẹ̀ jù lọ ní apá Gúúsù ilẹ̀ Nàìjíríà.[2] Ẹgbẹ́ ìwé-ìròyìn yìí lékè láárin àwọn ìwé-ìròyìn méje tó ń ṣáájú ní ilẹ̀ Nàìjíríà, nínú ètò ìpolówó ọjà.[3]

Àkóónú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìwé-ìròyìn yìí ní àtẹ̀jáde orí ayélujára, àwọn àkóónú inú ìwé-ìròyìn yìí sì jẹ́ títẹ̀ jáde láti ọwọ́ àwọn AllAfrica àti Gamji.[4] Ilé-iṣẹ́ náà ṣàfihàn àmì-ẹ̀yẹ ti "Daily Trust African of the Year", láti fi gbóríyìn fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Africa tó ti kó ipa ribiribi nínú ọ̀rọ̀ ilẹ̀ Africa, tí wọ́n sì ti ní ipa gidi lórí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn mìíràn.[5]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]