Eden Hazard

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Eden Michael Hazard (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ keje oṣù kìíní ọdún 1991) jẹ́ agbá-bọ́ọ̀lù àfẹsẹgbá-jẹun ọmọ orílẹ̀ èdè Belgium. Ẹgbẹ́ agbá-bọ́ọ̀lù Real Madrid ní orílè-èdè Spain ló ti ń gbá bọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ lọ́wọ́́lọ́wọ́ báyìí.[1] [2]

Eden Hazard ní ọdún 2019

Ìgbà èwe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú La Louvière ni wọ́n bí Eden Hazard sí ṣùgbọ́n wọ́n tó o dàgbà ni Braine-le-Comte. Agbàbọ́ọ̀lù-jẹun ni bàbá rẹ̀ Thierry àti ìyá rẹ̀, Carine. Ìdílé Eden Hazard ni wọ̀n bá má pè ní ìdílé Agbàbọ́ọ̀lù-jẹun nítorí pé yàtò sí àwọn òbí wọ́n méjèèjì tó jẹ́ Agbàbọ́ọ̀lù-jẹun, gbogbo àwọn àbúrò mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló tún jẹ́ Agbàbọ́ọ̀lù-jẹun pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbá-bọ́ọ̀lù káàkiri àgbáyé. Owó bọ́ọ̀lú gbígbá ni àwọn òbí wọn fi tọ́ wọn dàgbà.[3]

Ìgbé ayé Eden Hazard gẹ́gẹ́ bí Agbàbọ́ọ̀lù-jẹun[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ikọ̀ agbá-bọ́ọ̀lù Chelsea lórílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ló ti kúrò darapọ̀ mọ́ Real Madrid lọ́dún 2019. Ikọ̀ Chelsea yìí ló ti di ìlúmọ̀ọ́kà agbá-bọ́ọ̀lù káàkiri gbogbo àgbáyé. Hazard jẹ́ elésẹ̀ ayò àti elégèé àrà agbá-bọ́ọ̀lù. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmín ayò ló ti gbá wọlé nígbà tó wà ní Chelsea. Ẹgbẹ́ agbá-bọ́ọ̀lù Lile lórílẹ̀ èdè Faransé ló ti kọ́kọ́ tí ń gbá bọ́ọ̀lù kí ó tó darapọ̀ mọ́ ikọ̀ Chelsea lọ́dún 2012. Ó dára pọ̀ mọ́ Líle lọ́dún 2005.[4] [5] [6]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Eden Hazard". Barry Hugman's Footballers. 1991-01-07. Retrieved 2019-11-27. 
  2. "Hazard". Real Madrid C.F. - Web Oficial. Retrieved 2019-11-27. 
  3. "footlille.com". footlille.com. 2015-09-24. Archived from the original on 2015-09-24. Retrieved 2019-11-27.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Eden Hazard - Player profile 19/20". Transfermarkt (in Èdè Jámánì). Retrieved 2019-11-27. 
  5. "Eden Hazard Profile, News & Stats". Premier League. 2019-06-08. Retrieved 2019-11-27. 
  6. "Who is Eden Hazard? Everything You Need to Know". Eden Hazard Biography. 2019-03-19. Retrieved 2019-11-27.