Edo black soup

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Edo black soup ni wọ́n tún mọ̀ sí omoebe, ó jẹ́ ọbẹ̀ Nàìjíríà tí wọ́n fi èròjà ewé tó ṣe pàtàkì sè àwọn ni efinrin, ewé úsísá, àti ewúro. Àwọn èròjà mìíràn tí ó tún nílò ni ẹran, àlùbọ̀sà, edé, ata àti epo pupa.[1]

Orísun[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọbẹ̀ yìí gbajúgbajà ní Ìpínlẹ̀ Ẹdó, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnikẹ́ni tó bá wù ni ó le jẹ ẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[2]

Lápapọ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n máa ń bọ ẹran náà pẹ̀lú àwọn magí àti àlùbọ̀sà, nígbà tí ó bá ń bọ̀, ewé úsísá àti efinrin ma di lílọ̀ papọ̀, pẹ̀lú lílọ ewúro lọ́tọ̀.[3]

Ní àfikún sí epo pupa àti omi ẹran inú ìkòkò, ata lílọ, edé, àlùbọ̀sà àti ẹ̀fọ́ úsísá-efinrin ma di sísè fún ìṣẹ́jú 2-3. Àti pé, ewúro lílọ náà ma di àfikún sí ọbẹ̀ kíki náà.[4]

Àwọn Oúnjẹ Àfikún sí í[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n le fi fùfú, ẹ̀bà, ìyán àti sẹ̀mófità jẹ ọbẹ̀ dúdú náà.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "How To Prepare Delicious Edo State Black Soup". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-22. Retrieved 2022-06-26. 
  2. "That Edo Black Soup". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-03-27. Retrieved 2022-06-26. 
  3. omotolani (2018-03-20). "How to cook black soup". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-06-26. 
  4. "How To Prepare Delicious Edo State Black Soup". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-22. Retrieved 2022-06-26. 
  5. "Edo Black Soup Recipe (#1 Ultimate way)". FitNigerian (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-11-06. Retrieved 2022-06-26.