Jump to content

Ẹ̀gbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Egba)
Abule egba ní Ìpínlè Èkó, orílè-èdè Nàìjíríà

Ẹ̀gbá je eya Yoruba ni Naijiria.


Ó se pàtàkì láti mọ díẹ̀ nípa ìtàn ilẹ̀ Ẹ̀gbá àti irú ènìyàn tí ń gbé ìlú Ẹ̀gbá. Ìdí èyí ni pé yóò jẹ́ ohun ìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó yẹ ní mímọ̀ nínú orin ògódò. Fún ìdí pàtàkì yìí, n ó ò pín àkòrí yìí si ọ̀nà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.[1]

Ìtàn ṣókí nípa Ẹ̀gbá láti ẹnu ọmọ bíbí ìlú Ẹ̀gbá.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ onímọ̀ ló ti sọ nípa bí a ti se tẹ ilẹ̀ Ẹ̀gbá dó, tí wọn sí tì gbé àbọ̀ ìwádìí wọn fún aráyé rí. Ara irú àwọn báyìí ni Samuel Johnson, Sàbúrì Bíòbákú,[2] Ajísafẹ́, Délànà àti àwọn mìíràn tó jẹ́ òpìtàn àtẹnudẹ́nu.[3]

Johnson gbà pé Ọ̀yọ́ ni àwọn Ẹ̀gbá ti wá. O ní àwọn ẹ̀yà Ẹ̀gbá tòótọ́ lé ti orírun wọn de Ọ̀yọ́. ó tún tẹ̀ síwájú síi pé ọmọ àlè tàbí ẹrú ni Ẹ̀gbá tí kò bá ní orírun láti Ọ̀yọ́. Àwọn olóyè wọn wà lára àwọn Ẹ̀sọ́ Aláàfin láyé àtijọ́, àtipé àwọn olóyè yìí ló sá wá sí Abẹ́òkúta lábẹ́ olórí wọn tó jẹ́ àbúrò ọba Ọ̀yọ́ nígbà náà.[4]

Délànà ní tirẹ̀ ní etí ilé-ifẹ̀ ni àwọn Ẹ̀gbá tó kọ́kọ́ dé tẹ̀ dó sí. Àwọn ni ó pè ní Ẹ̀gbá Gbàgùrà. Wọ́n dúró súú sùù súú káàkiri. Olú ìlú wọn sì ni “ÌDDÓ” tí ó wà níbi tí Ọ̀yọ́ wà báyìí. Àwọn ìsí kejì sun mọ ìsàlẹ̀ díẹ̀. Wọ́n kọjá odò ọnà. Àwọn ni Ẹ̀gbá òkè-ọnà. Òsilẹ̀ ni ọba wọn. Òkó ni olú ìlú wọn .Ẹ̀gbá Aké ló dé gbẹ̀yìn.

Ajísafẹ́ ní ọ̀tẹ̀ ló lé àwọn Ẹ̀gbá kúrò ni ilé- ifẹ̀ wá Kétu. Láti Kétu ni wọn ti wá sí Igbó- Ẹ̀gbá kí wọn to de Abẹ́òkúta ní 1830. Sàbúrí Bíòbákú náà faramọ́ èyí. Lọ́rọ̀ kan sá, àwọn Ẹ̀gbá ti ilé- ifẹ̀ wá, wọ́n ni ohun i se pẹ̀lú oko Àdágbá, Kétu, àti igbó-Ẹ̀gbá. Ìtàn tún fi yé ni síwájú sii pé ìlú Ẹ̀gbá pọ̀ ní orílẹ̀ olúkúlùkù ló sì ń ní ọba tirẹ̀, fífọ́ tí orílẹ́ Ẹ̀gbá fọ́ lò gbé wọn dé ibi tí wọ́n wà báyìí. Gẹ́gẹ́ bí Ìtàn ti sọ, 1821 ni Ìjà tó fọ́ gbogbo Ìlú Ẹ̀gbá ti sẹlẹ̀. Ohun kékeré ló dá Ìjà sílẹ̀ láàárín àwọn òwu àti àwọn Ìjẹ̀bú ni ọjà Apòmù, Ogun Ọ̀yọ́ àti tí ifẹ̀ dà pọ̀ mọ́ ogun Ìjẹ̀bú láti bá Òwu jà. Àgbáríjọ ogun yìí dé ìlú àwọn Òwu ní tọ̀ọ̀ọ́tọ́ sùgbọ́n àwọn Òwu lé wọn padà títí wọ́n fi dé àárín àwọn Gbágùrá to wa ni Ìbàdàn. Inú àwọn Gbágùrá kò dùn sí è́yí wọ́n ti lérò pé ogun yóò kó àwọn Òwu. Èyí náà ló sì mú àwọn Gbágùrá tún gbárajọ láti pẹ̀lú ogun Ọ̀yọ́, Ìjẹ̀bú àti ifẹ̀ kí wọn le borí ogun Òwu. Wọ́n sẹ́gun lóòótọ́ sùgbọ́n lánlẹ́yìn, àkàrà Ríyìíkẹ́ ni ọ̀rọ̀ náà dà nígbẹ̀yìn. Òjò ń podídẹrẹ́ ni, àwòko ń yọ̀. Kò pẹ́ ẹ̀ ni ogun Ìjẹ̀bú, Ìjẹ̀sà, Ọ̀yọ́ àti ifẹ̀ rí i mọ́ pé àsé àwọn Ẹ̀gbá kò nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ tẹ̀ǹbẹ̀ lẹ̀kun sí àwọn Ẹ̀gbá. Wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ kó gbogbo Ìlú wọn tán lọ́kọ̀ọ̀kan.

Èyí tí ó wá burú jù níbẹ̀ ni ti IKÚ Ẹ́GẸ́ tó jẹ olóyè ifẹ̀ kan. Lámọ́di asíwájú Ẹ̀gbá kan ló páa nígbà tí ǹ dìtẹ̀ mọ ọn. Sùgbọ́n àwọn ọ̀tá kò sàì pa òun náà sán. Ọ̀tẹ̀ àti tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun tí wọn ń dí mọ́ àwọn Ẹ̀gbá yìí ló mú wọn pinnu láti kúrò ní ibùjókòó wọ́n. Àwọn babaláwo wọn gbé ọ̀pẹ̀lẹ̀ sánlẹ̀, wọn rí odù òfúnsàá. Wọ́n kifá lọ wọ́n kifá bọ̀, wọ́n ní wọn yóò dé Abẹ́òkúta, àwọn aláwọ̀ funfun yóò sì wá láti bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn babaláwo wọn náà ni Tẹ́jú osó láti Ìkìjà Òjo (a ń-là-lejì- ogbè) ara Ìlúgùn àti Awóbíyìí ará irò. 1830 Sódẹkẹ́ lo sáájú pẹ̀lú àwọn Ẹ̀gbá Aké. Balógun Ìlúgùn kó Ẹ̀gbá òkè-ọnà kẹ́yìn. Wọn kò rántí osù tí wọ́n dé Abẹ́òkúta mọ́ sùgbọ́n àsìkò òjò ni.

Nígbà tí wọn kọ́kọ́ dé, wọ́n do sí itòsí Olúmọ, olúkúlùkù ìlú sa ara wọn jọ, wọn do kiri Ẹ̀gbá Aké, Ẹ̀gbá òkè-ọnà àti Ẹ̀gbá Gbágùrá ló kọ́kọ́ dé sí Abẹ́òkúta. Ni 1831 ni àwọn Òwu sẹ̀sẹ̀ wá bá wọn tí àwọn Ẹ̀gbá sì gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀. Àwọn Ẹ̀gbádò tí wọ́n bá ní Ìbarà ló sọ wọ́n ni Ẹ̀gbá, nínú ọ̀rọ̀ “Ẹ̀GBÁLUGBÓ” ni wọ́n sì tí fa ọ̀rọ̀ náà yọ. Àwọn òpìtàn ní àwọn Ẹ̀gbádò ni ń gbé ìpadò nígbà tí àwọn Ẹ̀gbá ní gbé ni òkè ilẹ̀. Òpìtàn míìràn tún ní ìtumọ̀ Ẹ̀gbá ni “Ẹ GBÀ Á “ lálejò nítorí pé wọ́n gba àwọn Òwu àti àwọn mìíràn tí wọ́n ń wá abẹ́ ààbò sá sí mọ́ra.

ÀWỌN Ẹ̀YÀ TÓ WÀ NÍLẸ̀ Ẹ̀GBÁ LÓDE ÒNÍ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹ̀yà orísìírísìí tó wà nílẹ̀ Ẹ̀gbá ló jẹ́ kí ó di ìlú ń lá, pẹ̀lú ìjọba àkóso tó lágbára ogun ló sọ ọ́ di kékéré bó ti wàyìÍ. Ní apá Àríwá, ó fẹ̀ dé odò ọbà, ní gúúsù ó gba ilẹ̀ dé Èbúté mẹ́ta, lápá Ìlà Ìwọ̀ oòrùn (Ẹ̀gbádò) Johnson ní ìlú mẹ́tàlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ́ta (503) ló parapọ̀ dé Abẹ́òkúta lonìí yìí. Orísìí mẹ́rin ni àwọn Ẹ̀gbá tó wà ní Abẹ́òkúta lónìí. Kò parí síbẹ̀ àwọn miiran tún wà tí wọn ti di Ẹ̀gbá lónìí. Sé tí ewé bá pẹ́ lára ọsẹ, kò ní sàì di ọsẹ. Èkíní nínú àwọn ẹ̀yà Ẹ̀gbà yìí ni Ẹ̀gbá Aké. Orísìírísìí ìlú ló tẹ̀ ẹ́ dó, ìdí nìyí tí àwọn Ẹ̀gbá tó kù se ń sọ pé “Ẹ̀GBÁ KẸ́GBÁ PỌ̀ LÁKÉ”. Aké ni olú ìlú wọn. Àwọn ìlú tó kù lábẹ́ Ẹ̀gbá Aké ni Ìjokò, Ìjẹùn, Ọ̀bà, Ìgbẹ̀Ìn, Ìjẹmọ̀, Ìtọ̀kú, imọ̀, Emẹ̀rẹ̀, Kéesì, Kéǹta, Ìrò, Erunwọ̀n, Ìtórí, Ìtẹsi, Ìkọpa, Ìpóró ati Ìjákọ.

Ẹ̀gbá òkè-ọnà ló tẹ lẹ́ Ẹ̀gbá Aláké. Osìlè ni ọba wọn, oun ni igbákejì Aláké. Òkò ni olú ìlú wọn. Àwọn ìlú tó kù lábẹ́ Ẹ̀gbá òkè -ọnà ni Ejígbo, Ìkìjà, Ìjẹjà, odo, Ìkèrèkú, Ẹ̀runbẹ̀, Ìfọ́tẹ̀, Erinjà, ilogbo àti Ìkànna. Ẹ̀gbá Gbágùrá ni orísìí kẹta. Ìdó ni olórí ìlú wọn. Àgùrá si ni ọba wọn. Àwọn Ìlú to kù ni ọ̀wẹ̀, Ìbàdàn, Ìláwọ̀, Ìwéré, òjé ati àwọn ìlú mọ́kàndínlógoji (39) mìírán.Nígbà tí ogun bẹ sílẹ̀ ni mẹ́sàn-án lara ìlú Gbágùrá sá lọ fi orí balẹ̀ fún Ọlọ́yọ̀ọ́ títí di òní yìí. Àwọn ìlú naa ni Aáwẹ́, Kòjòkú Agéníge, Aràn, Fìdítì, Abẹnà, Akínmọ̀ọ́rìn, Ìlọràá àti Ìròkò.

Ẹ̀gbá Òwu ni orísìí kẹrin, Àgó-Òwu ni olú ìlú wọn, Olówu ni ọba wọn, ìlú tó kù lábẹ́ Òwu ni Erùnmu, Òkòlò, Mowó, Àgọ́ ọbà, àti Apòmù. Yàtọ̀ sí àwọn tí a sọ̀rọ̀ rẹ lókè yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀yà míìràn náà ló pọ̀ ní Ẹ̀gbá tí wọ́n ti di ọmọ onílẹ̀ tipẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn báyìí ni a kó lásìkò ogun tàbí kí wọn wá fúnra wọn nígbà tí wọn ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn, tí wọn sì ǹ wá ibi isádi. Irú àwọn báyìí ni Ègùn tí wọn wá ni Àgọ́- Ègùn, Ìjàyè- ni Àgọ́- Ìjàyè, àti àwọn Ìbàràpá ni Ìbẹ̀rẹ̀kòdó àti ni Arínlẹ́sẹ̀. Bákannáà ni àwọn Ẹ̀gbádò wà ní Ìbàrà iléwó, onídà àti oníkólóbó bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí sáájú Ẹ̀gbá dó síbẹ̀.

ÈTÒ ÌSÈLÚ ÀTI TI ỌRỌ̀ AJÉ ILẸ̀ Ẹ̀GBÁ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láti ìgbà tí àwọn Ẹ̀gbá ti dó sí Abẹ́òkúta ni ètò ìsèlú wọn ti bẹ̀rẹ̀ si yàtọ̀. Ó di pè wọn ń yan ọba kan gẹ́gẹ́ bí olórí gbogbo gbò. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, kọ́lọ́mú dọ́mú Ìyá rẹ gbé ni. Èyí náà ló sì fìyà jẹ wọ́n. ÀÌrìnpọ̀ ejò ló sá ǹ jẹ ejò níyà.Sé bọ́ká bá síwájú, tí pamọ́lẹ̀ tẹ le e, tí baba wọn òjòlá wá ń wọ́ ruru bọ̀ lẹ́yìn, kò sí baba ẹni tó jẹ dúró. Ọ̀rọ̀ “èmi –ò-gbà ìwọ -ò -gbà” yìí ló jẹ́ kí àwọn alábàágbé Ẹ̀gbá maa pòwe mọ́ wọn pe “Ẹ̀gbá kò lólú, gbogbo wọn ló ń se bí ọba” Ọba wá di púpọ̀.

Ìjọba ìlú pín sí ọ̀nà bíi mẹ́rin nígbà tí ọ̀kan wọn balẹ̀ tán ni ibùdó titun yìí. Àkọ́kọ́ nínú wọn ni àwọn Ológbòóni. Ìlú kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ẹgbẹ́ yìí fún ra rẹ̀. Lóòtọ́, ọba ló nilẹ̀, òun ló sì ń gbọ́ ẹjọ́ tó bá tóbi jù. Sị́bẹ̀ síbẹ̀, àwọn Ògbóni lágbára ju ọba lọ. Àwọn ni òsèlú gan-an. Àwọn ló ń pàsẹ ìlú. Wọn lágbára láti yọ ọba lóyè. Delanọ ní láti ilé-ifẹ̀ ni Ẹ̀gbá tí mú ètò Ògbóni wá. Wọn tún un se, wọn sì jẹ́ kí o wúlò tóbẹ́ẹ̀ tí ilé-ifẹ̀ pàápàá ń gáárùn wo ògbóni Ẹ̀gbá.

Orò ni wọn ń lò láti da sẹ̀ríà fún arúfin ti ẹ̀sẹ̀ rẹ tòbi. Bí orò bá ti ń ké ní oru yóò máa bọ̀ lákọlákọ. Olúwo ni olórí àwọn ògbóni. Àwọn oyè tó kù tó sì se pàtàkì ní Apèènà, Akẹ́rẹ̀, Baàjíkí, Baàlá, Baàjítò, Ọ̀dọ̀fín àti Lísa{. Àwọn olórógun tún ní àwọn ẹgbẹ́ kejì tó ń tún ìlú tò. Láti inú ẹgbẹ́ àáró tí ọkùnrin kan ti n jẹ Lísàbí dá sẹ́lẹ̀, ní ẹgbẹ́ olórógun ti yọ jáde. Ọjọ́ kẹtàdínlógún kẹtàdínlógún ni wọ́n ń se àpèjọ wọn. Àwọn náà ló gba Ẹ̀gbá kalẹ̀ lọ́wọ́ ìyà tí Ọlọ́yọ̀ọ́ àti àwọn Ìlàrí rẹ fi ń jẹ wọn. Ara àwọn oyè tí wọn ń jẹ ni jagùnà (ajagun lójú ọ̀nà) olúkọ̀tún (olú tí Í ko ogun òtún lójú), Akíngbógun, Òsíẹ̀lẹ̀ àti Akílẹ́gun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ni wọn si ti sẹ. Àwọn pàràkòyí náà tún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì tí ọrọ ba di ti ọrọ̀ ajé àti ìsèlú. Àwọn ni n parí ìjà lọ́jà, àwọn ló n gbowó ìsọ ̀. Asíwájú àwọn pàràkòyí ni olórí pàràkòyí.

Àwọn ọdẹ pàápàá tún jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn atúnlùútò. Wọ́n ń dá ogun jà nígbà mìíràn. Àwọn ni wọn n sọ ọjà àti gbogbo ìlú lóru. Àwọn olóyè ọdẹ jàǹjàǹkàn naa a maa ba àwọn tó wà ní ìgbìmọ̀ ìlú pésẹ̀ fún àpérò pàtàkì. Díẹ̀ lára oyè tí wọn n jẹ ni Asípa, olúọ́dẹ àti Àró ọdẹ.

Bí ọ̀rọ̀ kan ba n di èyí ti apá lé ko ka, o di ọdọ olórí àdúgbò nì yẹn. Bí kò bá tún ni ojútùú níbẹ̀, a jẹ́ pé ó di tìlùú nì yẹn ọba lo maa n dájọ́ irú èyí nígbà náà. Tí a bá ka a ni ẹní , èjì ó di ọba mẹsan an to ti jẹ láti ìgbà ti wọn ti de sí Abẹ́òkúta. Àwọn náà nìwọ̀n yii


ORÚKỌ ỌBA ̀ TÍ Ó JẸ . ÀKÓKÒ TÍ Ó KÚ.

ÒKÚNKẸ́NÚ 28/08/1854 31/08/1862

ADÉMỌ́LÁ 28/11/1869 30/12/1877

OYÉKÀN 18/01/1878 18/12/1881

OLÚWAÁJÌ 09/02/1885 27/01/1889

SÓKÁLÙ 18/09/1891 11/06/1898

GBÁDÉBỌ̀ 08/08/1898 28/05/1920

ADÉMỌ́LÁ II 10/07/1920 27/12/1962

GBÁDÉBỌII 12/08/1963 26/10/1971

LÍPẸ̀Ẹ́DẸ́ I 10/08 1972 ……………

Yàtọ̀ sí ọba Aláké tí a to orúkọ wọn sókè yìí, ọba mẹ́rin míìrán tún sì wà ní Abẹ́òkúta tí wọn ń se olórí ìlú wọn. Sùgbọ́n, gbogbo wọn tún sì wà lábẹ́ aláké gẹ́gẹ́ bii ọba gbogbo gbò ni. Àwọn ọba náà ni, Àgùrà Olówu, Òsilẹ̀ àti olúbarà. Ọba aládé sì ni gbogbo wọn. Ní ti oyè tó kù nílùú, o ní agbára tí wọn fún ìlú kọ̀ọ̀kan láti fi olóyè sílẹ̀. Ẹ̀gbá òkè- ọnà ló ń yan ọ̀tún ọba. Ẹ̀gbá Gbágùrá lo n fi òsì àti Òdọ̀fin sílẹ̀. Ẹ̀gbá Òwu lo si n yan Ẹ̀kẹrin ìlú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jàǹkànjàǹkàn tó ti fi ẹ̀mí wọn wu ewu fún Ẹ̀gbá ni wọ́n máa ń ráńtí nínú gbogbo orin wọn. Wọn a sì máa fi orúkọ wọn búra pàápàá. Irú àwọn báyìí ni Sódẹkẹ́, Lísàbí, Ẹfúnróyè, Tinúubú ati Ògúndìpẹ̀ Alátise. Àwọn Ẹ̀gbá kò kó iyán wọn kéré wọn kò sì yé bu ọlá fún wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kú.

Orísìí ètò ìjọba mẹ́rin ọtọ̀ọ̀ọ̀tọ̀ ni ó ti kọjá ní ilẹ̀ Ẹ̀gbá kí á tó bọ sí èyí tí a wà lóde òní.

Ètò ìbílẹ̀ lábẹ́ àsẹ Ògbóni àti Pàràkòyí 1830-1865

Ẹ̀gbá United Board of Management 1865-1898

Ẹ̀gbá United Government (Ìjọba Ẹ̀gbá) 1898 – 1914

Ẹ̀gbá Native Administration (Ìjọba Ìbílẹ̀) 1914 – 1960

ISẸ́ ÀWỌN Ẹ̀GBÁ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orísìírìsìí isé ajé ni àwọn Ẹ̀gbá n mú se nínú ìlú. Yàtọ̀ sí isẹ́ àgbẹ̀ tó jẹ́ tajá tẹran ló ń seé wọ́n fẹràn láti máa da aró, wọ́n mọ̀ nípa àdìrẹ ẹlẹ́kọ dáadáa. Wọ́n tún nífẹ̀ẹ́ si òwò síse. Àwọn àbọ̀ ilẹ̀ sàró ni ó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ òwò síse yìí túbọ̀ gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Kò sí ìlú kan tí kò ní ọjà tirẹ̀, sùgbọ́n àwọn ọjà ń lá kan wà tó ti di ti gbogbo gbo. Irú àwọn ọjà báyìí ni Ìtọ̀kú, Ìta Ẹlẹ́gà, ọjà ọba àti Ìbẹ̀rẹ̀kòdó. Paríparí rẹ̀ àwọn Ẹ̀gbá fẹ́ràn láti máa kọrin lásán.yálà kíkọ tà gẹ́gẹ́ bí alágbe tàbí ìfẹ́ láti máa kọrin lásán. Gbogbo ohun tó sì ti sẹlẹ̀ sí àwọn baba ńlá wọn ni wọ́n máa ń mú lò nínú orin wọn pàápàá.

ÌBÁSEPỌ̀ TÓ WÀ LÁÀÁRÍN ÀWỌN Ẹ̀YÀ Ẹ̀GBÁ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A ti sọ pé kálukú ẹ̀yà Ẹ̀gbá ló ń da ọmú ìyá rẹ̀ gbé, sị́bẹ̀, kò sàìsí ìbásepọ̀ díẹ̀ láàárín wọn. Lọ́nà kìnní, gbogbo Ẹ̀gbá ló gbà Abẹ́òkúta sí ìlú wọn.Wọn ni ilẹ̀ níbẹ̀, sùgbọ́n wọn a máa lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti lọ múlẹ̀ oko. Ní ìparí ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń wálé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú oko ẹ̀yìn odi ìlú báyìí lo ti di ìlú fún wọn. Abúlé ni wọn n pe àwọn ìletò wọ̀nyí. Kò sí ọmọ Ẹ̀gbá kan tí kò ní abúlé . Ètò abúlé wọ́ pọ̀, ó sì gún régé, Baálẹ̀ tàbí olóróko (olórí oko) ni o wà ní ipò ọ̀wọ̀ jùlọ.

Bákan náà ló jẹ́ pé gbogbo wọn lo jọ ń bú ọlá fún àwọn ẹni ńlá wọn. Kò sí pé apá kan kò ka àwọn ẹni àná yìí wọ̀nyìí́ kún. Orò tún jẹ́ ẹ̀sìn kan tó so wọ́n pọ̀. Nílélóko ni wọn ti ń sọdún orò lọ́dọọdún. Àwọn olórò ìlú kan lè mú orò wọn dé ìlú mìíràn láìsí ìjà láìsí ìta. Lóòótọ́, ìlú kọ̀ọ̀kan ló ní òrìsà tirẹ̀ tó se pàtàkì, fún àpẹẹrẹ, àwọn Òwu ló ni Òtòǹpòrò àti Ẹlúkú. Àwọn Odò ọnà ló ni Agẹmọ, àwọn ìbarà lo ni Gẹ̀lẹ̀dẹ́. Òrìsà Àdáátán, ọ̀tọ̀ ni. O máa ń sẹlẹ̀ ni ọ̀pọ̀ ìgbà pé tí ìlú kan bá parí ọdún tiwọn lónìí, tí àdúgbò míìràn le bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ keje ẹ̀. Èyí kò sí yi padà láti ọjọ́ pípẹ́ wá.

Ọjà kan náà ni wọn jọ́ ń ná, oúnjẹ ti wọn ń jẹ ní Aké ni wọn ń jẹ ní Òkò. Wọn fẹ́ràn àmàlà láfún púpọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń jẹ Sapala kòkò, ewé, awújẹ àti èsúrú. “Mo lérò pé pẹ̀lú gbogbo àlàyé mi òkè yìí ìrànlọ́wọ́ ni yóò jẹ fún àwọn ohun ti a ó ò máa kan nínú orin Ògóló níwájú, àwọn ọ̀rọ̀ tí ìbá si ru ni lójú tẹ́lẹ̀ ni yóò di ohun ti yóò tètè yé ni”.

  1. "Egba History in Brief". Opera News. 2020-04-29. Archived from the original on 2023-06-12. Retrieved 2023-06-12. 
  2. Biobaku, S.O. (1957). The Egba and Their Neighbors. Clarendon Press. https://books.google.com.ng/books?id=egyJnQEACAAJ. Retrieved 2023-06-12. 
  3. "Abeokuta’s Living History". ktravula - a travelogue!. 2014-04-16. Archived from the original on 2023-06-12. Retrieved 2023-06-12. 
  4. "Ẹ̀gbá – villagespec.com". villagespec.com. 2019-04-02. Retrieved 2023-06-12.