Emere

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Emere

Olatinwo Adeagbo

Adeagbo

Ọlátìńwò Adéagbo Fátokí (1991) Emèrè. Ìbàdán, Nigeria: Heineman Educational Books Nig. PLC. ISBN 978-129-234-2. Ojú-ìwé 53.

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

Ohun tó gbé mi dé ìdí à ń kọ ìwé yìí ni ìgbàgbọ́ àti ihà tí àwọn ènìyàn kọ sí àwọn ọmọ tí à ń pè ní Emèrè. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rí àwọn ọmọ wọ̀nyìí gẹ́gẹ́ bí Àbíkú, Ẹlẹ́gbẹ́, Ọ̀gbáńje, Ọmọ Ìyanu, Abáfẹ́fẹ́rìn-ọmọ Ẹlẹ́mìíkẹ́mìí-ọmọ àti Adíwọ̀n-ọmọ. Àwọn orúkọ wọ̀nyìí fi hàn pé ìṣòro ńlá wà láti dá Emèrè mọ̀. Lọ́wọ̀ọ́ ìgbà tó sì jẹ́ pé a ko le fi Ògún rẹ̀ gbárí pé Emèrè nìyìi, mo wá lọ sí Àròjinlẹ̀ ọkàn, mo pe kọ́lọ́fín ọpọlọ jáde, mo wá rí i pé Emèrè jẹ́ Àjíǹde-òkú tó ń pọ́n ọ̀bẹ sùn, tó tún fapò rọrí. Gbogbo ara ni wọ́n fi ṣe agbára. Ẹ̀mí àìrí tó sì ń bá wọn lò jẹ́ èyí tó ṣòro láti ṣàpèjúwe. Ọmọ kàyéfì ni Emèrè. À ní Àdánwò-ọmọ ni wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì dúró fún tibi-tire tó bá bá àwọn lọ́kọláyà tó bá lùgbàdì wọn. Ní ti agbára, wọ́n ní agbára ju Àjẹ́ àti Oṣó lọ. Ẹ̀yìn Ìyà mi, apani-má-hàá-Ogún, ìbà! Pẹ̀lú fàájì ni Emèrè ṣe ń wọ inú obìnrin-kóbìnrin. Taa ni yóò yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ wò? Wọ́n ní agbára láti yí padà tàbí taari ọmọ inú aboyún jáde nígbà tí wọ́n bá fẹ́ lo ààyè ibẹ̀. …