Jump to content

Emma Dabiri

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Emma Dabiri
Dabiri in 2021
BornDublin, Ireland
Alma mater
Influences

Emma Dabiri FRSL (tí wọ́n bí ní 25 March 1979) jẹ́ òǹkọ̀wé, onímọ̀ àti akàròyìn ọmọ orílẹ̀-èdè Ireland. Ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́ ni àkọlé rẹ̀ ń jẹ́, Don't Touch My Hair, ni ó tẹ̀ jáde ní ọdún 2019. Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ẹgbẹ́ he Royal Society of Literature ní ọdún 2023.[1]

Ìgbésí ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú Dublin ni wọ́n bí Dabiri sí, ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ireland, bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ Yorùbá, láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lẹ́yìn tó lo ìbẹ̀rẹ̀ ọdún rẹ̀ ní ìlú Atlanta, ní Georgia, ìdílé rẹ̀ padà lọ sí Dublin, nígbà tí Dabiri wà ní ọmọ-ọdún márùn-ún.[2] Ó ní pé òun dá wà lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà, nígbà tí òun ń dàgbà nítorí ẹlẹ́yàmẹyà.[3] Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó kó lọ sí ìlú London láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa African Studies ní School of Oriental and African Studies. Ẹ̀kọ́ rè ló mu bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ akàròyìn, ó sì jẹ́ olóòtú ètò BBC Four's Britain's Lost Masterpieces, ètò orí Channel 4, bí i Is Love Racist?, àti ètò orí rédíò kan tó pè ní Afrofuturism, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[4]

Àwọn ìwé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Creamer, Ella (12 July 2023). "Royal Society of Literature aims to broaden representation as it announces 62 new fellows". The Guardian. https://www.theguardian.com/books/2023/jul/12/royal-society-of-literature-aims-to-broaden-representation-as-it-announces-62-new-fellows. 
  2. Dabiri, Emma (27 April 2019). "I'm Irish but not white. Why is that still a problem 100 years after the Easter Rising?". Irish Times. https://www.irishtimes.com/news/ireland/irish-news/i-m-irish-but-not-white-why-is-that-still-a-problem-100-years-after-the-easter-rising-1.2590841. 
  3. Ganatra, Shilpa (27 April 2019). "Emma Dabiri: 'I wouldn't want my children to experience what I did in Ireland'". Irish Times. https://www.irishtimes.com/life-and-style/people/emma-dabiri-i-wouldn-t-want-my-children-to-experience-what-i-did-in-ireland-1.3866197. 
  4. "Irish writer and actor among the rising stars of 2019". Irish Central. 11 January 2019. https://www.irishcentral.com/culture/entertainment/irish-rising-stars-2019.