Emma Nyra

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Emma Nyra
Emma Nyra on ndanitv
Ọjọ́ìbíEmma Chukwugoziam Obi
18 Oṣù Keje 1988 (1988-07-18) (ọmọ ọdún 35)
Tyler, Texas, U.S
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaTexas Southern University
Iṣẹ́
  • model
  • Actor
Àwọn ọmọ2
Websiteemmanyra.com
Musical career
Irú orinafropop, soul, R&B
Occupation(s)singer-songwriter, vocalist
InstrumentsVocals
Years active2011–present
LabelsIndependent
Associated acts

Emma Chukwugoziam Obi (tí a bí ní 18 Oṣù Keèje, Ọdún 1988)[1] tí a mọ̀ sí Emma Nyra jẹ́ òṣèrébìnrin, akọrin, àti afẹwàṣiṣẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà.[2]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Emma Nyra ni a bí tó sì dàgbà ní agbègbè Tyler ní ìlú Texas, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó ní ètò-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ìlú yìí bákan náà, níbẹ̀ ló sì tún ti gba oyè-ẹ̀kọ́ nígbà tí ó fi lọ sí Texas Southern University tó sì kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìsàkóso Ìlera. Ní ọdún 2012, ó gbéra wá sí Nàìjíríà láti lépa iṣẹ́ orin àti afẹwàṣiṣẹ́.[3]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Iṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Emma Nyra ṣe àgbéjáde àwọn àkọ́kọ́ orin rẹ̀ tí àkólé wọn ń ṣe "Do It" àti "Everything I Do" ní ọdún 2011 ní àkókò tí ó wà ní Amẹ́ríkà. Lẹ́hìn tí ó padà sí Nàìjíríà ní ọdún 2012, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ pẹ̀lu D'Tunes àti Iyanya, àwọn tí ó ti pàdé ní ọdún 2010 ní Amẹ́ríkà.

Ní ọdún 2013, Emma Nyra gba àmì-ẹ̀yẹ òṣèré tí ó ní ìlérí jùlọ níbi ayẹyẹ Nigeria Entertainment Awards. Ó ti wá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn òṣèré akọrin bíi Davido, Patoranking, Olu Maintain àti àwọn míràn. Àkọ́kọ́ àkójọpọ̀ àwọn orin rẹ̀ tí ó pe àkólé rẹ̀ ní Emma Nyra Hot Like Fiya Vol. 1 kò tíì jẹ́ gbígbéjáde.[4]

Iṣẹ́ fíìmù rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Yàtọ̀ sí orin kíkọ, Emma Nyra tún jẹ́ òṣèré.[5] Ó ti kópa nínu àwọn fíìmù mẹ́ta tí àkọ́lé wọn ń jẹ́ American Driver,[6] Rebound àti The Re-Union.[7]

Àwọn ìyẹ́sí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún Ayẹyẹ Ẹ̀ka Èsì Ìtọ́kasí
2013 2013 Nigeria Entertainment Awards Gbàá [8]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Omigie, Abiodun (July 21, 2013). "PHOTOS: Surprise birthday party for Iyanya protegee Emma Nyra". Nigerian Entertainment Today. http://thenet.ng/2013/07/photos-surprise-birthday-party-for-iyanya-protegee-emma-nyra/. Retrieved May 28, 2016. 
  2. "Why I wore what I wore at Channel O award – Emma Nyra". Vanguard Newspaper. December 6, 2014. http://www.vanguardngr.com/2014/12/wore-wore-channel-o-award-emma-nyra/. Retrieved May 28, 2016. 
  3. Wha'anda, Sam (October 31, 2014). "Hot Like Fire:Emma Nyra's Love For Cleavage Exposure". Pulse Nigeria. http://pulse.ng/hotpulse/hot-like-fire-emma-nyras-love-for-cleavage-exposure-id3238976.html. Retrieved May 28, 2016. 
  4. Dupe Ayinla-Olasunakanmi (June 20, 2015). "Emma Nyra takes on personal projects". The Nation News. http://thenationonlineng.net/emma-nyra-takes-on-personal-projects/. Retrieved May 28, 2016. 
  5. "Sultry singer, Emma Nyra ventures into acting". Television Continental. March 11, 2016. http://tvcontinental.tv/2016/03/11/emma-nyra-joins-davido-falzacts-nollywood-industry/. Retrieved May 28, 2016. 
  6. Izuzu, Chidumga (March 11, 2016). ""American Driver":Jim Iyke, Nadia Buari, Nse Ikpe-Etim, Emma Nyra star in new film". Pulse Nigeria. http://pulse.ng/movies/american-driver-jim-iyke-nadia-buari-nse-ikpe-etim-emma-nyra-star-in-new-film-id4790061.html. Retrieved May 28, 2016. 
  7. O., Ovie (November 11, 2011). "Emma Nyra – Do It ft Eno Will + Everything I Do". notJustOk. Archived from the original on August 5, 2016. https://web.archive.org/web/20160805061215/http://notjustok.com/2011/11/01/emma-nyra-do-it-ft-eno-will-everything-i-do/. Retrieved May 28, 2016. 
  8. Aiki, Damilare (September 2, 2013). "2013 Nigeria Entertainment Awards: Full List of Winners & Scoop". https://www.bellanaija.com/2013/09/2013-nigeria-entertainment-awards-full-list-of-winners-scoop/. Retrieved May 28, 2016. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]