Ere idaraya

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àwọn ọmọdé tó'nṣeré okùnmẹ́ran

Eré ìdárayá jẹ́ àṣà àti ọ̀nà ìdárayá jákè-jádò ilẹ̀ Yorùbá nígbà tí ọwọ́ bá dilẹ̀. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní "ohun gbogbo ni ìgbà àti àkókó ńbẹ fún". Ìran Yorùbá fẹràn iṣẹ́ ṣíṣe lọ́pọ̀lọpọ̀. Wọ́n sì gbàgbọ́ wí pé iṣẹ́ ni òògùn ìṣẹ́. Ṣùgbọ́n bí wọ́n ti fẹràn iṣẹ́ tó, ó ní àwọn àkókò tí wọ́n máa ń fi sílẹ̀ fún eré ṣíṣe ninu ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Iru akoko bẹẹ ni a mọ si akoko ere idaraya. Eyi fi han pe kii ṣe awọn oyinbo ni o mu ere idaraya de ilẹ Yoruba. Yoruba ka ere idaraya si ere pataki nitori o ye wọn pe ipa ti o gbopọn ni ere idaraya nko ninu alaafia ara ati ẹmi gigun. Bi ere idaraya ṣe wa fun awọn ọmọ ọwọ ati ọmọ irinsẹ naa ni o wa fun ọmọde ati agbalagba. Bi ere abẹle ti wa naa ni ti an ṣe ni ita wa. Oriṣiiriṣii ni ere idaraya ti a maa n ṣe nilẹ Yoruba, pupọ si ni ko mu agbara dani nitori lẹyin iṣẹ agbara ni Yoruba nṣe wọn. Wọn wa lati fun ara ni isinmi lẹyin iṣẹ oojọ. Awọn ere idaraya kan wa fun ilera, lati mu ki ara laagun. Awọn miiran wa fun inaju, awọn kan wa gẹgẹ bii amuṣẹya. Bẹẹ ni awọn isọri miiran wa fun dida ọpọlọpọ laraya. Lara ere idaraya Yoruba ni ere ayo, arin, okoto, ijakadi, kannakanna, ere oṣupa, ere alọ, adendele, ki-ni-n-lẹjẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ayò Títa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ayò títa jẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn eré ilẹ̀ Yorùbá ti wọn maa fi dárayá l'ẹhin iṣẹ́ oojọ wọn. Eré abẹ́lé tí kò gba agbára ni eré ayò, bẹẹ si ni ori ìjokòó ni wọ́n ti nta á. Ọ̀sán tàbí ìrọ̀lẹ́ ni wọ́n ń ta ayò ní ìgbà tí wọ́n bá ṣíwọ́ oko wá sí ilé. "Eré l'a nfi ọmọ ayò ṣe". Òwe nai

gbólóhùn yì l'ede Yoruba. O si jasì pe eré ayo kii ṣe nkan ìjà tabi ohun ti o le mu ìkùnsínú wa. Bi a ba si tun f'eti si awọn àgbàlabà nigbamiran, a o gbọ ti wọn nsọ bayi pe "T'ọmọdé t'agba ni iyọ mọ ọmọ ayò. Eyi tun fihan kedere pe ko si ẹni ti ki i ta ayò. Eèyàn méjì ni ó má ń jòkóò láti tayò. Wọn yóò jókòó dojú kọ ara wọn. Ọpọ́n ayò yóò sì wà láàrin wọn.

Ọpọ́n ayò jẹ ohun èlò ayò títa ti o ni ihò méjìlá tí à ń da ọmọ ayó si, tí mẹ́fà-mẹ́fà kọjú sí ara wọn. Ihò mẹ́fà yóò wà lọ́dọ̀ ẹni kì-ín-ní. Ihò mẹ́fà yóò wà lọ́dọ̀ ẹni kejì. L'oju ọpọ́n ayò mìíràn, ihò náà lè jẹ́ mẹ́rìnlá. Ihò kọ̀ọ̀kan tò lé yìí a si maa wa ni apá ọtún ati apá òsi ọpọ́n naa. Ihò meji yi wa fun lilo awọn ọ̀tayò lati tọ́jú ayò ti wọn bá jẹ sí. Nígbà mìíràn, àwọn ènìyàn máa ń gbẹ́ ihò sí orí ilẹ̀ tí yóò dúró gẹ́gẹ́ bí ọpọ́n ayò, ṣùgbọ́n ohun ti a kàn nípá ni ihò mejila ojú ọpọ́n ayò. Bi ọpọ́n ayò bawa bi ko ba si ọmọ ayò, ayò ko ṣe ta rara. Iyẹn tumọ si pe ayòtita kò lè rọrùn láìsí èso ayò tí a tún mọ̀ sì ṣẹ́yọ̀.

Ọmọ ayò jẹ kóró inu èso igi kan bayi, eso yìí dán lára púpọ̀, ó sì le kóró kóró, ara rẹ yóò ma yọ́ kọ̀rọ́. Ọmọ ayò mẹ́rin ní ń gbé inú ihò kọ̀ọ̀kan. Eyi jasi pe ọmọ ayò méjìdínláàdọ́ta ni mbẹ l'oju ọpọ́n ayò, awọn òtayò yóò si pin l'aarin ara wọn dọ́gbadọ́gba. Ọmọ ayò gbọ́dọ̀ pé kí eré ayò tóó bẹ̀rẹ̀.

Ṣugbọn bí a kò bá wá rí àdán, à máa fòòsẹ̀ ṣẹbọ. Bi òùngbẹ ayò ba ngbẹ awọn eniyan ti nwọn ko si le ri ọkan ninu awọn ohun ti a fi nse ọmọ ayò, a máa ń lo òkúta wẹ́wẹ́ láti fi dípò ọmọ ayò. A sì ń lo kóró iṣin pẹ̀lú. Eèwọ̀ ni kìí a ta ayò ní alẹ́ àti àárọ̀ kùtùkùtù. Ìdì nìyí tí a fi ń pa òwe pé: "Bí alẹ́ bá lẹ́, à fi ọmọ ayò fún ayò". Eré ayò ni ànfaani pupọ. O máa ń pani lẹ́rìn-ìn, a o gbe apá, a o gbe ẹsẹ̀, ara wa yóò si ya gágá. Eré ayò a máa mú ni ronú jinlẹ̀, ti o si le mu ki ọpọlọ ẹni gbooro si i. O nmu ni ronu kiakia, o si mu ki ojú wa riran sìwaju si.

Eré Àrín[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bi awọn eniyan ba fẹ ta àrín tabi ṣe eré àrín, nwọn a wa èso ti a npè ni seeàrín lọ si inu igbó. Èso kan bayi ti a nri ṣa ninu igbo la npe ni àrín. Ẹ̀so ìgi tí ó n fà bí i pákuǹ ni àrín. Èso náà dan lára, ó sì tóbi púpọ̀ ju ọmọ ayò lọ. Àwọ̀ páànù tó dógùn-ún ni ó ní. Èniyàn mẹta ni nta iru àrín yi lẹ́ẹ̀kánnáá.

Ki ọ́mọdé tabi awọn géndé to pade nibi eré àrín, nwọn a ti wọ iho ti ko ju bi isun meji tabi mẹta, wọn yóò tẹ́ ẹní pàkìtí lé ihò náà lórí. Bakannaa ni nwọn o si ti wá àrín bi mẹfa mẹfa tabi ju bẹẹ lọ dani. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yóò ta àrín wọn sínú ihò tí a tẹ́ ẹní sí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Àwọn àrín náà ti a npe ni "apẹ àrín". Ẹnikẹ́ni tí àrín rẹ̀ bá jáde láti inú ihò yóò san àrín mìíràn fún ẹni tí ó ni àrín tó lé e síta. Sugbọn bi àrín awọn mejeeji ti o ṣẹkù si'nu ihò ba tuka lẹẹkannaa a jẹ'pe awọn mejeeji naa ta ọ̀mi. Ẹni tí àrín rẹ̀ bá sì gbẹ̀yìn sínú ihò ni ó borí.

Ànfaní to wa lara ere arin pọ janti rẹrẹ, lara ẹ ni pe, o nkọ ni l'ẹkọ lati mọ bi a ti nf'ojú sun ohun òkèèrè. O nfun oju wa l'agbara lati riran dárádárá ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bojú Bojú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Boojú boojújẹ́ ọ̀kan lára erémọde tí a máa nfi ọ̀yàyà ṣe. Eniyan bi mẹjọ tabi mẹwa le ṣe eré boojú boojú.

Nínú eré boojú boojú a máa n bo ènìyàn kan lójú. Èyí le jẹ obìnrin tàbí ọkùnrin. Lẹ́yìn tí a bá bo ẹnìkan loju tan, àwọn ọmọdé yòóku yoo lọ sá pamọ́. Nigba ti nwọn ba nfi ara pamọ bayi ẹni t'o ndiju yóò maa kọrin pe "Bo ojú bo o ojú o". Awọn ti o nfi ara pamọ náà yóò máa dahun pe: "Eee" "Boojú boojú o! Olórò ń bọ̀, Ẹ para mọ o Ṣé kí ń ṣi Ṣì ṣì ṣí ṣí Ẹni tó lóro bá mu Á pa á jẹ ò Ojú ń ta mí ò".

Lẹhin igba ti gbogbo wọn ba si ti fi ara pamọ tan, nwọn yóò sọ pe ki o ṣi i. Nigba ti a ba ti ṣi aṣọ loju ẹni náà tan, ko ni mọ ibi ti yóò lọ rara; Lẹhin igba pipẹ tabi diẹ, o le lọ ri ẹnikan nibi ti o sa pamọ sí. Wípé ó rí ẹni yí kò sọ pé ki ọwọ rẹ̀ tẹ ẹ, nitori ni riri ti o ti ri i yẹn, ẹni ti à ri náà ko ni duro rara, yóò yara ba ẹsẹ rẹ̀ sọrọ lati salọ. Ṣugbọn ti ẹni ti o nwa wọn kiri yi ba ṣe ri ẹnikan mu, ẹni tí ó ba mú ni yóò ṣe eré boojú boojú mìíràn. Nigba ti ere ọ̀jọ́ yi ba fẹ ka'sẹ nilẹ, ara ẹni ti nwọn ba ti mu yóò wa kan gógógó, oun náà yóò si gbìyànju gidigidi lati ri ẹnikan mu nitori yóò maa bẹ́rù ki eré má bàá ku mọ oun lori. Ẹni ti ere ba ku mọ lórí, awọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yóò mu u si aarin, nwọn yóò si kọrin lee wipe: "Ẹni oro ku mọ lori ko ṣe í ba ṣere alẹ" Orin yi ni nwọn yóò si kọ ti nwọn yóò si tu mọ ọ loju, ti olúkúlùkù yóò si gba ile baba rẹ̀ lọ.

Itọkasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

1. Awọn Àṣà ati Òrìṣà Ilẹ Yoruba Lati ọwọ Olu Daramola ati Adebayo Jeje.

2. Ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá òde òní lati ọwọ Egbẹ́ Akọ́mọlédè Yorùbá.

3. Àkọ́bẹ̀rẹ̀ Yorùbá lati ọwọ Razat Publishers.

4. "ASA ATI ISESE Yoruba". Facebook (in Èdè Latini). Retrieved 2019-11-27. 

5. "Ere Idaraya". Online Yoruba Teacher (in Èdè Faransé). Retrieved 2019-11-27. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]