Jump to content

Eskor Toyo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Eskor Toyo (Asuquo Its; 1929-2015[1]) jẹ ọmọwe Marxist, onímọ̀ Akádẹ́mì àti olukọwe ilẹ̀ Nàìjíríà[2]. Títì ọjọ́ ikú rẹ, arákùnrin náà jẹ ọjọgbọn lórí imọ ọrọ aje ni ile ìwé gíga ti Calabar[3].

Ìgbésí Ayé Eskor Toyo

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọn bí Eskor sì Oron, Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ni ọdún 1929. Arákùnrin náà parí ẹkọ rẹ ni Calabar àti Ẹ̀kọ́. Ní ọdún 1945,nigbati Eskor wá ní Grade àkọ́kọ́ ó gba iwe ẹri ilé ìwé Cambridge. Lẹ́yìn tí arákùnrin náà gbà Diploma ni ori imọ ìṣàkóso àwùjọ ẹda lọ gba BSc lórí imọ ọrọ aje ni ilé ìwé gíga ti London. Arákùnrin náà tẹsiwaju lórí ẹ̀kọ́ rẹ ni bí to ti gba Diploma Àgbà ní ètò ọ̀rọ̀ aje, MSc àti PhD lórí imọ ọrọ aje.[4]. Gẹgebi ọjọgbọn, Eskor kọ imọ ọrọ aje ni awọn ilé ìwé gíga ni ilẹ Europe àti Naijiria kò tó di pé ó di olórí Ẹka tí imọ ọrọ aje ni ilé ìwé gíga ti Maiduguri àti Calabar.

Eskor jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdarí ẹgbẹ́ Marxist-Leninist tó dá lórí àwọn òṣìṣẹ́ àti agbẹ ni ilẹ Naijiria[5][6]. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àárun ọpọlọ, arákùnrin náà kú ní ọjọ́ keje, oṣu December, ọdún 2015 ni ile ìwé ìwòsàn ikẹẹkọ tó wà ní ilé ìwé gíga ti Calabar[7].

  1. "Buhari pays ultimate tribute to Eskor Toyo -". The NEWS. 2016-03-04. Retrieved 2023-10-07. 
  2. Lakemfa, Owei (2016-01-17). "Eskor Toyo: A life of struggle". Vanguard News. Retrieved 2023-10-07. 
  3. Nigeria, Guardian (2016-03-24). "Remembering Eskor Toyo, a rounded Marxist scholar". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Retrieved 2023-10-07. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  4. "Eskor Toyo: Exit of a renowned scholar and activist". The Sun Newspaper. 23 December 2015. http://www.sunnewsonline.com/new/eskor-toyo-exit-of-a-renowned-scholar-and-activist/. Retrieved 19 January 2016. 
  5. Madunagu, E. (2001). The Making and Unmaking of Nigeria: Critical Essays on Nigerian History and Politics. Clear Lines Publications. https://books.google.com.ng/books?id=nooPAQAAMAAJ. Retrieved 2023-10-07. 
  6. Madunagu, E.; Jeyifo, B. (2006). Understanding Nigeria and the New Imperialism: Essays 2000-2006. Clear Lines. ISBN 978-978-38525-1-8. https://books.google.com.ng/books?id=x5EuAQAAIAAJ. Retrieved 2023-10-07. 
  7. Nigeria, Guardian (2015-12-10). "Eskor Toyo dies at 85". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Retrieved 2023-10-07.