Jump to content

Ewì Ayaba

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

EWÌ AYABA ÀTI ÌLÀNÀ ÌGBÉKALẸ̀ LÁÀRIN ÀWỌN Ọ̀YỌ́ Ọ̀ṢUN

Ewì ayaba jẹ́ ewì tí a mọ̀ mọ́ àwọn ìyàwó ọba nìkan. Ọ̀kan pàtàkì lára ẹ̀yà ewì alohùn ilẹ̀ Yorùbá ni pẹ̀lú. Ààfin ọba ni a ti ń bá ewì ayaba pàdé. Ní pàtàkì jù lọ, ewì obìnrin ni ewì ayaba. Ohun tí à ń sọ ni pé àwọn obìnrin nìkan ló ń kópa nínú àgbékalẹ̀ ewì ayaba.

Ọjọ́ ewì ayaba ti pẹ́ láwùjọ Yorùbá. Láàrin àwọn Ọ̀yọ́ ni ewì yìí ti wọ́pọ̀ jù lọ. Ìwádìí jẹ́ kí á mọ̀ pé irú ewì yìí náà ń wáyé láàrin àwọn Èkìtì. (Aládésurú, 1985) Orúkọ tí a mọ̀ mọ́ ewì yìí ní agbègbè Èkìtì ni orin olorì. Yálà kí á pe ewì yìí ní “ewì ayaba” tàbí “orin olorì”, sibẹ́ iṣẹ́ kan náà ni wọ́n ń ṣe láwùjọ Yorùbá. Ìwádìí jẹ́ kí á mọ̀ pé àwọn ayaba kì í gbé ewì yìí jáde kọjá àsìkò ayẹyẹ tàbí ìṣẹ̀ṣe inú ààfin ọba láyé àtijọ́. Lóde òní, ewì ayaba ti ń wáyé nínú ayẹyẹ tó jẹ́ ti ìdílé ọba. Bákan náà, ewì ayaba a tún máa wáyé nínú ayẹyẹ ìlú; tí ọba bá ti wà níbè.̣ Nípa àkíyèsí wọ̀nyìí, a rí i pé ewì ayaba wà fún ọba, ayaba àti ẹbí ọba lápapọ̀.

Gbogbo ewì alohùn Yorùbá ló ní kókó tí wọ́n má ń dá lé lórí. Lára kókó tí ewì ayaba máa ń dá lé lórí ni ìjúwe àwọn ayaba gẹ́gẹ́ bí i aya aládé, àrẹ̀mọ ọba tàbí abọ́baṣèlú. Ọ̀rọ̀ nípa ìgbésí-ayé ayaba, àti ọba nínú ààfin. Àlèébù to wà nínú ilé ọba. Ìwà òjòwú láàrin ayaba, ìṣàfihàn ipò ọba láàrin ìlú. Orúkọ àdàpè ọba. Ítàn àwọn ọba tó ti jẹ rí. Ọ̀rọ̀ nípa ìdàgbàsókè tó wọ inú ìlú lásìkò ọba kọ̀ọ̀kan. Àkíyèsí nípa ìwà ọba tàbí ìrísí ọba. Ọ̀rọ̀ nípa ọdún àti ìbọ tó ń wáyé láàrin ìlú tó jẹ́ ti ọba Ọ̀yọ́-Ọ̀ṣun. Ìwúre fún ọba àti ẹbí ọba.

M. O. Oyewale, ‘Àgbéyẹ̀wò Ewì Ayaba láàrin Àwọn Ọ̀yọ́-Ọ̀ṣun’., Àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹẹ́meè, DALL, OAU, Ifè, Nigeria.

ÀṢAMỌ̀ Iṣẹ́ yìí ṣe àgbéyẹ̀wò ewì ayaba láàrin àwọn Ọ̀yọ́-Ọ̀ṣun. Ó sì jẹ́ kí á mọ̀ nípa àbùdá ewì ayaba, ìsọwọ́lò-èdè ewì ayaba, ọgbọ́n ìsèré ewì ayaba àti ìwílò rẹ̀ láwùjọ. Ọgbọ́n ìwádìí tí a yàn láàyò nínú iṣẹ́ yìí ni gbígba ohùn ewì ayaba sínú fọ́nrán. Àwọn ìlú márùn-ún tí agba ohùn ewì ayaba wọn sínú fọ́nrán ni Òṣogbo, Ẹdẹ, Ìláwó-Èjìgbò, Ìwó àti Ìkòyí. Lẹ́yìn náà, a ṣe àdàkọ ewì wọ̀nyìí, a sì ṣe àtúpalẹ̀ rẹ̀. Síbẹ̀, a fi ọ̀rọ̀ wá àwọn ọba ìlú tí a mẹ́nubà yìí lẹ́nu wò. A tún ka àwọn ìwé tó bá iṣẹ́ yìí mu. Tíọ́rí ìbára-ẹni-gbépọ̀ láwùjọ ni a yan láàyò láti fi ṣe àtúpalẹ̀ àkòónú àti ìsọwọ́lò-èdè inú ewì ayaba yìí. Ìwádìí lórí iṣẹ́ yìí fi hàn pé ewì ayaba jẹ́ ẹ̀yà lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá tó jẹ́ ti àwọn obìnrin; ní pàtàkì jùlọ ìyàwo ọba olorì ọba tàbí ayaba. A jẹ́ kí ó di mímọ̀ nínú iṣẹ́ yìí pé àwọn ayaba a máa ké ewì wọn yìí láàfin tàbí nínú ayẹyẹ tó kan ọba ìlú dáradára. A sọ nínú iṣẹ́ yìí pé ìsọ̀rí ayaba méjì tí a mọ̀ sí ayaba àgbà àti ayaba kéékèèké ló ń lọ́wọ́ nínú ewì yìí. Ní ìkádìí, iṣẹ́ yìí ṣàlàyé pé orin àti ìsàré ni ewì ayaba Ọ̀yọ́-Ọ̀ṣun. Ìwádìí lórí iṣẹ́ yìí sì jẹ́ kí á mọ̀ pé ewì ayaba yìí gbajúgbajà nínú ṣíṣe ìjíyìn nípa ayaba, ọba àti àwọn ìṣèṣe inú àwùjọ kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀ ewì ayaba yìí tún jẹ mọ́ ìwúre fún ọba àti ẹbi ọba

Alámòójútó:Ọ̀mọ̀wẹ́ J.B. Agbájé

Ojú Ewé:228