Jump to content

Ewedu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Amala and Gbegiri with Ewedu soup

Ewedu soup èyí tí a mọ̀ sí ọbẹ̀ ewédú jẹ́ ọbẹ̀ ti àwọn tí ó wá láti Ilẹ̀ Yorùbá sábà máa ń jẹ tí ó jẹ mọ́ ọbẹ̀ ilá tí àwọn olóyìnbó mọ̀ sí"Okra". Ewé Ewédú ni wọ́n fi ṣe obẹ̀ ewédú, nítorí náà ni àwọn olóyìnbó máa ń pè é ní "jute" leaf soup". [1] Ọbẹ̀ Yorùbá yìí máa ń yọ̀, ó dẹ̀ lọ lẹ́nu pẹ̀lú ọbẹ̀ ògúnfe àti ọbẹ̀ ẹja. Ọbẹ̀ ewédú máa ń tó ìṣẹ́jú méjìlá láti sẹ̀ àti pé ó lọ dáradára pẹ̀lú iyán, fùfú àti àmàlà. Ẹ já ewédú, ṣàn án nínú omi, lọ̀ọ́ nínú ẹ̀rọ, fi edé si, irú àti iyọ̀ láti jẹ́ kí ó dùn.

Rí dájú pé a kò fi omi tó pọ̀ sí, a lè má lo ìjábẹ̀ tí a máa ń lo káún fún tí a bá ń lo ẹ̀rọ láti lọ̀ọ́.[2]

Sísè Ọbẹ̀ Ewédú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A ma nílò àwọn ohun èlò wọ̀nyí láti fi se ọbẹ̀ ewédú:

  • Ewé Ewédú
  • Omi
  • Irú
  • Edé
  • Iyọ̀
  • (ohun tí àwọn òyìnbó ń pè ní "Bouillon Powder" - èyí ò pọn dandan.)

Nígbà tí a bá ti tọ́ ewé yìí, a ó sàn-án nù kí omi inú ẹ̀ rẹ rọ́ jáde tí kò bá sí òkúta àti iyẹ̀pẹ̀ nínú rẹ̀ mọ́, a ó ko jáde. A lè kọ́kọ́ se ewédú yẹn lóri iná láti jẹ́ kí ìrọ̀rùn wáyé tí a bá ń lọ̀ọ́. [3]

A lè lo ìjábẹ̀, èyí tí ó jẹ́ ìgbálẹ̀ àbáláyé tí wọ́n gé kúrú láti fi já ewédú títí tí ó ma fi tú dáradára. Àmọ́ èyí tí ó ṣe kíá kíá jù ni lílò ẹ̀rọ. Kí a kàn da ewédú sínú ẹ̀rọ, kí a ta omi díẹ̀ sí kí ó má baà ṣàn jù. Lọ̀ọ́ kí ó fi jọ̀lọ̀.[4]

Ọkà Tí Ó Bá Ọbẹ̀ Ewédú Lọ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọbẹ̀ Ewedu lọ dáradára pẹ̀lú fùfú, àmàlà àti iyán.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Ewedu - Jute Leaves Soup". Chef Lola's Kitchen (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-03-05. Retrieved 2022-05-19. 
  2. "Ewedu Soup". My Active Kitchen (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-05-30. Retrieved 2022-05-19. 
  3. Cuisine, K's (2015-07-16). "Ewedu (How to cook Ewedu Soup that draws)". K's Cuisine (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-19. 
  4. "Ewedu Soup Recipe". Sisi Jemimah (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-08-31. Retrieved 2022-05-19. 
  5. "Ewedu Soup". Low Carb Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-10-04. Retrieved 2022-05-19.