Fáwẹ̀lì Yorùbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Fáwẹ̀lì Yorùbá

Fáwẹ̀lì ni ìró tí a pè tí kò sí ìdiwọ́ fún afẹ́fẹ́ tàbí èémí ton ti inu edo foro bo wa si ona enu. Bí àpẹẹrẹ: a, e, ẹ, i, o, ọ, u, an, ẹn, in, ọn, un,. Gbogbo ìró fáwẹ̀lì èdè Yorùbá ló jẹ ìró akùnyùn. Èyí ni pé tán-án-ná gbọ̀n rìrì nígbà tí a pè wọ́n.

Oríṣi méjì ni fáwẹ̀lì èdè Yorùbá, àwọn ìsọ̀rí méjì náà ni…Fáwẹ̀lì àìránmúpè àti fáwẹ̀lì àránmúpè....

Kọ́ńsónáǹtì Yorùbá[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìró kọ́ńsónáǹtì ni ìró tí a pè tí ìdíwọ́ wà fún afẹ́fẹ́ tàbi èémí nínú káà-ẹnu. Kọ́ńsónáǹtì méjìdínlógún ló wà lédè Yorùbá. àwọn ìró ọ̀hún ni: b, d, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, ṣ, t, w, y. Ọ̀nàmẹ́ta la lé fi mọ irúfẹ́ ìró kọ́ńsónáǹtì tí a ń pè jáde. Àwọn ni: ...

Fóníìmù[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fóníìmù ni òṣùwọ̀n ìró tó mú ìyàtọ̀ wá láàrin ọ̀rọ̀ méjì. Nínú orí yìí, a ó ṣe àgbéyẹ̀wò fóníìmù fáwẹ̀lì àti fóníìmú kọ́ńsónáǹtì. A ó yẹ fóníìmú ohùn wò ni orí kárùn-ún ìwé yìí.

Àpẹẹrẹ Fóníìmú èdè Yorùbá

(a)(b) bí bọ́

ká kó

sọ̀ sè

fò fẹ̀...

Yorùbá Èdè Olóhun[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá a máa dún bí orin nítorí pé èdè olóhùn ni èdè náà í ṣe. Àwọn ọ̀rọ̀ kan ní sípẹ́lì kan náà, ṣùgbọ́n ìtumọ̀ wọn yàtọ̀ nitorí ohùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọn gbérù. Bí àpẹẹrẹ:

agba

àgbà

àgbá ...


Rótìmí Ọláníyan ati Fẹ́mi Ọlọ́runfẹ́mi (2003), Àtùpà Àṣeyọrí, Àkọkún Ìsípayá Lórí Fònẹ́tíìkì pẹ̀lú ètò ìró Yorùbá ìwé Kìn-ín-ní. Ascent & Thrust Books Lagos, ISBN 978-32402-4-4, oju-iwe 8-25.