Fúnmi Àrágbayé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Fúnmi Àrágbayé jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Òndóìpínlẹ̀ Òndó tí wọ́n bí ní ojọ́ Karùún oṣù Kẹẹfà, ọdún 1954( July 5,1954), sí ìdílé onígbàgbọ́. [1] ìkọ́ni ní (Ondo state Civil Service traning School) kí ó tó lọ sí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ dỌ́yọ́ state Civil Service) kí ó tó fẹ̀yìn tì gẹ́gẹ́ bí Olùkọ́ àgbà ní ọdún 1997. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ̀ orin ìyìn-rere rẹ̀ ní iké ìjọsìn Evangelical Church Winning All, ní ìlú Ìlórin, lẹ́yìn ìgbà tí ó gba ìwé ẹ̀rí Wasc. Àwo orin tó gbé jáde tí ó pe ní (Ọlọ́run Ìgbàlà) pẹ̀lú (Síónì Ìlú Ayọ̀) ní ọdún 1982. Ó ṣe àjọ̀dún ọjọọ́ ìbí Ọgọ́ta Ọdún (60th years) nígbà tí ó sì ṣe ayẹyẹẹ àjọ̀dún Ọgbọ̀n ódún (30th years aniverssary on stage) bákan náà ní ( July 5,2014). Ní ìpínlẹ̀ Èkó. Àwọn tí wọ́n kópa nínú ayẹyẹ náà ni: Ebenezer Obey, Joseph Adébáyọ̀ Adélakùn, Dùnní Ọlánrewájú, Kúnlé Àjàyí, Bọ́lá Àrẹ tí ó jẹ́ Ààrẹ lẹẹ̀mejì fún àwọn ẹgbẹ́ akọrin ajíyìnrere nílẹ̀ Nàìjíríà.[2]

Àwọn àwo orin rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọlọ́run Ìgbàlà (1983). Síónì ìlú ayọ̀ (1983). Ìpín rere (Good portion). Ogo Olúwa ( Glory of God).

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Ayoola, Simbiat (2019-01-31). "Tragedy as gospel singer Funmi Aragbaye's 77-year-old husband dies". Legit.ng - Nigeria news. Archived from the original on 2019-07-13. Retrieved 2019-03-14. 
  2. "Yoruba musician, Funmi Aragbaye, loses husband". Premium Times Nigeria. 2019-01-30. Retrieved 2019-03-14.