Jump to content

Fausat Balogun

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Fausat Balógun)
Fausat Balogun
Ọjọ́ìbíFausat Balogun
13 Oṣù Kejì 1959 (1959-02-13) (ọmọ ọdún 65)
Ifelodun, Kwara State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Orúkọ mírànMadam ṣajẹ
Iṣẹ́Film actress
Ìgbà iṣẹ́1975–present
Olólùfẹ́Rafiu Balógun

Fausat Balogun tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Madam ṣajẹ,[1] ní wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì ọdún 1959 (February 13th, 1959) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Sinimá àgbéléwò èdè Yorùbá ni Madam ṣajẹ tí gbajúmọ̀. [2][3] Gbajúmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré sinimá àgbéléwò bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ó kópa ère àwàdà lorí tẹlifíṣàn kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀rín kèékèé. Nínú eré yìí ni ó ti gba orúkọ ìnagijẹ rẹ̀, Madam ṣajẹ lọ́dún 1990. Lẹ́yìn èyí, Fausat Balógun tí kópa nínú eré sinimá àgbéléwò tí ó ti ju ọgọ́rin lọ.[1][4]

Ìgbésí ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fausat Balógun fẹ́ òṣèré sinimá àgbéléwò mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rafiu Balógun, Rafiu jẹ́ ọ̀gá rẹ̀ kí wọ́n tó fẹ́ ara wọn.[1] Nígbà tí ó fi di gbajúmọ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ ti dàgbà. Àkọ́bí rẹ̀ jẹ́ olùdarí fíìmù àgbéléwò, àbígbẹ̀yìn rẹ̀ tó sì jẹ́ obìnrin náà jẹ́ òṣèré fíìmù àgbéléwò.[4]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]